Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Omo Egbe Yoruba ati ‘OPC’ (Oodu Peoples Congress) Fajuro lori rogbodiyan ti o sele ninu ile ife

    Awon omo egbe apapo-Yorùbá-titi eka –oselu, Afenifere ati awọn omo egeb (Oodua Peoples Congress), OPC, ti fariga nipa rogbodiyan ti oun lo ni ilu Ile Ife. Ninu oro kan ti abenugo fun eggbe Afenifere kán so eyi ti un se ogbeni Yinka Odumakin wipe, opolopo dukia ni o sonu ati emi awon ana ise ni won pe ati wipe pupo ninu awon ti awon agbofinro mu ni ki un se alaise aye won sọnu ni figagbaga ṣugbọn faulted aabo operatives fun rù jade a ọkan-apa imuni ti diẹ ninu awọn alaiṣẹ olugbe.

     
    Ninu oro won afenifere sọ pé: opololopo awon ti awon agbofinro mu ni alaise eyi ti won ko lo si ago olopa ni ilu Osogbo ati ago won ti o wa ninu Abuja. Ba kan na olori awọn omo egeb (OPC), Otunba Gani Adams ti pe ipe fun pele larin awon ara ilu Ile Ife ati awon Hausa na lati ma gbe ni aalafia .
    Ninu oro kan nipa awọn alabagbe yi , akowe ti OPC ogbeni Yinka Oguntimehin sọ pé: “A ko fẹ ki alejò ti oun gbelori ilewa so wa di eni ti a o beru lori ile babawa. Awọn Yorùbá ko ni gba lati je eni ti won yi o ma beru ni ori ile won abi lati je eru ni orílẹ-èdè yi . O te se wa ju ni oror re pe ki won tu awon ti agbofinro mu lala ise se le ni waran sesa, Ba kan na ni ogbeni ti oruko re unje Babajide Omoworare, omo ile igbimo aso fin agba titi olu ilu ile wa ti o wan ni ilu Abuja ti o nsoju (Osun East Senatorial District ni National Assembly) nigba ti o sabewo si Sabo ni bi ti awon awusa na un gbe ni ile ife Omoworare tun so wipe oun o fe ki itaje sile wa larin awon husa ati ara ilu ile ife mo, bee na ni o pese iranwo fun awon ti won padanu dukia ati ounje.

     
    Awon igbimo apapo the (Supreme Council for Sharia in Nigeria SCS) ti eka oriilede nigeria ti fi da awon orinide yi loju wipe won yi o wa unkan se si rogbodiyan na lati mafa gbonmisi omioto kakiri orile-ede yi.

     

    English Version:

    Continue after the page break.

  • Ti eba jabo si inu omi pelo ọkọ ayọkẹlẹ: Eleyi ni ona irọrun ti elefi gba emi yin la (Fidio)

    Eleyi ni ona irọrun ti elefi gba emi yin la, ati ligba ti eba jabo si nu omi eyin ati ọkọ ayọkẹlẹ yin. A se iwadi wipe egbelegbe irinwo “400” awon eniyan ni ounku ni ododun lipa ijamba awon ati ọkọ ayọkẹlẹ won kiko si nu odo, ase iwa di wipe opolopo awon eniyah ni won ma un wole pelu oko ayokele na.  Eyii ni oun ti e ne se lati yo ara yin ninu ewu na, na i pe egbe omo ogun panapana tabi olopa, nipa wiwo fidio ti o wa ni sale oro yi, yi o je anfani fun yi nigba ti isele na ba se si yin.

     

    English Version

    Continue after the page break.

  • Posita gbigba okore pada Kun ilu Port-Harcourt Egba ni eleja

    Posita wagba okore kun igboro ilu Port-Harcourt

     

     

  • Eyin eniyan e wo E-moni(E-money) ninu photo titun re.

    Alaga ti Ẹgbẹ eka marun apapo , wuni ninu poto re titun ti o sese ya.

  • Tonto Dikeh ki Mercy Johnson pe ‘oku orire fun ipo titun ti Gomina Kogi sese yan si’.

    Awuyewuye ija ti oun lo laarin awọn oṣere Tonto Dikeh ati Mercy Johnson, Tonto Dikeh ti toro aforiji lori awọn gbólóhùn o ṣe nipa ọmọ rẹ ati awon oro miran to ti so ni odun die seyin. Mercy Johnson gba ebe e, awon mejeji si tọ akọroyin lo, lati fi ha wipe ni otito ni won ti pari ija won. Tonto Dikeh , si ki Mercy Johnson noni lori ipo titun eyi ti unse biba gomina jiroro lori Asa ati ise, ti gomina ipinle Kogi sese fi je.

     

    English Version–>

    Continue after the Page break

  • Aseritu: Awon Agbofinro ‘SON’ Ri Ile Alaja Meji Ti Won Ko Ogun Ti O Ti Ba Je Si. (Aworan)

    Awon  ‘SON’ (Standards Organisation of Nigeria) ti mu ogbeni akeruwole ti oun ta aye deru Kosimetik ati ọti-waini ti se ayipada awọn ogun ti ọjọ ti lo lori wọn ati ti o nri titun ọjọ lori wọn, ni eyi ti se awon onibara, Akeruwole na, Ogbeni Joseph Udeh, eni ti Jouf Nigeria Limited, be ni ojule kewa, igbagbo pa ti Oboh Street, Kirikiri Road, Apapa, ni ilu eko, ti wa ni wi lati wa ni a pataki onisowo ni gbajumo Kosimetik ati ile ọja burandi.

    O si iyipada meji mẹrin-oke ile ibugbe awọn ile, kọọkan ti o ni awọn mẹjọ yara sinu ibi ipamọ ohun elo fun awọn ọja. A jo wo ni diẹ ninu awọn ti Kosimetik fi han orisirisi oogun to ọjọ re ti baje, diẹ ninu awọn ibaṣepọ bi jina pada bi 2004 nigba ti diẹ ninu awọn ti pari ni 2013 ati diẹ ninu wọn ni 2016.

    Udeh ti itaja re wa ni be ni oja Balogun ati ni ite isowo gbogbongbo , so wipe o je a isise to pataki soobu iÿë ati diẹ ninu awọn pataki Eka ile oja ni orile ede naigeria .

    Awon alase (SON) Won ba awon oniroyin soro ni kete nipari iwadi won, wipe awon ako ogun ti oti baje wole na yio fi oju wina ofin ni kikun
    “Awon iwọn didun ti awọn de ti pari ni inestimable. Fojuinu a ọja ti o yẹ ki o wa lo ni murasilẹ soke a omo ni 2017 ti pari ni 2015, ohun ti yoo jẹ awọn ipa lori omo, dajudaju o yoo jẹ odi lenu lori omo.

    A ni omo ‘powders’ ti o ti pari niwon 2013 ati mẹrin ọdun lẹhin ti, awọn ọja ti wa ni ṣi lọ sinu oja. Nígbà tí wọn ta, nwọn si yọ awọn expiry ọjọ ki o si fi titun ọjọ lati tan awọn unsuspecting awọn onibara ati nigba ti o ra awọn ọja, ti o ba ro ti won ba wa ni awọn ọja ti o le ran o, ko mọ pe ti won ba wa awọn ọja ti yoo fa o gbogbo ona ti arun. “
    Ni ibamu si awọn osise (SON ), ọpọlọpọ awọn alaiṣẹ eniyan jìya lai mọ awọn orisun okunfa aisan won , won tun te si waju wipe awo akeruwole ogun ti o ti baje yi npa opolopo ati wipe won si un ja awon omo ori nile ede nigeria nolè.

     

    Oniroyin –  Omo Oba Olusola

    English Version:

     

    Continue reading after the page break!

  • Ẹ̀rù ló sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò/Ológìní tó fi di ” Ẹran-àmúsìn – Ọdẹ peku-peku” –

    Ni igbà àtijọ́, ẹranko ti wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára ẹranko. Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku. Ti Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nitori Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyi ti a fi ńpè ni “Baba Ẹranko”, ti a ńpè Kìnìún ni “Ọlọ́là Ijù”.

    Kìnìún ni “Ọlọ́là Iju
    Kìnìún ni “Ọlọ́là Iju
    Ológbò/Ológìní
    Ológbò/Ológìní

     

    Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré wọn kò lè yára bi iyá wọn. Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn.

    Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja. Ibi ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni dé ibẹ̀. Nitori èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé “Kàkà ki Kìnìún ṣe akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ”.

