
Ogbontarigi agbaboolu omo Naijiria, Ahmed Musa, ti n le waju bayii ninu awon agbaboolu to rawon julo niluu Russia. Iroyin yii jade ni kete ti egbe agbaboolu re, CSKA Moscow jawe olubori nigba ti won pade pelu Dynamo pelu ayo meji sodo. Musa naa gba goolu kan wole ninu ifesewonse to waye lopin ose yii eleyii to mu apapo boolu to gba wole je mefa ninu liigi oreede Russia.
Tag: Àṣà Yorùbá
-
Ahmed (Amedi) Musa lo rawon julo bayii niluu Russia
-
Ohun to mu Odun Ominira eyi yato si ti igba ti Goodluck Jonathan wa lori oye
Ara opo awon omo Naijiria tun ya gaga si orile ede won lojo Alamisi to koja, nigba ti a se ayeye ominira odun karunlelaadota.
Kaakiri awon ipinle, opo eniyan lo ki akegbe won ku oriire, ti won si n soro lori ireti pe nnkan yoo pada bo sipo fun Naija.Awon onmoran woye pe igbagbo ninu ijoba Aare Muhammadu Buhari lo fa eyi, tori awon eniyan gba pe o fe fi otito inu tun ilu to.
Idi niyii ti ko fi yani lenu pe opo eniyan lo ra asia Naijiria, ti won si ta a si ara moto won.
Lori ero alatagba intaneeti naa, awon enyan n kira won, ti won si n ka aseyori Buhari.
Odun 2015 yii ko ni igba akoko ti orileede Naijeria yoo maa yo ayo ominira. Odun eyi to wole lo je odun marundinlogota (55) ti ilu awon eniyan dudu to poju lo lagbaaye yoo maa yo ayo bibo lowo awon oyinbo amunisin.
Bi o tile je wi pe teru-tomo pata ni won fo fayo lojo kinni osu kewaa odun 1960 latari akikanju, ifomoniyanse ati ilakaka awon akoni igbaani bi Nnadi Azikiwe, Obafemi Awolowo ati Ahamadu Bello; sugbon nigba to ya, irewesi n de ba awon omo Naijiria nipa yiyo ayo odun ominira eleyii ti opolopo gba gege bi omi inira.
Eleyii ko sadeede waye, jegudujera, riba gbigba, ojelu, aisododo, ainife ara ilu to gbile laaarin awon alase ati olori ile yii lo bu omi tutu si okan awon eniyan.
Aimoye ibeere ni awon eniyan n beere lati ojo pipe eleyii ti enikeni ko ri idahun si. Kilode ti Naijeria to kun fun wara ati oyin n sun lebi? Kilode ti omo eleran n jeegun? Kilode ti omo alaso alaari wo akisa kiri igboro?
Leyin eto idibo aare to waye lojo kejidinlogbon osu keta odun ta a wa yii, igbagbo awon eniyan ko ja wale eleyii to fun ireti awon ara ilu lagbara ninu isejoba Aare Muhammed Buhari.
Bi o tile je wi pe o pe ki Buhari to yan awon minisita ti won yoo jo maa sise gege bi igbimo, sibesibe iyipada to loorin ko sai foju han nipa ina monamona, igbogun ti iwa jegudujera, ifese mule eto abo ati igbenusoke eto oro aje bi baalu to setan ti o fo soju orun.
O ku ojo bi meloo kan ti ayajo ominiran odun yii yoo wole, bee ni atejade kan bere si ni fo kiri ori ero ayelujara eleyii to n se afihan iye owo ti ijoba to kuro loye, Ijoba Goodluck Jonathan, ti i na lori ayeye ayajo ominira ati eleyii ti aare tuntun to wa lode yii setan lati naa fun ayeye kan naa.
Atejade naa ni yii:
Ijoba Jonathan 2011:
Bilionu metala (13b)Ijoba Jonathan 2012:
Bilionu meedogun (15b)Ijoba Jonathan 2013:
Bilionu merinla (14b)Ijoba Jonathan 2014:
Bilionu mejilelogun (22b)Ijoba Buhari: 2015:
Aadorin Milionu (70m)Awon iroyin to jade yii tun bo mu inu opolopo dun eleyii mu won jigiri si ajoyo ayajo ominira odun yii ju ti ateyin wa lo.
Sugbon sa, ajoyo ayajo odun ominiran ko fi bee rinle ni awon ipinle bi Osun ati ipinle Oyo.Sebi awon Yoruba bo, won ni aja ti o yo kii ba eyi ti ko yo sere. Bi ijoba awon ipinle naa se je awon osise lowo ko je ki inu awon eniyan dun debi wi pe ara won yoo ya gaga.
Sebi bi oode ko dun, bi igbe niluu ri.
