NEW! Àǹfààní àgbàyanu fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ pàtàkì wa!Ka siwaju
38°C
16 November 2026
Atunyẹwo Iroyin Pajawiri

Ó Pọ́dún Mẹ́ta Lónìí Tí Aláàfin Adéyẹmí Re Barà.

  • April 22, 2025
  • 1 min read
  • 5 Views
[addtoany]
Ó Pọ́dún Mẹ́ta Lónìí Tí Aláàfin Adéyẹmí Re Barà.

Kò sẹ́ni tí ó ju sáyé, gbogbo wa la ó dìtàn. Aláàfin Àtàndá ti kópa ti wọn, wọ́n ti lọ. Ọdún kẹta rèé tí Aláàfin Ọláyíwọlá ọmọ Adéyẹmí yíjú kúrò níhìn-ín, Ọláyíwọlá kọjú sáwọn aláṣekù, Baba bá wọn lọ. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe é lẹ̀ là ń sọ, tó dìròyìn. Bí a ti ń sọ ọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ìbírònkẹ́ lónìí, àsìkò ń bọ̀ tí àwọn kan náà ó sọ nípa tiwa. Kí layé á sọ nípa tèmi-tìrẹ?

Ìlẹ̀pa dòdò kó dẹlẹ̀ fún Aláàfin Adéyẹmí, kọ́wọ́ ìbàjẹ́ ó sì má ba gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ 🙏

About Author

asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *