Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Èsì Ikú Tí Ó Pa Joy Odama Akékòó Odún Kejí (200l) Ti Ilé-èkó Gíga Ifáfitì Tí Ó Wà Ní Ìpínlè Cross River
Léyìn tí a gbó èsì ikú tí ó pa Joy Odama akékòó odún kejí (200l) ti ilé-èkó gíga ifáfitì tí ó wà ní ìpínlè Cross river (university of science and technology (CRUTEC)) èyí tí ó kú ikú kàyééfi léyìn ìgbà tí ó rí Alhaji kan tí a mò sí Alhaji Usman Adamu ní ìlú Abuja ní osù kewàá odún tí ó Jojo.Gégé bí ìwé ìròyìn Vanguard, èsì ikú yìí tí ilé-ìwòsàn ìjoba àpapó (National hospital) ní ìlú Abuja gbé jáde , fihàn pé ikú májèlé ni arabìnrin náà kú, látàrí egbò igi olóró tí a mò sí kokeènì (cocaine). Agbó wípé arabìnrin yìí ní àìsàn okàn tí a mò sí (cardiogenic shock). Ìyá olóògbé ,Philomena Odama, ní ìbèrè pèpè osù ti ko ìwé èbè (petition) sí ipò ààre orílè èdè (presidency), ìgbìmò asòfin àgbà (Senate president), agbenuso ilé ìgbìmò asojú sòfin (speaker of house of representative), ògá àgbà ilé-isé olóòpá (IGP) DSS àti àwon èyà tí o ń dáàbò bo ìlú pèlú àwon tí ó wà ní ipò gíga nípa ikú omo rè. Nínú ìwé tí aya Philomena ko o se àfihàn bí eni tí won fura sí yìí ti máa ń gbé òpòlopò omoge ní èbá ònà tí ó sì máa ń se ìlérí wípé òhun o tó won ní iié-ìwé.Ní àkámó eni tí a fura sí yìí ní arabìnrin Joy odama kú sí. Ó sì ti gbìmò pò mó àwon olóòpá láti gbé omo náà sínú yìnyín láì fi tó àwon òbí rè létí. Àwon olóòpá ní kí àwon jáwó nínú ejó náà kí àwon sì gba egbèrún lónà egbèédógún (300,000) tí a fura sí yìí gbé fún won. Wípé àwon kò sì le è dá ejó nítorí gbajúmò tí ó túmò sí wípé òtòkùlú ni……. -
Gbajúgbajà Olórin, Diamond Platnumz Ti Yanjú Aáwò Tí Ó Wà Láàrin Òhun Àti Ìyá Omo Rè
Gbajúgbajà olórin ní ìlà oorùn adúláwò tí a mò si Diamond platnumz ti yanjú aáwò tí ó wà láàrin òhun àti ìyá omo rè léyìn wákàtí tí ó bá a wí fún àìso òtító . Ó pín eré oníse amóhùn máwòrán (video) tí òhun àti omo àti ìyá omo rè hàn nínú è “mo ti sòrò ” won jùmò pa ohun tí won fi sí orí aféfé ré. Ó tún pín eré obese amóhùn máwòrán òhun àti Zari pèlú àwon omo won tí won ń seré pèlú ohun tí a mò sí “yà ko tè “(snapchat)…….
English VersionContinue after the page break
-
Odomokunrin Kan Ni Orile Ede Naijiria Ati Ara Binrin Oyinbo To Sanra Mu Ki Awon Eniyan Soro
Oro to panilerin ninu itakuroso ti o wa laarin arakunrin yi ati ololufe re tele eyi ti o yan je. Arakunrin naa kunle lati beere owo owo arabinrin orobo yi fun igbeyawo..
Eyi ni lati fi ife otito han si ololufe re, odomokunrin ile naijiria ti di gbajugbaja lori ero ayelujara. Arakunrin yi fi aworan ohun ati ololufe re han nigba ti won n sere ife lowo. Eyi je iyalenu fun opo eniyan.
English VersionContinue after the page break
-
Sangbafo! Won Ge Apa Ati Ori Arakunrin Kan Nitori Ija Ile Ni Ipinle Delta
Ajalu ti o n sele lowo ni amai ati umuebu ni agbegbe iwo oorun ni ijoba ibile ndokwa ti owa ni ipinle delta – o ti gba ona iburu nipa pipa odomokunrin kan ti won ge apa ati ori re nitori ija ile. Ajalu ti o ti n sele lati ojo pipe ti opolopo eniyan si ti fara kaasa (farapa) ti opo ti gba ibe rorun ti ijoba o si gbe igbese lori re….