Orisun: Olayemioniroyin.com
-
Ajimobi ati Amosun Da Ara Ilu: Won Ni Ko Si Eko Ofe Mo

Lati inu iwe Iroyin Owuro to jade lose to koja ni iroyin naa ti jade wi pe Ajimobi ati Amosun ti pada ninu ileri eto eko ofe ti won se ileri re fun awon ara ilu. Won ni ki olomu da omu iya re gbe; won ni ki awon obi maa san owo idanwo asejade (WAEC) awon omo won funra won.Ki ni ero awon eniyan nipa igbese tuntun yii? E le ka awon ero ara ilu ninu linki isale yii.
-
E Wa Wo Ohun Ti Omokekere Yii Da Lara: Eleyii Koja Afenu So

Lara awon iroyin wa to ti jade tele, awon iroyin lori ate Olayemi Oniroyin, mo se lalaye wi pe Edua Oke ko da ile Adulawo gege bi ibugbe awon otosi ati alaini; awon olori wa lo so ilu wa di ero eyin ati akurete.
Olorun fun wa ni awon eniyan olopolo pipe, sugbon kaka ki won ri iranlowo nipa ironilagbara, pupo iru awon eniyan bee di eni itanu lai ni oluranlowo kankan.
Tuntun mii ti jade: Olayemi Oniroyin tun ti gbo nipa omode onise opolo nla kan ni orileede Uganda ti ile Adulawo.
Omokunrin kekere yii lo dara nla yii lati Mubende to wa ni orileede Uganda. Gbogbo awon ara abule ibi ti omo naa n gbe nise owo re ya won lenu pupo ju.
Omo kekere yii to igi papo, o fi se oko bogini pelu ero ayarabiasa.
Olayemi Oniroyin, mo ti n rise ona (art) to fakiki, eleyii tun jo mi loju.
Ki Olorun ba wa da omo naa si, ki Edua oke si ba wa ran oluranlowo si i.
Olayemi Oniroyin ni oruko mi, ilu Naijeria olokiki ni mo n gbe. Mo feran iyan pelu obe egusi ti won ko eran ogunfe le lori.
Emi kii mu oti lile o, sugbon ti mo ba ri Chivita to tutu, mo le maneeji re.E ku faaji opin ose!
-
Omo Naijeria Setan Lati Dije Fun Ipo Aare Orileede Spain
Ko to di wi pe ma kan lu agbami oselu ti n gbona felifeli bayii ni ilu Spain, nibi ti Arabirin Helen Mukoro to je omo ipinle Delta lati orileede Naijeria ti setan lati dije fun ipo aare orileede Spain, mo royin ki e gba mi laaye ki n ti owo bo itan awon isele to sele bi nnkan bi ogota si aadorin odun seyin ni ilu Amerika.Sebi won ni bi omode o batan, yoo ba aroba. Awon agbalagba ile Yoruba ni won ni aroba ni baba itan.
Kini je itan? Kini je aroba?Ti e ba fun mi laaye die si, mo fi dayin loju wi pe mejeeji ni maa salaye lai senuku sibi kankan.
Odun 1929 ni won bi gege bi alawo dudu omo ile Amerika ni Atlanta, Georgia to wa ni orileede Amerika.
Jije alawo dudu omo ile Amerika tunmo si wi pe orirun re tabi iran re se wa lati ile Afirika to je ile adulawo.
Nnkan bi ago mefa koja iseju kan, lojo kerin osu kerin, odun 1968 ni awon agbanipa yin-in ni bajinatu lojiji ni ile itura Lorraine to wa Memohis, Tennessee latari wi pe enu re ti mu ju nipa jija fun eto omoniyan, paapa julo, eto awon omo adulawo ile Amerika ati iponlogo re eleyii to lodi si eleyameya ni ilu Amerika.Bi won tile seku pa a ninu agbara eje to n san bi omi odo Ogunpa, sugbon ero re ati igbagbo re ko ba a wonu ese mefa lo.
Ni awon akoko yii, ilu Amerika je ilu ti won ri awon alawo dudu omo ile Amerika gege bi awon eniyan ti ko dogba pelu awon alawo funfun omo ile Amerika.
Won on te eto awon alawo dudu mole, won si n re won je nigbogbo ona.
Itan tile so fun wa wi pe won ko ka awon alawo dudu si eniyan eleran-ara, oju eranko inu igbo ni won fi n wo awon eniyan ti awo won ba dudu.
Bi alawo funfun ba wo inu oko nla akero, to ba ri alawo dudu lori ijokoo, ofin ilu Amerika nigba naa so wi pe ki eniyan dudu dide naro fun alawo funfun lati joko.
Iru igbe aye yii je ohun ti akoni yii lodi si nigbogbo ojo aye re gege bi alawo dudu omo ile Amerika.
Ni odun 1965, o salaye fun awon oniroyin wi pe ile Amerika je awon eniyan dudu ni gbese pupo gan-an latari imunisin tabi imunileru awon eniyan dudu to ti waye ni awon igba kan seyin ninu itan ile Amerika.O ni nipa sise eleyii, ile Amerika ti jebi tite eto omoniyan loju mole. Lara awon esun mi-in to menu ba ni ifiyajeni lona aito.
Lori awon esun mejeeji yii, o beere fun aadota bilionu owo ile Amerika ($50B) gege bi owo itanran lati san fun awon eniyan alawo dudu omo ile Amerika ati awon alaise ti won ti te eto won loju mole.
Martin Luther King Jr ko si mo lonii, won seku pa baba Yolanda Denise King leni odun mokandinlogoji (39).
Won pa oninuure nibi o ti gbe n sise Oluwa oba, awon ika eniyan pa oko Coretta Scott King nibi o ti gbe n kilo iwa ibaje.Sugbon oro akoni to so kale lodun 1963 ni awon onkotan agbaye so wi pe yoo maa wa titi lae bi Opa Oranmiyan ti n be lode Oyo Oba Lamidi Adeyemi III.
“Mo so fun yin, eyin ore mi. Bi o tile je wi pe a n dojuko isoro toni ati tola, mo si lala. O je ala eleyii to ridi mule ninu ala ile Amerika. Mo lala wi pe ojo kan orileede yii yoo dide lati gbe igbe aye to ni itunmo otito gege bi igbagbo re: ‘ A di otito yii mu gege bi eri ti wa, wi pe aparo kan ko ga jukan lo; ibi o si ju ibi lo.’
Mo ni ala wi pe lojo kan, ni ori awon oke pupa to wa ni Georgia, awon omo eru igba kan ati awon omo olowo eru igba kan won yoo le joko papo lori tabili kan naa gege bi tegbon taburo.”Die lara oro Martin Luther King niyii eleyii to se niwaju opo eniyan ni ojo kejidinlogbon osu kejo odun 1963 ni Lincoln Memorial, Washington D.C.
Ni akoko ti Martin Luther King n ro ala re fun awon eniyan nipa ojo iwaju awon eniyan dudu ile Amerika lodun 1963 ni ilu Washington, Barack Obama, omo ile Amerika alawo dudu, eni ti iran re se wa lati orileede Kenya, wa ni Honolulu leni odun meji nibi to ti n yi taya kiri adugbo ni orileede Amerika kan naa.
Leyin odun merindinlaadota (46) ti Martin Luther King ti ro ala re fun gbogbo aye, Barack Obama wo inu ile nla funfun lo ni Washington D.C. gege bi aare ile Amerika akoko ti o je alawo dudu.
Ala Martin Luther King wa si imuse nigba ti ilu Amerika gbe Barack Obama soke lodun 2009.
Nje a tun le fi okan si i wi pe ala yii kan naa maa wa si imuse ni ilu Spain?Arabirin Helen Mukoro to je omo ipinle Delta lati orieede Naijeria wo ilu Spain ni odun 1992 nibi ti omobirn naa ti rese wale to si ti ridi joko remuremu.
Onkowe ni, amofin ati agbaoje nipa ise otelemuye to dangajia tun ni pelu. Ninu osu karun-un odun yii, omobirin naa gbe apati lati du ipo alase ilu Denia to wa ni orileede Spain sugbon to fidiremi.
Isubu yii ko da omi tutu si lokan rara pelu bo tun se dide lati gbe apoti ibo fun ipo aare orileede naa.
Helen Mukoro ti da egbe oselu sile eleyii to pe ni Union De Todos, labe egbe oselu yii naa ni yoo si ti maa dije fun ipo aare eleyii ti yoo waye ninu osu kejila odun taa wayii.Gege bi alaye Helen Mukoro, itunmo Union De Todos to je oruko egbe re ni “wiwa ni isokan.”
Ibeere ti n fi maa kadi alaye mi naa ni wi pe: n je awon eniyan ilu Spain le fi owo sowopo pelu isokan lati gbe alawo dudu akoko wole gege bi aare orileede naa?Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ala mi ati igbagbo mi ni wi pe ni ojo kan, eni ti n je eran ogunfe , uyan Ekiti ati obe egusi ko ni loun jaye mo, nitori teru-tomo ile yii ni o maa fi ayokele se faaji lo je eja tutu nirole.
Olayemi Olatilewa
@OlayemiOniroyin -
E Wo Ohun Ti Awon Omo Ile Igbimo Asofin Se Lodun 1962
-
Odaju Abiyamo Fi Ina Jo Omobirin Eni Odun Merindinlogun Loju Ara: O Ni Omo Naa N Se Agbere

Omobirin odaran kan ni owo awon olopaa ti te ni agbegbe Ketu niluu Eko pelu bo se fi ero ayoonu iloso jo omo egbon re ti n gbe pelu re, Bimpe Badmus, omo odun merindinlogun, nidi pelu esun wi pe omobirin naa n ba omo lanloodu won lajosepo.Isele to sele ni opopona Ogunjimi ni obirin naa ti fi ayoonu iloso jo Bimpe loju ara, ikun ati itan omo naa pelu iranlowo awon awon ore meji kan ti won ba a mu omo naa duro.
Gbogbo awon onise ibi naa ni won ti wa ni gbaga awon olopaa bayii nibi ti won ti n jo “azonto” nigba ti Bimpe wa ni osibitu.
Lara oro Bimpe, “Iro ni gbogbo oro naa, ko si nnkankan laaarin emi ati omo lanloodu.”





