Home / Àṣà Oòduà / Akékòó okùnrin tí ó ti wà ní ìpelè tí ó parí ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìlú Oko ni won yìnbo fún tí ó sì kú.

Akékòó okùnrin tí ó ti wà ní ìpelè tí ó parí ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìlú Oko ni won yìnbo fún tí ó sì kú.

Arákùnrin kan ni won yìn ìbon fún ní ilé-èkó gíga polytechnic ti ìjoba ní Oko ní ìpínlè Anambra.

Gégé bí ìròyìn se so, olóògbé tí gbogbo èèyàn mò sí ‘ De moon’ jé Akékòó féè pari tí ó sì jé wípé odún yí ni yóò parí èkó rè, ni won ti yin ìbon fún ní alé ojóbò (Thursday) tí se àná. Agbó wípé eka-èkó Banking and Finance ni ó wà ní ilé-èkó náà.
Àwon akékòó tí ó n gbé ní inú ogbà yí ti è ti ñ bèrú tèlè kí ó tó di wípé èyí tún selè.
Ìdí tí ó fa ìbon kò tí yé eni kankan, bí àwon kan se so wípé àwon omo egbe òkùnkùn ni ó yin ìbon náà, tí àwon kan sì so wípé olóògbé n ló èro ìbánisòrò rè mó àwon tí ó yìnbo yí lówó kí won tó paá.
Ìsèlè yí ti kó jìnìjìnì bá òpò akékòó.

About Awo

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...