
Author: Awo
-
Ooni ti ile-ife ní ìdí òpe àgùnká .
Ayeye Odún ifá àgbáyé eléyìí tí ó wáyé ní òkè-ìtase ní ilú ilé-ifè. Ooni rèé ní ìdí òpe àgùnká ní ibi tí mùtúmùwà ti ń se àdúrà sí ìsèdá won, kódà oba náà kò jáfara.

-
Ìwúre Òṣù Tuntun
Bí ÒṢÙ bá yọ loke terutọmọ niiri,
omi ajipon kiiru, ninu ÒṢÙ kẹfa yi aye gbogbo wa yio toro minimini, bi Ọgẹdẹ ba pọn ará aa dẹẹ, ara oni ni emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, àtijẹ atimu koni jẹ inira fún wa, tọtuntosi ni ẹiyele fi nko ire wale, ire owo ire ọmọ ire ile tuntun ire ọkọ àti aya tuntun yio wọle wa wa, nibikibi ni origun mẹẹrẹrin ayé, tí àwọn ooloore wà wá, Ọlọrun tio ṣé àwáàrí Aake nínú omi, nínú ÒṢÙ yi ooloore wà yóó wá wá rí, yio sí fí ire wá l’ewa lọwọ,
Kọkọrọ Ayọ rẹ yio tẹ ẹ lọwọ,
Bí akeregbe bá fọ ŃṢE nii dẹ̀hìn lẹ́hìn odo, ori buruku yio dẹ̀hìn lẹ́hìn gbogbo wa, Ipọnju, aṣeeri, amubọ, ijakulẹ, afaa’to, idiwọ, idena, àti ẹti yio dẹ̀hìn lẹ́hìn wa, ìbànújé, ẹkun ajọsun, ẹkun adasun, ẹkun asunrin koni jẹ ti’wa, àṣẹ oooo,
ogun idile, ogun ile binukonu, ogun ibi ìṣẹ, ogun arinako nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣẹ wọn wọlẹ pátápátá nínú aye wá àmìn, Ohùn Ayọ tí yio mú inú wá dùn tí ọpọlọpọ ènìyàn yio bawa se ajọyọ rẹ nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣé fún wa nínú ÒṢÙ tuntun yìí iṣẹlẹ iyanu Ayọ tí kó i ti ṣẹlẹ rí nínú ẹbí wá yio ṣẹlẹ nínú aye emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, tí àwọn ènìyàn yio fí máa fí orúkọ tuntun pé wa. Àmìn.
Ọmọ wá kóni Kú,
Ọkọ wá kóni Kú,
Aya wá kóni Kú,
Ojú kiipọn iṣin ki o má LÀ afaila ọjọ bí ọjọ bá tí LÀ gbogbo wà ni láti LÀ, ṣẹkẹrẹ kì bá wọn rode ìbànújé, ìbànújé oni kàn wá lagbara elédùà, àṣẹ gun. Ao ṣégun oṣo ilé àti ajẹ ode, ao rẹyín odi.
Otiri bẹẹ, nítorí bẹẹ lewurẹ nke kó’ni yí padà. NÍ opin ÒṢÙ kẹfa yi ao Jọ gbé igba Ọpẹ Àmín oooo oooA ku ÒṢÙ tuntun o, yio tuwa Lára ooo koni le koko mo wa Àmín àṣẹ oooo.
-
A kú òsè jàkúta.
Sango oooo
Olukoso ayanran ina
Ina loju, ina lenu
Sangiri, lagiri
Olagiripapa figba edun bo
Eefin ina la n da laye
Ina nbe lodo oko mi lorun
Abaabe ooooooooo
Abaabe laba Se fun SANGO
Emi Se SANGO labaabe
Agbenajo, Agbenayan
Agbenarababa kari bi Olodumare
Imumuna eledumare itara ni gbaye
Alaramoka ti I deru bojo
Aduloju, Adulenu
Ajo lagbon isale woiwoi
Kee wolu baale ndifa
SANGO koti wolu
Timo fi n gbo bata leyin Odi
SANGO gbemi, ewe gbemi
Awalawulu,ogbojo aseru bote
Akinkanju Akoni ti yona lenuKaabiyesi Olukoso!
Kaabiyesi Olukoso!!
Kaabiyesi Olukoso!!!A kú òsè jàkúta
-
Àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó tokotayà yí ti won pàdé nígbà tí won ń sin orílè èdè won lówó ní odún mérin séyìn.
Arábìnrin Nìjíríà kan tí a mò sí Rosemary nípa eni tí yó sèsè di oko rè Láìpé odún màrún-ùn séyìn, nígbà tí won ń sin orílè èdè won lówó ní Kaduna ti pín àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó won.
Wón dìjo wo aso ìsìnlú won pèlú bàtà aláwò kan náà.
-
Fúlàní darandaran pa àwon èèyàn ní ojú ònà Makarda ní òpópónà Makarda.
Óní òun so gbangba gbàngbà ni Láì bèrù enikéni :báyìí ni Adamu Donald Dekwagh, wípé enikéni kò gbodò sùn nígbà tí igbákejì Ààre orílè èdè lo kí won ní Benue ní ànà yí tí àwon wòólì méjì àti darandaran pa. Óní àwon Fúlàní darandaran ti di p’àyàn p’àyàn.
-
Òdókùnrin kan ní àwon olópàá yin ìbon pa nígbà tí won fé parí ìjà ní Ajegunle.
Òdókùnrin kan tí a gbó wípé ó jé omo ogún odún ni a gbó wípé won fi èsùn kàn àwon olópàá Látàrí ìbon tí won yìn pa Òdókùnrin yí, nígbà tí won ń parí ìjà lówó láàrin àwon ìkò ológun méjì ní agbègbè Ajegunle ní ìpínlè Èkó. Kí olórun te sí aféfé rere.
-
Paul Okoye níbi tí ó ti ń bá àwon ìbejì rè Nadia àti Nathan seré .
Paul Okoye tí a mò sí Rude boy ni ó pín àwòrán tí ó rewà yí nígbà tí ó ń lo àsìkò pàtàkì pèlú àwon ìbejì rè Nadia àti Nathan seré èyí tí ó pín sí orí èro ayélujára (instagram)..
-
Kemi Olunloyo so báyìí wípé! Àwòkóse burúkú gbáà ni Linda Ikeji àtiwípé òun ni àwòkóse there.
Kemi Olunloyo so báyìí wípé! Àwòkóse burúkú gbáà ni Linda Ikeji àtiwípé òun ni àwòkóse rere.OK olunloyo so òpòlopò àsírí nípa oyún inú Linda Ikeji àti nípa ara rè pàápàá.
Àtiwípé Linda Ikeji ti kó bá òpòlopò òdóbínrin. -
Sùúrù lógbà.
Ìsé kìí se ohun àmúseré
Ìyà kìí se ohun àmúsàwàdà
Ebi ń pamí kìí mérìń p’ani
Sebí ebi kìí w’onú
Kí òrò míràn wòóOjú tí ń kúkú pón isin
Kìí se àpón ku
Bí kòse àpónlà
Bówù kópé títí
Ìyà ayé eni ń bò wá d’ópin
Sùúrù tó kúkú l’ójó niÀforítì ló kúkú se pàtàkí
B’órí bá pé n’ílè á kúkú d’ire
Sùúrù lógbà -
A o ni ri ogun aisan
A o ni r’ogun aisan!
Ifa ni:
Pere ni tewe iyeye, aloye ni ti peregun;
Piri l’eye olongo n ji;
A kii b’okunrun eye lori ite;
Gege lowu alantakun n fuye;
Ota kii ku, ota kii run;
Koko lara ota n le;
Ojojo kii sokuta lale odo;
Aluti la n lu eru oko;
Aluti la n lu eru ada;
Ere kii ba eri wo;
Ko ba won wa kii ba won lo;
Ope kii ba igi oko wo’we;
Efun kii mu igun, edi kii mu alakan;
Ota t’ota pa ka sai segun ota fun wa!
Aase!
Ao ni ba won ku iku ajoku!
Edi, efun, asasi ko ni mu wa ati awon tiwa!
Aaaaaaaaaaaase.