English Version
Continue after the page break
-
Aawọ ni Oshodi: Oluomo, Talonskibo, Harmburger Ati Oluwo.
English Version
Continue after the page break
-
Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe Àjọyọ̀ Ìdásílẹ̀ Àádọ́ta Ọdún
Ìjọba-àpapọ̀ sọ Èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin. Èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si Abuja. Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ ikan ninú ipinle mẹ́fà Yorùbá.
Yorùbá ni “Èkó gba olè, ó gba ọlẹ”, ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ Èkó nitori Èkó gba olówó, ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni Èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo. Kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn Nigeria ti kò si ni Èkó. Nitori èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nitori omi ló yi Èkó ká.

Èkó ṣe àjọ̀dún lóri agbami – Lagos celebrate on the Ocean
Àwọn Gómìnà ti ó ti jẹ lati ìgbà ti wọn ti dá ìpínlẹ̀ Èkó silẹ̀ ni wọnyi:
Gómìnà Kini – Ọ̀gágun Àgbà Mobọ́lájí Johnson – Gómìnà fún ọdún mẹjọ – àádọ́ta ọdún si ọdún méjìlélógójì sẹhin
Gómìnà Keji – Gómìnà Ori Omi Adékúnlé Lawal – Gómìnà fún ọdún méjilá – ọdún mejilélógójì titi di ogóji ọdún sẹhin
Gómìnà Kẹta – Ọ̀gágun Ori Omi Ndubuisi Kanu – Gómìnà fún ọdún kan – ogójì ọdún titi di ọdún mọ́kàndinlógójì sẹhin
Gómìnà kẹrin – Ọ̀gágun Ori Omi Ebitu Ukiwe – Gómìnà fún ọdún kan – ọdún mọ́kàndinlógóji titi di ọdún méjidinlógóji sẹhin
Gómìnà Karun – Alhaji Lateef Jakande – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹrin – lati ọdú́n mejidinlogoji titi di ọdún merinlelogbon sẹhin
Gómìnà Kẹfà – Ọ̀gágun Òfúrufú – Gbọ́láhàn Múdàṣírù – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mẹ́tàlélogbon di ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n
Gómìnà Keje – Ọ̀gá Adarioko Ojúomi Mike Akhigbe – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mọ́kànlélọ́gbọ̀n di ọdún mọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹhin
Gómìnà Kẹjọ – Ọ̀gágun Àgbà Rájí Ràsákì – Gómìnà fún ọdún mẹrin – ọdú́n mọ́kàndinlọgbọn di ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n sẹhin
Gómìnà Kẹsan – Ọ̀gá Michael Ọ̀tẹ́dọlá – Gómìnà fún ọdún kan àti oṣù mẹwa – ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n titi di ọdún mẹ́rinlélógún sẹhin
Gómìnà Kẹwa – Ọ̀gágun Ọlágúnsóyè Oyinlọlá – Gómìnà fún ọdún meta – ọdún mẹ́rinlélógún di ọdún mọ́kànlélógún sẹhin
Gómìnà Kọkànlá – Ọ̀gágun Mohammed Buba Marwa – Gómìnà fún ọdún mẹ́ta – ọdún mọ́kànlélógún di ọdún mejidinlógún sẹhin.
Gómìnà Kejilá – Ọ̀gbẹ́ni Bọla Ahmed Tinubu – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹjọ – ọdún mejidinlógún titi di ọdún mẹwa sẹhin
Gómìnà Kẹtàlá – Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Rájí Fáṣọlá – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹ́jọ – ọdún mẹwa titi di ọdún meji sẹhin
Gómìnà Kẹrinlá – Ọ̀gbẹ́ni Akínwùnmí Ambọde – Gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́ lati ọdún meji titi di òniYàtọ̀ si ìgbà Ìjọba Ológun, Èkó gbádùn ìdúróṣinṣin ni àsìkò Ìjọba Alágbádá tàbi Ìjọba Tiwantiwa lati ọdún kẹtàdínlógún sẹhin. Eyi jẹ ki ipinle Èkó mókè ju gbogbo ìpínlẹ̀ yókù lọ.
