Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Ní Iwájú Si : Nípa Ìlànà Oba Ifá Ti Gúúsù America (South America).
Àrídájú ti so wípé…1. Àwon ènìyàn kan wà tí won ń lo orúko àti ipò Aláàfin láti fi lu àwon tí kò mò nípa Àsà yorùba ní jìbìtì ní ìlú òyìnbó.2. Àwon babaláwo tí ó wà lábé ilé-ifá Ìjo ifá Àdìmúlà. Wón ń gbá àwon ènìyàn lórí èro ayélujàra (internet) nípa fífún won ni oyè orísirísi láì fi tó Aláàfin létí.3. Aláàfin Oba Adeyemi, ti ń lo òfin láti ri wípé àwon afurasí oníjìbìtì wònyí San owó ìtanràn pé won fi Àsà yorùba wólè ní gbogbo àgbáyé.4. Ààfin ti bèèrè gbàgede fún gbogbo elésìn àbáláyé láàrin ìlú kí won fi orúko sílè lábé egbé tí a mò sí Àsà òrìsà láti ri wípé wón wà ní ìbámu pèlú ìse onísèse àti láti kápá ìwà jìbìtì.5. Orúko àwon afurasí wòn yí ni :Faniyi Awoniran Omoyemi, Ojelabi Okewole, Faleye Ikusaanu, Famuwagun Oloyede, Ifayemi Olaniyan, Ifakorede Ifaloseyi, Ifadotun Fatoki, Oyasogo Ifakorede, ifasooto Ifawumi Adeyemo, Awoniran Awotunde, Awoniran Ifamuyiwa àti béè lo.6. Ikusaanu Faleye, Fasola Olaniyan àti Olaniyan Awoyemi nìkan ni ó ti Fara hàn ní ilé ejó ní ìyágànku Ibadan tí ó sì kun àwon tí ó pò.7. Èsè mérin òtòtò ni a ti kà sí won lésè Èsè òdaràn, ìfirawé, Ayédèrú àti ìwà tí ó le mú ìpalára wá fún àláfíà ìlú.8. Abánirojó, Fasola Sunday, sàlàyé wípé olùjéjó àti àwon tí ó ń se àfarawé Aláàfin fi oyè fún ènìyàn wípé kòsí oyè kankan tí ó ńlá jé Oba ifá ti gúúsù America (south America) lórí àtòhúnrìwá kankan.9. Àwon olùjéjó se ayédèrú ìwé-èrí oyè náà tí won sì fi irú rè fún Franciva Leoa Nobres tí wón so ní Ifatoowo Adebayo :Dasiel Guerra, Awotunde Ajisola : àti Jose Lara tí won so ni Ifakayode Falade.10. Àwon tí a fi èsùn kan wí àwíjàre pé àwon kò jèbi èsùn tí a fi kàn wón tí ó sì jé wípé Adájó AA. Adebisi sì fún won ní béèlì egbèrún lónà ogóòrun (#100,000) tí àrídájú isé sì wà, wón sún ejó nà lo sí ojó ketàdínlógún osù kefà (July 17).11. Olúwo ti òyó Aláàfin, Ifatoki Ojo fi àrídájú lélè wípé babaláwo kankan kò ní àse láti fi enikéni je oyè láìní owó Aláàfin nínúEnglish VersionContinue after the page break -
Fatai Owoseni sàkóso lílo bíbò ní Ikorodu láti owó omo oòduà rere !
Kàyééfi ńlá gbáà ni súnkere fàkere okò tí ó selè ní ìròlé àná ní bóòsì dúró Agric (Agric bus stop), Ikorodu ní ìlú Èkó. Tí ó kan ògá pátápátá ilé-isé olóòpá (commissioner of police) Ògbéni Fatai Owoseni láti yo òpòlopò ènìyàn nínú súnkere fàkere tí ó selè ní bóòsì dúró Agric.
Gégé bí ìròyìn se so àwon ò n tajá àti ò n rajà ti férè gba ìlàjì ojú ònà tán, tí won sì fi ònà díè sílè fún àwon tí ó ni ònà, èyí fa ìdádúró púpò fún òpòlopò ènìyàn tí àwon míràn sì dúró sinsin.
Nígbà tí Ògá olóòpá (CP) ń bò láti Ikorodu ó sò kalè láti rìn lo sí bóòsì dúró (bus stop) láti mo ohun tí ó fà á.
Nígbà tí LASTMA tí kò leè gba ara rè sílè, àti àwon tí ó ń darí maalo maabò àti ìgbìmò egbé awakò (NURTW) dúró láìrí nkankan se, ògá olóòpá àti àwon emèwà rè lé àwon tí ó ń tajà ní ojú ònà yí kúrò tí gbogbo rè sì lo sí rowó rosè kí ó tó kúrò lo sí Ikeja.