    Ẹkùn “Baba Ẹranko”
    Ẹkùn “Baba Ẹranko”

    Lai fà ọ̀rọ̀ gùn àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá. Nigbati Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà. Nitori èyi, ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ.

    ọmọ Ẹkùn
    ọmọ Ẹkùn

    Nigbati iyá wọn kọ̀ wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri. Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni òwe pé “Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú ilé.

    English Version

    Continue after the page break.

  • “Àṣejù Baba Àṣetẹ́” – Ìtàn bi Ojúkòkòrò àti Ìgbéraga ti jẹ́ Àṣejù

    Ni ìgbà àtijọ́, ọkùnrin kan wa ti orúkọ rẹ njẹ́ Ìgbéraga. Wọ́n bi Ìgbéraga si ilé olórogún, àwọn ìyàwó bàbá́ rẹ yoku ni ó tọ nitori ìyá rẹ kú nigbati ó wà ni kékeré. Lẹhin ti o tiraka lati pari iwé mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́, ó gbéra lọ si ilú Èkó nibiti ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Ẹlẹ́ja.

    Ó nṣe dáradára ni ibi iṣẹ́ ki ó tó gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ. Ìgbéraga pinu lati padà si ilú rẹ lati gba ogún ti ó tọ́ si lára oko kòkó rẹpẹtẹ ti bàbá rẹ fi silẹ̀. Ohun fúnra rẹ ra oko kún oko bàbá rẹ ti wọn pín fun. Ó di ẹni ti ó ri ṣe ju àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ ki gbogbo àwọn ọbàkan rẹ gbójú le fún ìrànlọ́wọ́.

     

    Ni igbà ti ó yá, o ni ilé àti ọlà ju gbogbo àwọn yoku ni abúlé ṣùgbọ́n kò to, ó bẹ̀rẹ̀ si ra oko si titi dé oko àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ́ ki ó sọ àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku di alágbàṣe ni oko ti wọn jogún. Inú àwọn ọmọ bàbá rẹ wọnyi kò dùn si wi pé wọn ti di atọrọjẹ àti alágbàṣe fún àbúrò wọn ninú ilé ara wọn.

     

    Yorùbá ni “Àṣejù Baba Àṣetẹ́”. Ìgbéraga bẹ̀rẹ̀ si ṣe àṣejù, kò dúró lati má a fi ọrọ̀ rẹ yangà si gbogbo ará ilú pàtàki si àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, ó jọ ara rẹ lójú, ó si nsọ ọ̀rọ̀ lai ronú tàbi gba ikilọ̀ àwọn àgbà ti wọn mọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ. Kò mọ̀ wi pé ohun ngbẹ́ ikòtò ìṣubú fún ara rẹ́. Ni ọjọ́ kan, ó pe ọ̀kan ninú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ó sọ di alágbàṣe ninú oko rẹ tẹ́lẹ̀ ó si bu, ó pe e ni aláìní dé ojú rẹ. Ẹ̀gbọ́n ké pẹ̀lú omijé lójú pé “Bi ó bá jẹ ìwọ ni Ọlọrun, ma ṣe iwà burúkú yi lọ, ṣùgbọ́n bi ó bá jẹ́ enia bi ti òhun, wà á ká ohun ti o gbin yi”.

     

    Alágbàṣe ni oko Kòkó ti wọn jogún – Working as Labourers in their inheritted Cocoa farm. Ni àárọ̀ ọjọ́ kan, Ìgbéraga ji ṣùgbọ́n kò lè di de nitori ó ti yarọ. Wọ́n gbe kiri titi fún itọ́jú ṣùgbọ́n asán ló já si. Ìṣòro yi jẹ ki ó ta gbogbo ohun ini rẹ ti ó fi nyangàn titi o fi di atọrọjẹ.

    Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe àṣejù ohunkóhun kò dára pàtàki ki enia gbójúlé ọrọ̀ ilé ayé bi ẹni pé àwọn ti ó kù kò mọ̀ ọ́ ṣe, nitori Yorùbá sọ wi pé “kìtà kìtà kò mọ́là, Ká ṣiṣẹ́ bi ẹrú kò da nkan, Ọlọrun ló ngbé ni ga”.