English Version
Continue Reading after the page break
-
Àpẹrẹ Ìsìnkú Ìbílẹ̀ fún Arúgbó ni Ilẹ́ Yorùbá
Ìnáwó rẹpẹtẹ ni ìsìnkú arúgbó jẹ́ ni ilé Yorùbá. Bi arúgbó bá kú ni ilé Yorùbá ki ṣe òkú ọ̀fọ̀ ṣùgbọ́n òkú ijọ àti ji jẹ, mi mu ni pàtàki bi irú arúgbó bá bi àwọn ọmọ ti ó ti dàgbà. Gbogbo ẹbi, ará àti ilú yi ó parapọ̀ lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún irú arúgbó bẹ́ ẹ̀. Àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ yi o ṣe oriṣiriṣi ẹ̀yẹ ìbílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lati gbé ìyá tàbi àgbà bàbá àgbà relé. Bi eléré ìbílẹ̀ kan ti nlọ ni òmíràn yio de, eleyi lo njẹ́ ki ilú kékeré dùn.
A o ṣe àpẹrẹ àṣà ìsìnkú ìbílẹ̀ fún arúgbó pẹ̀lú ni Ìbòròpa Àkókó ilú Yorùbá ni ẹ̀gbẹ́ Ìkàrẹ́-Àkókó ti Ipinle Ondo, orile-ede Nigeria.
English Version
Continue reading after the page break
-
Edi Alálà !!!
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? aku ijosin ifa toni to je ojo abameta, Olodumare ninu aanu re koni da emin wa legbodo lati le se pupo ijosin naa loke erupe o Ase.
Idanileko ti aaro yi jade lati inu odu mimo EDI ALÁLÀ, ifa yi gba awa omo eniyan niyanju wipe ki a mase ro ara wa pin, ifa ni opolopo lo ti ro ara re pin to siti so ireti nu wipe oun ko le se rere tabi lo lati ibikan sibi ikeji tabi dawole nkan ko si yori si rere, ifa sope kosi ohun ti Eledumare ko le se o, ifa wa fi afefe(efufulele) se akajuwe laarin awon nkan ti Olodumare seda wipe bi ako se nri afefe yi sugbon a ngba sara ko de sibiti ogo afefe ko buyo de lagbaye, bee gege naa ni igbesi aye omo eniyan naa seri o.
E jeki a gbo nkan ti ifa naa so.
Ifa naa ki bayi wipe:
Edi funfun ko níran
Atagoala ko mosù
Omo elésémopé
A difa fun èfùfùlèlè eyiti yio fe ka gbogbo aye won ni ki o karaale ebo ni ki o wa se nitori ki o ma baa rogun idena, obi meji, igba ewe ayajo ifa, èfùfùlèlè kabomora o rubo won si se sise ifa fun, bi èfùfùlèlè se bere sini nfe kaakiri gbogbo agbaye niyen to je wipe ko sibiti ki nfe de, gbogbo ibi ni okiki èfùfùlèlè kan de, o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin Olodumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi fun ori kookan wa wipe gbogbo ibi rere ti a ti ro wipe ako ni le debe ninu aye Olodumare yio sobe di aresepa funwa, okiki wa yio kan kaakiri agbaye si rere, afefe koni fe ko ma kan igi oko lara bi ara yin ba gba afefe ojo oni sara iwure ti mo se yi yio wasi imuse ninu igbesi aye yin oo Aaaase.
ABORU ABOYE OOO.Faniyi David Osagbami
English Version
Continue reading after the page break
-
Ọọ̀ni Kò Ṣe Rífín ! (Apá Kìíní Lati Ọwọ́ Daniel Adefare)
Oríadé, ọrùn-ìlẹ̀kẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ajunilọ mo júbà o.
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní “Kíkéré labẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì fádìyẹ” Káláyé tó dáyé, kékeré kọ́ ni Bàbá fi ju ọmọ lọ. Ọọ̀ni kìí ṣe ẹgbẹ́ ọba kọ́ba gẹ́gẹ́ ìtàn ti sọ́ ọ di mímọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ?
Eégún ilé kò ṣe rífín, òòṣà ọjà kò ṣe é gbálójú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọba Ẹnìtàn Adéyẹyè Ògúnwùsì, Ọọ̀ni tilẹ̀ Ifẹ̀ ri. Ẹni tó bá fi ojú di Ọọ̀ni, dandan ni kí àwówó wó.Eyín funfun báláí ni iyì ẹnu, ẹ̀jẹ̀ pupa yòò ni iyì òòṣà, àpọ́nlé ló yẹ olórí Ọba yoòbá gbogbo kìí ṣe ìwọ̀sí.