Kò saláì fi ìkìlò sílè kí ó tó lo wípé ohun kò fé rí àwon olójà kankan ní ojú ònà mó láéláé…..English VersionContnue after the page breakBómbù Déru Bà Wón Ní Ilé-ìfowópamó Diamond (Diamond Bank) Ní Ìlú Jos
Bómbù déru bà wón ní ilé-ìfowópamó Diamond (Diamond bank) ní ìlú Jos, Bí won se fura wípé wón ti wà okò kan gúnlè tí irinsé olóró Bómbù sì wà ní inú rè. Gbogbo òsìsé ilé-ìfowópamó Diamond ti eka Katako, ní Jos, àti àwon olùgbé ti sí kúrò léyìn tí okò afurasí tí ohun ìjà olóró wà nínú rè wà gúnlè ní iwájú ilé-ìfowópamó náà.Ilé-isé kan tí a mò sí JTown connect metro kójopò wípé wón ti wa okò náà gúnlè fún ojó kan àti òpò wákàtí séyìn tí enikéni kò sì wá fún un.Olùgbé àti òsìsé ilé-ìfowópamó ti eka Katako tí èrù ti ń bà pariwo síta or àwon tí ó le gbógun ti Bómbù, won kò sì pé tí won fi dé ibè.Àwon tí ó ń gbógun ti Bómbù dí ònà tí òpò ènìyàn ń gbà láti dáàbò bo ènìyàn pèlú okò tí ó ń kojá.Léyìn ìgbà tí won ti se ìwáàdí àti àyèwò fínífíní, àwon olù gbógun ti Bómbù gbógun ti ohun olóró yìí tí ó sì túká yángáyángá. Wo àwòrán síi ní ìsàlè….English Version
Continue after the page breakÀwòrán Kí Ó Tó Di Ojó Ìgbeyàwó Láàrin Eléyàmeyà
Omo Ooduarere tún gbé tuntun dé ooo, àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó láàrin eléyàmeyà. Femi (yorùba) àti Mma rè tí ó ń jé OGECHI láti (River), inú won dùn púpò gan bí won se ya àwòrán papò nínu aso a-lá-rà-n-ba-rà….
Orísirísi àwòrán sì wolé léyìn ìjáde won…
English versionContinue after the page break
Iná gbé arabìnrin kan tí ó jé akékòó ifáfitì ní ìjoba ìpínlè River (River state university).
Akékòó ifáfitì ní Ìjoba ìpínlè River kan tí a ò tíì mo eye to ó su ú ni Iná gbé ní ojó ìségun (Tuesday) ojó ketàlá osù kefà (June 13). A bá a tí ó subú lulè léègbé kan tí kò jìnà sí ilé-ìwé náà tí won sì gbé e dìgbàdìgbà lo sí ilé-ìwòsàn ilé-ìwé náà, kí ó tó di wípé Dókítà fi ìdí rè múlè wípé ó ti kú.
Gégé bí ojú tí ó ríi se so. Omobìrin náà ń gbìyànjú láti dá àgbàrá òjò kojá, nítorí òjò kan ti ń rò láti òwúrò ojó náà.
“Àgbàrá òjò tí ó fé dákojá yí òpó Iná kan ti wó sí inú rè ní ojó ajé (Monday) ojó kejìlá osù kefà (June 12).olóògbé kò sì mo èyí”.
Arí gbó wípé àwon aláse ilé-ìwé yìí ti fi tó àwon olùmójútó (PHED) létí wípé òpó kan ti wó.

English Version
Continue after the page breakTonto Dikeh Pèlú Muhammed Lai Nínú Okò Ojú Òfurunfú
Gbajúgbajà òsèré Tonto Dikeh àti Asàkóso ìwí àti Àsà (minister of information and culture) Muhammed Lai. Ya àwòrán nínu okò ojú òfurunfú nínu ipò tí ó wà ní ìsàlè. “mo wo bí ayò mi se kún tó nígba tí Hon. Muhammed Lai sòrò kárakára nípa ìpìlè mi. Bí ènìyàn bá gbájú mó isé rè tí ó se olórun a ma fi èrè si. Inú mi ń dùn fún ìgbésè tuntun…..English Version
Continue after the page breakEwi Toni: Toju Iwa Re Ore Mi
Toju iwa re, ore mi;Ola a ma si lo n’ile eni,Ewa a si ma si l’ara enia,Olowo oni ‘nd’olosi b’o d’ola.Okun l’ola; okun n’igbi oro,Gbogbo won l’o nsi lo n’ile eni;Sugbon iwa ni m’ba ni de sare’e.Owo ko je nkan fun ni,Iwa l’ewa omo enia.Bi o l’owo bi o ko ni’wa nko?Tani je f’inu tan e ba s’ohun rere?Tabi ki o je obirin rogbodo;Ti o ba jina si’wa ti eda nfe,Tani je fe o s’ile bi aya?Tabi ki o je onijibiti enia;Bi o tile mo iwe amodaju,Tani je gbe’se aje fun o se?Toju Iwa re, ore mi,Iwa ko si, eko d’egbe;Gbogbo aiye ni ‘nfe ‘ni t’o je rere.(ENGLISH TRANSLATION)(ENHANCE YOUR CHARACTER MY FRIEND)Continue after the page breakOwó ti te àwon àpapò tí a mò sí Boko Haram tí won ń dógbón se bíi fúlàní darandaran ní ìlú Edo