     

     

    English Version:

    Continue reading after the page break.

  • Iwure Fun Wa Latari Bi A Se Mo Ise Aburu Ti Awon Elenini Nse Lati Ma Fe Jeki Eniyan Se Rere Ati Saseyori Nile Aye,

    Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku imura toni, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo awon ota ti won ba sope ako ni se rere yio di gige kuro lori ile alaaye loni o ase.
    Laaro yi mo maa fi odu mimo ejioore se iwure fun wa latari bi a se mo ise aburu ti awon elenini nse lati ma fe jeki eniyan se rere ati saseyori nile aye, c ko sibiti elenini ko si laye yi, o wa nile ti a ngbe o wa ladugbo ati ibi ise wa, sugbon eyikeyi ninu won to ba sope oun koni jawo leyin wa yio di eni akolebo loni.
    Ifa naa ki bayi wipe:
    Igba awodi nla ni nfiye apa se ilu legan a difa fun Atalanpako eyiti nse elenini baranipetu seni Atalanpako maa nse ènìní baranipetu nkakiri ibi gbogbo, won ni ki baranipetu karaale ebo ni ki o wa se nitori ki o baa le segun elenini re, obi meji, igiripa obuko, ida olominimini, abe ati igba ewe ayajo ifa baranipetu kabomora o rubo won se sise ifa fun, nibiti Atalanpako ti gbe nse enini baranipetu ibe ni abe ifa ti koó lori ti ida olominimini si ti ni lorun bi atalanpako se ku niyen o ti aye ifa wa dofe moore, ijo ni baranipetu njo ayo lo nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
    AKOSE IFA RE: ewe ida olominimini, ewe àró, ewe arogbo, ewe uda, ewe udi ao gun papo mose ao fi eje obuko naa po lehin ti abati fi bo esu tan, ao gbaye ifa naa si ao ko sinu igba olomori ao fi obe oloju meji gun lori ao maa fi obe yen bu ose yi sori kanhinkanhin iwe, hmmn! Ifa isegun elenini todaju ni.
    Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi wipe gbogbo awon elenini aye wa ni ifa yio fi ida re be lori, gbogbo awon alatako nibi ise wa tabi ladugbo ni won yio ku iku itiju, ao segun ota ao si reyin odì lagbara Orunmila mimo alagbawi wa aaaseee.
    ABORU ABOYE OOO.

     
    ENGLISH VERSION:
    Continue after the page break

  • Ifa naa ki bayi wipe

    Aku ise ana o a si tun ku amojuba osu tuntun o, eledumare yio jeki osu yi tuwa lara o, ako ni bawon paruwo kosi kosi lase eledumare.
    Laaro yi mo maa fi odu mimo ejioore se iwure fun yin gegebi ojo kinni ninu osu tuntun.
    Ifa naa ki bayi wipe:
    Orunmila ni moyò
    Moni moyò
    Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
    Moni ogoke otu ife ni, to fi iwaju gun ope to si feyin so kale pada laisi wahala
    Oni se ko to òrò ayo ni?
    Moni o toro ayo
    Orunmila ni moyò
    Moni moyò
    Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
    Moni àgbè mùyoko otu ife ni, ti won lo soko lati ibere Odun ti won de lopin odun ti won si roko bodunde
    Oni se ko to òrò ayo ni?
    Moni o toro ayo
    Orunmila ni moyò
    Moni moyò
    Orunmila ni kini mori ti mo nyo fun?
    Moni awon aboyun otu ife ni, ti won ru oyun fun osu mesan gbako! Ti won si bi tibi tire laisi wahala
    Oni se ko to òrò ayo ni?
    Moni o toro ayo
    Moni Orunmila kilode to fi nfo bi ede bi eyo?
    Orunmila loun ko fo bi ede bi eyo
    Oni bi kose ire ayo toun ri niwaju akapo toun
    Oni omo kan tuntun ni eleyi ti won maa bi ki won so omo naa ni MOYÒ.
    Eyin eniyan mi, mo se ni iwure wipe osu tuntun yi yio je osu ayo, idunnu ati ilosiwaju funwa o, aye yio bawa yayo nkan rere o, osu yi yio san wa ju gbogbo osu to ti koja lo o aaaseee
    ABORU ABOYE OOO.

    English Version

    Continue after the page break bellow.