Ohun ti Ọba Rílíwànù Akiolú, Ọba Èèkó ṣe sí Ọọ̀ni kò dara rárá. A kò lè rìn kórí má mì nítòótọ́, orí bíbẹ́ kọ́ ni oògùn orí fífọ́ kẹ̀! Ó wu èdùmàrè ló gbórí ẹwà fún àkùkọ, ọ̀pọ̀ igi ló ń bẹ nígbó ká tó fí ìrókò jọba igi.Ẹ máa jẹ kí á torí ọ̀làjú tàbí òṣèlú gbàgbé àṣà wa. Àṣà ìbọ̀wọ̀ fágbà ni Yorùbá fi ń gbajúmọ̀ nílẹ̀-kílẹ̀. Àgbà kò ní ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí rárá, ipò làgbà.
Àràbà ni bàbá, ẹni a bá lábà ni bàbá. Ọba Adéyeyè lè jẹ́ ọmọdé sùgbọ́n ipò àti àyè tí ó wà gẹ́gẹ́ bí i ỌỌ̀NI ti sọ ọ́ di àràbà tí gbogbo ọba bá lábà. Bí èèyàn bá ta ará ilé ẹ̀ lọ́pọ̀, kò le rí i rà lọ́wọ̀ń.
Bàbá ni Ọọ̀ní jẹ́ láàárín àwọn lọ́ba-lọ́ba. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn Ọba tí kìí ṣe Ọba ní ilẹ̀ káàárọ̀-o-jíire lè máa ṣe àpọ́nlé tí ó tọ́ fún Ọọ̀ni, mo lérò pé ó tọ́, ó sì yẹ kí àwọn Ọba yorùbá ṣe àpọ́nlé ara wọn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ,pàápàá jùlọ fún olórí aládé gbogbo.
Mo kí Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II, kú àíbínú. N kò sàì gbóríyìn fún gbgbo ẹni tó da sí ọ̀rọ̀ náà ní pàtàkì jùlọ Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ GCFR, ààrẹ àná.Mo rọ́ Ọba Èèko ki ó máa bínú sí Ọọ̀ni lórí ohun tí ó lè fa ìwà àjòjì yìí. Àmọ̀nràn mi ni pé kí Ọba Akiolú ti Èèkó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ọ Ọọ̀ni àti gbogbo ọmọ yorùbá pé òun kò ní dárú asọ bẹ́ẹ̀ sorò mọ. Lákòtán ọ̀rọ̀ mi, Baba kìí bínú púpọ̀, Kábíèsí, ọba Adéyẹyẹ̀ ẹ fojú fo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ máa gbàgbé ọ̀rọ̀ àwọn Baba ńlá yín pé “Iṣu ẹni níi tọwọ́ ẹnị bepo” kí òwe jẹ́ ti ẹ̀yin àgbà. Kí ẹsin ọba kó joko pẹ́. Ilẹ̀ yorùbá kò ní dàrú o. Àṣẹ.
Tóò bí ó ti mọ ní í jẹ ìrẹ́mọ. Ẹ jẹ kí ẹyin mi di àkùkọ.
Ẹ ṣé púpọ̀.
Ọgbẹ́ni Daniel Adefare
08033234826 -
Iwure ojo ajé toni jade ninu odu mimo ogbe onigun.
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isimi ana o, Olodumare yio funwa nisinmi o, bi oni se je ojo ajé ao raje sokun ao raje sede ao si raje saiku baale orò o Ase.
Iwure ojo ajé toni jade ninu odu mimo ogbe onigun.
Ifa naa ki bayi wipe:
Kúkúùndùkú
Pété ìnàkí
Egbèje àgbàdo
Àgbàdo egbèje
A difa fun won nígùnmojò omo olówó eyo lojo ti won ni ki won o rubo ki won baa le lowo lówó, obi meji, opolopo owó eyo, opolopo eka, eru eko, eru akara, igiripa obuko ati igba ewe ayajo ifa, won kabomora won rubo won se sise ifa funwon, lati igba naa ni ara ìgùnmojò ti di olowo, won rije won rimun, won wa njo won nyo won nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin Olodumare won ni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Awon ara ìgùnmojò wa fiyere ohun bonu wipe:
Ìgùn re o omo olowo eyo
Ìgùn re o omo olowo eyo oo
Olowo eyo la npègùn o.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi wipe Olodumare yio pese opolopo owó ti ao fi sele aye wa pelu irorun funwa, ako ni ku sinu ebi oun ìyà, orisa ajé yio sawari enikookan wa loni o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.English Version
Continue after the page break.