
Gégé bí ìròyìn se so, won ti fi ìgò gún omo odún mókàndínlógún (19) yánmayànma látàrí àwon èyà ara tí won bá ní owó rè, won bá omoníka àti ojú ara omo odún mérin okùnrin ní Awka, ìpínlè Anambra.
Afura sí náà, tí a mò sí Ògbéni Sunday Onwebenyi láti Emeziaka Mgbo ní ìjoba ìbíle Ohaukwu ní Ìpínlè Ebonyi, tí ó jéwó wípé òun pa omo náà pèlú àwon afura sí míràn ní ibì kan nàà.
Èyí selè nígbà tí òré bìnrin láti agbègbè kan náà tí n jé, omidan Blessing Eze, ni ó ti so fún kí ó lo sí àdúgbò kan ní ìlú Awka, níbi tí owó ti tè é, èróngbà won ni láti tún rí owó púpò si.
Won ti fáà fún àwon olópàá fún Ìwàdìí tí ó tó.
Tag: Àṣà Yorùbá
-
Àwòrán omo odún mókàndínlógún (19) tí won mú pèlú orísirísi èyà ara ní Awka.
-
Tonto Dikeh se tán láti se isé abe láti tún ara rè dá.
Tonto Dikeh se tán láti se isé abe láti tún ara rè dá
.
Gbajúgbajà àti ìlú mòóká òsèré tí a mò sí ìyá ìjo, Tonto Dikeh, ti gbe lo sí orí èro ayélujára Ínsítágírámú láti jé kí ámò wípé nse ni ó dàbí eni wípé òun máa se isé abe ojú míràn.
Tí a bá rántí dáadáa bíi osù méwàá séyìn ni ó so wípé òun fé se isé abe láìpé sì ni èróngbà rè wá sí ìmúse.
Ó gbe lo sí orí èro ayélujára láti pín wípé òun náa òpòlopò mílíònú náírà láti fi se isé abe náà . léyìn osú díè tí ó ti fi èyi se oge tán ni ó bá túngbèrò láti se òmìràn fún ìgbà èkejì.
Arewà tí ó tún jé ìyá omo kan ní ojo mérìnlá osú kokànlá odún yí (14/11/2018). Ojó rù, pín àwòrán òun pèlú Dr. Rasheed Ayobami Aranmolate nígbà tí ó bérè wípé se Oliver Twist ni. -
KÁDÀRÁ Ò GBÓÒGÙN
Adáni wáyé ti dáni sáyé ná.
Káwayé máyà tó sayé dàwáàlọ.
Òréré layé kò see wò tán.
Àyàfi ká gba kádàrá lókù.
Kádàrá ò seé kọ̀ láìgbà.
Ádíá f’ẹ́ja tó f’ibú selé.
Ádíá f’ọ́pọ̀lọ́ tó f’òkè s’ebùgbé.
Ọ̀pọ̀ló f’omi s’elé, ó fèèpẹ̀ s’ebùgbé.
Àdán s’ẹyẹ tán, ó tún s’eku.
Lọ́wọ́ ọba mi àrà tí ń sisẹ́ àràmàǹdà.
Kí gbogbo ẹyẹ ó máse bínú àdán mọ́.
Kí gbogbo ẹja ó máse bínú ọ̀pọ̀lọ́ gan.
Ìpín-ò-jọ̀pín nílé ayé ń bí.
K’óníkálukú gba ti ẹ̀ lókù.
Iná ń bẹ lábẹ́ asọ kóówá.
Bí ti ń jóníkálùkù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Iná tí ń jóni tá ò gbọdọ̀ jósí.
Iná tí ń jóni tá ò le è pa.
Iná abẹ́ asọ a máa jóni lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Ẹ̀dá tí ń sáré àtilà.
Kó rántí ẹni tó sáré là tí ò tọ́jọ́.
Ẹ̀dá tí ń sáré àtilu.
Kó rántí ẹni tó sáré lura rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Ẹni ọba mi òkè bá pá lórí kó dúpé.
Lọ́jọ́ tí wèrè bá mọlé onígbàjamọ̀.
Ẹkún ń lá, tí kò leè sun ni.
Olówó ń sunkún, ẹ̀yin lẹ ò gbọ́
Ẹdìẹ ń làágùn, ẹ̀yin le ò mọ̀.
Iná tí ń jóni lábẹ́ asọ.
S’ebí lára oníkálukú ní ń bẹ.
Iná tí ń jóni tá ò leè pa.
Iná abẹ́ asọ ni wọ́n pè bẹ́ẹ̀.
Bí ẹ r’ẹ́ni tó lówó lọ́wọ́ bí alówólódù,
Ẹ má rò pó ti ń dùn bí ìlù dùn-ùn dún.
Ohun tí ń rán lábẹ́ asọ rẹ̀ ń dùn-ún dénú.
