Tag: Àṣà Yorùbá

  • Àwon tí ó n gbélè sunkún síta fún ìrànlówó nígbà tí àwon adigunjalè jàwón lólè ní Bayelsa.

    Àwon olùgbé Opolo ní Yenagoa ìpínlè Bayelsa ni ìbèrùbojo ti gba okàn won léyìn tí àwon adigunjalè jà won lólè tán.
    Gégé bí ìròyìn se so, àwon olè yí kojá ogbòn tí won sì gbé àwon ohun ìjà olóró lówó bíi Ìbon, òbe, àkéé lówó, tí won fi lo ká arábìnrin tí a mò sí Jane nílé pèlú àwon míràn náà.
    A gbo wípé owó tí àwon olè yí jí lo kò ní ònkà pèlú àwon nkan míràn náà nígbà tí won wolé síwon lára tán, won wolé siwon lára láti ojú fèrèsì.
    A gbo wípé àwon adigunjalè yí lo láì sí eni kankan láti yèwón lówó wò. Àti wípé won kò pa enikéni bí kò se wípé won fi àpá sí àwon kan lára.
    Àwon ará àdúgbò n bèrè fún àbò tí ó péye láti gbawón lówó irú ìsèlè náà.

  • Mi ò le fé okùnrin tí kò bá le bámi sùn fún wákàtí méjìlá sí méèdógún.

    Mi ò le fé okùnrin tí kò bá le bámi sùn fún wákàtí méjìlá sí méèdógún.
    Arábìnrin kan tí a kò fi taratara mo orúko rè súgbón tí kò le jú omo odún méèdógún sí ogbòn kan ni ó so wípé òun kò le fé okùnrin tí kò ba le ba ní àjosepò fún wákàtí méjìlá tàbí méèdógún. Arábìnrin ní a gbó wípé omo bíbí orílè èdè yí tí a mò sí Nìjíríà ni.

  • Gómìnà ìpínlè Osun tí a sí Oyetola gba àwon èèyàn là nínú ìjàmbá okò tí ó selè ní òpópónà Ibadan sí Èkó.

    Ókéré jù èèyàn tí ó kojá néjìlá ni ó fara pa nínú ìjàmbá tí ô selè ní òpópónà Ibadan lo sí Èkó sùgbón tí Gómìnà Oyetola ti gba wón kalè.
    Ògbéni Isiaka Oyetola náà n lo sí èkó ni ojó náà kí ó tó di wípé ìjambá náa selè tí ó dì kò kalè láti ràn wón lówó. Ìjàmbá okò yí selè ní òpin Ibadan ní ìyànà Sagamu.
    Ní òpópónà Ibadan sí Ekoní ìpínlè Ògún ní agogo méjìlà àbò òsán.
    Oyetola nígbà tí ó débè ó jáde kúrò nínú okò rè láti ran awon tí ìsèlè yí selè sí lówó.
    Oyetola tún gbìyànjú báwon pe ilé-ìwòsàn ní kíákíá.
    Ìjàmba yí selè láàrin oko Toyota Corolla fúdú ati okò elérò méjìlá. Won ni oko elérò yí ti tàkìtì láìmoye ìgbà nígba tí ó tí so owó okò nù.
    Bí ó tilè je wípé bí ó se selè pò ju báyìí lo súgbón èyí tí a rígbó nìyí.

  • Bánà Omo Egbé APC tí ó n lo fún Gómìnà ìpínlè Kwara ni won lè sí iwájú agboolé àwon Saraki.

    Bánà Omo Egbé APC tí ó n lo fún Gómìnà ìpínlè Kwara ni won lè sí iwájú agboolé àwon Saraki.
    Ìròyìn kàyéfì…
    Omo egbé APC tí a mò sí Abdulrasaq Abdulrahman, tí ó n díjé fún ipò Gómìnà ìpínlè Kwara ti se bánà tí ó pò won sì ti rò wípé bí ó ti tó àti bí ó ti ye ni ó ye kí àwon pín bánà tí àwon ti fi owó tè káàkiri, ni won bá lè sí agboolé àwon Saraki tí ó jé alátakò won..

  • Tope Osoba se ayeye ojó ìbí rè nígbà tí ó pé omo odún métàlélógbò (33) pèlú àwon àwòyanu àwòrán.

    Temitope Osoba tí gbogbo ènìyàn mò sí Tope Osoba jé òsèré orílè èdè Nìjíríà tí ó sì tún jé olùko eré, won bí i ní ojó kejì osù kejìlá, odún 1985.
    Ó jé jé akékòó jáde ilé-èkó gíga ifáfitì Olabisi Onabanjo tí ó kó nípa èkó káràkárà.
    Òsèré tí ó rewà yí bèrè eré orí ìtàgé ní odún 2005 nígbà tí ó kópa fún ìgbà àkókó nínú eré tí a mò sí “Ijoya” láti owó Laide Bakare.
    Ó di gbajúgbajà òsèré ní odún 2009 nígbà tí ó kópa nínú “ogun mi” láti owó Dayo Amusan . Báyìí ó ti hàn nínú eré tí ó kojá ogún bí apeere, Abimbola, Anu oju mi láti owó Adesanya, Omotara Johnson, Gucci girl àti béè béè lo.
    Ó se ayeye ojó ìbí rè pèlú àwon àwòrán tí ó ta lénu nígbà tí ó pé odún métàlélégbòn.