NAN, Otaru ti ilè Auchi, Alhaji Aliru H. Momoh , ní ìlú Edo, ti kéde ní ojó ajé bí owó se te okòó lé mérin( 24) àwon afurasí Boko Haram tí won ń se bíi fúlàní darandaran ní agbègbè náà tí owó àwon ológun ti bà.Oba so fún àwon oníròyìn ní ààfin rè ní Auchi ní àgbáríjo ìjoba ìbílè ìwò oòrùn ní ìjoba ìbílè náà, wípé apàse ilé-ìwé ológun orílè èdè Nàìjíríà NICOHO ní agbègbè Auchi, fi tó o létí nípa mímú àwon afurasí náà. “kí ó tó di wípé o wolé, mo ti ní òrò pèlú apàse “.“ó fi oun tí won ń se tó mi tó mi létí àti bíwon se mú okòó lé mérin (24) àwon afurasí yi Boko Haram tí won sisé bí fúlàní darandaran “.ó so béè.“Apàse tún fi tó mi létí wípé àwon afurasí yí won máa darí won lo sí Benin “Oba so béè.Ó gbé oríyìn fún apàse fún ìgbésè takuntakun tí ó gbé láti bá àwon afurasí náà wo ìjàkadi nínú aginjùÓ so wípé “ètò ìdáàbòbò ní láti se àmójútó fínífíní “,Otaru sàpéjùwé ètò àwon darandaran lágbègbè won wípé óburú jàè so pé ” A ti be àwon àgbè, papàá jùlo àwon obìnrin láti má lo sí oko ní àkókò yí.A fún won ní owó díè láti jé kí won máa se isé tí owó won bá fún ìgbà díè náà. Tí gbogbo rè máa fi yanjú.Àwon ìgbìmò ìbílè ń jùmò sisé pò pèlú àwon ológun, àwon olùdáàbòbò ìlú asì ti fi tó àwon olóde létí láti wá ònà àbáyo tó dángájíá sí òrò náà “ó fi kunEnglish VersionContinue after the page breakLaura Ikeji àti Ogbonaya Kanu kí omo tuntun sí inú ìdílé won ní ìlú òyìnbó (u. S).
Omo ìyá Linda Ikeji , Laura Ikeji àti oko rè Ogbonna Kanu kí omo tuntun káàbò sí ìdílé won ní ìlú òyìnbó (U. S). Linda Ikeji kéde ewu omo tuntun náà lórí èro ayélujàra (instagram), níbi tí o ti pín àwòrán ara rè….English VersionContinue after the page breakOmo Oba Gwamnishu Harrison, tí won jígbé ,ké pé òun ń fi Nàìjíríà sílè
Olùdarí ilé-isé (CEO) ‘Behind Bar Initiative’, èyí tí ó pín àwòrán ara rè ní ibi tí ó gbé ń sunkún lórí èro ayélujàra (facebook). Ti so àsírí èròńgbà rè láti fi orílè èdè Nàìjíríà sílè lo sí ìlú òyìnbó (U. S. A), nígbà tí ó ti kó sí páńpé àwon tí ó jà á lólè lójó díè séyìn ní ìjoba ìpínlè Delta .Ó fi ègbékègbé pèlú àwon òdaràn yí nígbà tí ó ń bò láti Agbor tí won sì gba owó tí ó tó egbèrún lónà Igba (#200,000) lówó rè. Àwon òdaràn yí tún fi sí àhámó fún wákàtí díè tí won sì gba káàdì tí ó máa ń powó (ATM card) rè tí won sì bèrè nómbà àsírí tí ó fi máa ń gba owó jáde ní ilé-ìfowópamó (bank). Tí ó sì fun won, ni won bá gba gbogbo owó tí ó fi pamó pátápátá pèlú èro ìbánisòrò (phone) rè àti nkan míràn ni won gbà lo.Gégé bí ó se so, àwon ajínigbé yìí fun ní sìgà (cigarettes) pèlú Alomo kí ó tó di wípé won ja jù sílè ní àgbáríjo oko kan tí a mò sí Ughelli, ní ìpínlè Delta.E wo ohun tí ó pín sí orí èro ayélujàra (facebook) Lánàá.“E mo nkan tí ó duni jù? Kí o ní èròńgbà lókàn kí o má mo bí o se gbe jáde. Àkókò yí le gan fún mi. Kí olórun wà pèlú ìgbìmò egbé Kingsley Ughe àti egbé JLAA fún agbáterù yín.Modúpé púpò fún ìfé yín JLAA ti Ughelli àti ti Àsàbà.Kí ó tó di wákàtí Méjì-lé-láàdóta (48 hours) n o ti ma fohùn ní ìlú òyìnbó (U.S.A)……English Version
Continue after the page break