Ènìyàn le lówó lọ́wọ́ láì l’ẹ́nìkan.
Ènìyàn le lówó lọ́wọ́ láì láya ńlé.
Débi wípé ó máa bímọ gan.
Obìnrin le lówó lọ́wọ́.
Obìnrin le lẹ́wà lọ́dọ̀,
Kó tún jẹ́ opó ọ̀sán gangan.
Lọ́wọ́ ọba mi àrà tí ń sisé àràmàǹdà.
Òbìrí layé ẹ̀yin ọ̀rẹ́.
Òbìrí layé ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi.
Ẹní lòrí ò ní fìlà.
Ẹni nì fìlà ò lórí.
Ẹni ra bàtà ò lẹ́sẹ̀.
Ẹní lẹ́sẹ̀ ò ra bàtà.
Oníkálukú abi ti ẹ lára.
Iná ń jó ògiri ò sá.
Òjò ń rọ̀ òrùlé téwọ́.
Sebí wọ́n gba kádàrá ni.
Ká gba kádàrá,
Káma jírẹ̀ẹ́bẹ̀,
Sọ́ẉọ́ ọba mi àrà tí ń sisẹ́ àràmàǹdà.
Kámá torí gbígbó ká pajá.
Kámá torí kíkàn ká pàgbò.
Kámá torí àwíjàre kítọ́ ó tán lẹ́nu.
Ẹni bá torí p’élé ayé burú,
Tó wá gbòrun alákeji lọ.
Ẹ báni bi wọ́n pé kin ni wọ́n fẹ́ bá pàdé níbẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀ẹ̀. -
Olódùmarè mà tóbi lóba ooo.
Olódùmarè mà tóbi lóba ooo.

Kíni olórun olódúmarè kò le se tán, Olódùmarè tó dá ayé òhun òrun tí ó sì so òrò sí órìlè ayé, òrò náà á máa jé Ifá tí ó fi rán òrúnmìlà baba àgbónìrègún.
Òdú ìfá ni ó sì n se atóka ohun gbogbo, odù ifá náà bèrè láti orí Èjìogbè dé Òfún méjì.
Olódùmarè ti se atóka rè sí orílè alàyè a sì rí odù Ejìogbè ní ara Eranko Ewúró.
Njé Olódùmarè yí kò tóbi bí. -
Olorì Basirat tí ó pé odún mókàndínlógún ni ojó mélòó séyìn ya àwon àwòrán tí ó wuyì.
Olorì oba àti ìyá ìbejì ni a gbó wípé ó máa n dá oba lóhùn láàfin àti wípé òhun ni ó máa n pèsè gbogbo nkan tí Kábìèsí fé láàfin àti ní orí èro ayélujára.
A gbó wípé kò sí ibi náà tí e ó ti ri Aláàfin tí e kò ni ri Olorì Ola níbè.
Olorì ti se ayeye ojo ìbí rè ní àrà òtò látàrí pínpín àwòrán tó yááyì. -
Òsèré Yvonne Jegede àti Oko è kí omo tuntun káàbò tí ó tún jé àkóbí won.
Gbajúgbajà Òsèré Yvonne Jegede Fawole àti oko rè dun nú nígbà tí won bí omo tuntun tí ó tún jé Àkóbí won. Bí ó ti lè jé wípé a kò tí mò bóyà ako ni àbí abo sùgbón a mò wípé ó ti bímo.
Yvonne tí ó se ìgbéyàwó ní osú Èrèlé (February) odún tó lo, ti bímo láìpé. -
Ká ṣojú ẹni Ká sẹ́yìn ẹni Orúkọ tí à á pe ìránṣẹ́ (ìbò) .
Òtítọ́ wọn kò sí láyé mọ́
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Ká ṣojú ẹni
Ká ṣẹ̀yìn ẹni
Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ọmọ ìkọ́fa
Ilé Àgbọnnìrègún
Baba kọ́won ní dídá ọwọ́
Wọ́n mọ̀ ọ́n dá
Ifá kọ́won ní títẹ̀ ilẹ̀Wọ́n mò ọ́n tẹ̀
Baba kọ́won ní ìkarara ẹbọ ní híha
Wọ́n mọ̀ ọ́n ha
Wọ́n ń jẹ ìtí eku
Wọ́n ń jẹ ìtí ẹja
Wọ́n ń gba ẹyẹ
Wọ́n ń gba ẹran
Wọ́n ń jẹ ọ̀tọ̀tọ̀ ènìyàn lérù
Baba wá ní òun ṣ’awo lọ sí apá kan òkun
Òun ṣ’awo lọ sí ìlà mejì Ọ̀ṣáÓdi ọdún mẹ́rìndínlógún kí òun tó darí dé
Òtítọ́ wọn kò sì láyé mọ́
Ni baba kó ewúrẹ́ fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Ni baba kó àgùntàn fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Ni baba kó adìẹ òkòkó fún pé kó mọ́ ọn tọ́jú
Ká ṣojú ẹni
Ká sẹ̀yìn ẹni
Ni baba ko ẹyẹlé fún pé kó mọ́ ọn tọ́júLẹ́yìn ọdún kẹrìndínlógún tí baba dé
Òtítọ́ wọn kò sì láyé mọ́
Eléyìun tí ba ewúrẹ́ jẹ́
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Eléyìun nì ba àgùntàn jẹ́
Àbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Eléyìun nì kó adìẹ òkòkó wọgbó
Ká ṣojú ẹni
Ká ṣẹ̀yìn ẹni
Eléyìun nìkàn ló tún ẹyẹlé ṣeÒtítọ́ wọn kò sí láyé mọ́
orúkọ tí à á pe ìrọ́kẹ́
Ifá ní eléyìun kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́ láí láí
Tí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọ́n má a fẹnu rẹ̀ ṣẹpọ́n ko ko ko
Aṣẹ̀yìn deni wọn kò wọpọ̀
Orúkọ tí à á pe ìrùkẹ̀rẹ̀
Ifá ní eléyìun kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́ láí láí
Bí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọ́n kó má a fẹnu rẹ̀ gbáyẹ̀ròṣùnÀbàtà ńlá abojú dẹ̀gun dẹ̀gun
Orúkọ tí à á pe ọpọ́n
Ifá ní eleyíun náà kò gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ tòun mọ́
Tí wọ́n bá ń dá’fá
Kí wọn má a fọwọ́ lọ̀ọ́ nímú
Ká ṣojú ẹni
Ká sẹ́yìn ẹni
Orúkọ tí à á pe ìránṣẹ́ (ìbò)
Ifá ní ìbò nìkan ni kí ó má a dá sí ọ̀rọ̀ tòun ní gbogbo ìgbàǸjẹ́ kínni ń bẹ lẹ́yìn tí ń tubọ?
Ìrànràn
Ìránṣẹ́ nìkàn ní ń bẹ lẹ́yìn tí ń tubọ
Ìrànràn
Ǹjẹ́ kínni yíò ma rànwá ṣe?
Ìrànràn
Ifá ni yóò ma a rànwá ṣe
ÌrànrànIfá yíò ma ṣe àrànṣe fún gbogbo Awo o!
– Ogbè Ògúndà (Ogbèyọ́nú)
-
Akékòó okùnrin tí ó ti wà ní ìpelè tí ó parí ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìlú Oko ni won yìnbo fún tí ó sì kú.
Arákùnrin kan ni won yìn ìbon fún ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìjoba ní Oko ní ìpínlè Anambra.
Gégé bí ìròyìn se so, olóògbé tí gbogbo èèyàn mò sí ‘ De moon’ jé Akékòó féè pari tí ó sì jé wípé odún yí ni yóò parí èkó rè, ni won ti yin ìbon fún ní alé ojóbò (Thursday) tí se àná. Agbó wípé eka-èkó Banking and Finance ni ó wà ní ilé-èkó náà.
Àwon akékòó tí ó n gbé ní inú ogbà yí ti è ti ñ bèrú tèlè kí ó tó di wípé èyí tún selè.
Ìdí tí ó fa ìbon kò tí yé eni kankan, bí àwon kan se so wípé àwon omo egbe òkùnkùn ni ó yin ìbon náà, tí àwon kan sì so wípé olóògbé n ló èro ìbánisòrò rè mó àwon tí ó yìnbo yí lówó kí won tó paá.
Ìsèlè yí ti kó jìnìjìnì bá òpò akékòó. -
Davido àti Kiss Daniel nínú o okò ojú òfurufú.
Davido àti Kiss Daniel nínú o okò ojú òfurufú.
Gbajúgbajà olórin àti ìlú mòóká olórin tí gbogbo ayé mò sí Wizkid àti Kiss Daniel ya àwòrán papò nínú okò ojú òfurufú aládani. Nse ni ó dàbí eni wípé won fé jo ko orin tí yóò mìlú tìtì papò.
Nse ni ó dàbí eni wípé òré tímó tímó ni won báyìí -
Toke Makinwa nínú aso ìwè nígbà tí ó lo sí èbá òkun ní ìlú Èkó.
Gbajúgbajà ò n lò èro ayélujára tí a mò sí Toke Makinwa tí gbé ògo tí olórun fún hàn, nígbà tí ó gbé àwòrán ìgbà tí ó wo aso ìwè sí orí èro ayélujára tí ó n jé Ínsítágírámù .
Àwòrán tí ó gbòde yí ni ó yà ní èbá òkun ní ìlú Èkó. Toke tí won so wípé bí ó bá yá ti è yóo ju ti Kim Kardashian lo.