  • Àwòrán télè ti Leo Babarinde Dasilva nígbà tí ó wà ní omo àgbákórùn.

    Àwòrán télè ti Leo Babarinde Dasilva nígbà tí ó wà ní omo àgbákórùn.
    Ní àná tí se ojóbò tí àwon eléyìbó n pè ni Thursday, won ni kí àwon wo èyìn wò.
    Ará ilé BBNaija télè tí a mò sí Leo Babarinde Dasilva náà wo èyìn wò nígbà tí ó pín àwòrán ìgbà èwe rè sì orí èro ayélujára insítágírámú.

  • Àwon Jagunjagun tí a mò sí Soldier ti pa ìko àwon Boko Haram ní Arege, Borno, tí won sì gbà àwon ohun ìja olóró ní owó won.

    Two Ikò Boko Haram ti fi ojú winá ogun won sì ti bá ogún lo, tí ojú won sì rí méwàá ni ojó kejìlélógbòn osù kokànlá odún 2018 nígbà tí won tún fé se bí ìse won ní Arege ní ìjoba ìbílè Mobbar ní ìpínlè Borno.
    Àwon akoni wa ti kojú ogún dàwón won sì ti jéyán won nísu.

  • Arákùnrin tí ó n se yahoo ni ó ti ya wèrè nígbá tí bàbá eè kú tán ní ìlú Benin.


    Kàyéfì nlá ni ó jé nígbà tí Arákùnrin kan ya wèrè ní ìlú Benin ní ìpínlè Edo.
    Gégé bí ìròyìn se so, òdókùnrin yí ni won fi èsùn kàn wípé isé kí á máa fi èro gbáni ni ó n se tí a mò sí Yahoo ni ó n se.
    Nígbá tí ó ya sòkòtò pénpé mó ara rè tí ó sì jókòó sí ilè’lè ní ìta gbangba, tí ó sì n jéwó àwon ìwà ìbàjé kan.
    Ìsèlè náa selè ní Agbior park by Ohovbe junction ní ìlú náa tí ó sì fa òpò èrò tí àwon ará àdúgbò sì fi se yèyé wípé àwon mòó dáadáa.
    Won fi èsùn kàn wípé ó ra okò tuntun fún bàbá rè kí ó tó di wípé ó kú, won so wípé ó n kà wípé òun ti fi òpò ènìyàn se ògùn owó.
    Nibi fídíò ti a rí wò nse ni arákùnrin yí n pariwo “Daddy, Daddy” nígbà tí ó fi ara rè se èsí ní ìta gbangba tí àwon èyàn sì ni kí ó máa jèrè isé owó rè.

  • Mr Harri se ìgbéyawó pèlú ohun èlò orin tí a mò sí guitar ní ìpínlè Eko.

    Arákùnrin kan ní orílè èdè Nìjíríà ti ya òpò èyan lénu látàrí sése ìgbéyàwó pèlú ohun èlò orin tí a mò sí guitar rè. Tí e bá rò wípé e ti ri tán , eléyìí tún ya ni lénu ò.
    Harri best ti pín sí orí èro ayélujára tí a mò sí Insítágírámú láti pín àwòrán òun àti guitar rè tí won sì múra bíi toko taya, nígbà tí ó ko ìfé tí ó ní sì orin.
    Ìsèlè yí selè ní ìpínlè Èkó, nígbà tí ó sì n ya èèyan ní enu wípé se iró ni àbí òtító.

  • Olùsò àgùntàn tí a mò sí pásítò Adeboye tí ó jé olórí àwon omo léyìn Jésù ti ìjo RCCG fún àwon akékòó ìmò adajó tí ó yege jùlo mérin ní Fìlà orí ri awon adájó àti aso won.

    Olórí àwon olùfokànsìn àti omo léyì jésù ti Ìjo àwon RCCG, gbogbo àgbáyé, Pásítò E.A Adeboye fún àwon akékòó tí won sèsè gboyè gégé bíi adájó mérin nínú ìjo rè ní àgbàlá HALL OF MERCY, Bwari ní ìpínlè Abuja, ní èbún.
    Nítórí àgbàlá Hall of Mercy yíì kojú da ilé-èkó náà ní, ní Abuja, pasito Adeboye jé kí ó di mímò wípé, enikéni tí ó jé omo àgbàlá náà tí ó se àseyege láti ilé-èkó àwon adájó náa yóò gba àmì èye aso àwon adájó àti fìlà rè.
    Àwon olóóri mérin náà ni:
    Adewole Oluwatofarati
    Ayomide Racheal Akinyemi
    Onwioduokit Ugongabasa
    Ananyi Emeka Emedo.
    Obìnrin méta àti okùnrin kan.