Home / Àṣà Oòduà / Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Ọdún orò gbìnà yá, ìdájí ní àwọn olórò yóò fi máa yíde ìlú níṣẹ̀yin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe aifẹsọ kebosi,lai rẹni jo o,ati pe n ta o ba fẹ o bajẹ,o ni bi o ṣe yẹ ka ṣe e,eyi lo bi atunse abẹnu lati fopin sawuye wuye to waye latari aawọ to suyọ laarin awọn onisese ati awọn ẹlẹsin meji ti o ku(Kitẹẹni ati Musulumi).
Wayi o, igbakeji alaga fun ẹgbẹ agbaagba nilu Isẹyin, Alhaji Bọlaji Kareem, ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan lori aawọ ọrọ sise nilu Isẹyin.
Kareem, ẹni to soju Asẹyin nibi ipade ipẹtu saawọ kan ti ẹgbẹ agbaagba naa seto salaye pe, lasiko to n ba lroyin Owurọ Yoruba sọrọ ni, awọn igbimọ Imaamu ati Alfa nilu Isẹyin, to fi mọ ẹgbẹ ẹlẹsin ọmọlẹyin Kitẹẹni,CAN atawọn
abọrẹ oro mẹrẹẹrin nilu naa, lo peju sibi ipade ọhun.

Nibi ipade naa lo ni wọn ti fẹnu ko lati jẹ ki ogun o sinmi, ti awọn oloro yoo si maa se oro wọn lati aago marun aabọ irọlẹ si marun idaji, ti wọn ko si ni yaju si ẹnikẹni.
Bakan naa, etutu oro ti gbera nilu Isẹyin lọjọ Aje pẹlu bibẹ aja sidi Ogun to wa loju ọja ilu naa.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo