Ẹ jẹ ka jọ gbadura fun Ẹda Onile-ọla pe bi wọn ṣe ṣe tọdun yii ni wọn yoo ṣe tẹẹmi-in towo-tọmọ, ninu ilera pipe ati aiku ti i ṣe baalẹ ọrọ.
Author: ayangalu
-
Bàbà wá Lérè paimo pé ọgọ́rin ọdún lónìí (80)
-
Àmọ̀tẹkùn ni wọn yóó maa pe orúkọ ikọ̀ tó n pèsè ààbò yíká ilẹ̀ Yorùbá – Akeredolu
Àmọ̀tẹkùn ni wọn yóó maa pe orúkọ ikọ̀ tó n pèsè ààbò yíká ilẹ̀ Yorùbá…..Akerdolu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe Yoruba bọ ,wọn ni Ogun ti yoo wọle koni,ọna la a tii pade ẹ lo bi ọrọ ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu sọ,bi o ṣe kede pe Amotẹkun ni wọn yoo maa pe orukọ ikọ to n pese aabo yika ilẹ Yoruba.
Bẹẹ ba gbagbe, lọjọbọ ni ipade eto aabo tun waye lati wa ojutu si awọn ipenija aabo to mẹhẹ to n ba ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria naa finra.
Awọn gomina ati ileesẹ ọlọpaa si ti se agbekalẹ igbimọ alaabo kan ninu eyi taa ti ri awọn osisẹ agbofinro ati awọn ọmọ ẹgbẹ akọya fun ilẹ Yoruba, OPC, awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn asọgbo.“Àsìkò yí ló yẹ kí Yorùbá fi ìmọ̀ ṣọ̀kan”
Ni itẹsiwaju abọ ipade naa, gomina Akeredolu ti gbe ọkọ nla Hilux bii ogun ati ọkada ọgọfa kalẹ fun ikọ Amọtẹkun naa, eyi ti yoo wagbo dẹkun fun awọn eeyan to n pagidina eto aabo lẹkun Kaarọ Oojire.Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, Kọmisana feto iroyin ati itaniji nipinlẹ Ondo, Donald Ojogo, salaye pe lati
igbadegba ni igbogun ti eto aabo to mẹhẹ yoo maa waye, eyi ti awọn gomina n se atilẹyin fun.Ojogo ni gbogbo awọn ọdaran to n fi igbo boju lawọn yoo fin jade bii okete, ti wọn yoo si sa kuro tefetefe jinna sawọn
ilu to wa nilẹ Yoruba.O wa fọwọ gbaya pe laipẹ ni wọn yoo si asọ loju eegun ikọ Amọtẹkun naa, ti wọn yoo si kawọ ikọlu awọn ọdaran to n waye nilẹ Kaarọ Oojire duro.
-
Adúmáadán Àjèjé
Ẹmu daada ní ń bẹ nínú ahá
Ògùrọ̀ àtàtà ní ń bẹ nílẹ̀ akèrèǹgbè
Ọtí ò dá, àlejò ò lọ!
Ẹni ọtí kìí tí Adúmáadán
Adúmáadán Àjèjé
má gbádùn ara rẹ lọ!‘Òògùn ibà ni, òògùn ibà ni,’
Bí eré, bí eré ìyálé ilé mútí yó!
Ẹmu lásán ni kìí pàayàn
Àṣẹ̀yínwá àṣẹ̀yìnbọ̀ baálé ń tọ̀ sí ṣòkòtò.
Akúwárápá abitọ́ funfun lẹ́nu.
Èpè akèǹgbè ọmọ a jà lóòjọ́.Orin:
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Bó ṣegbá kan bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Bó sì ṣèjì n ò kọ̀ bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Sá ti bùn mí lẹ́mu- bùn mí.Adúmáadán Àjèjé ìfẹ́ rẹ ń pá mí lọ!
Adúmáadán ọmọ dúdú bí i kóró iṣin
Adúmáadán jọ̀wọ́ arẹwà eèyàn!
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu- bùn mí Adúmáadán jẹ́ n rẹ̀ǹgbẹ ìfẹ́.
Adúmáadán má lókùú èèyàn lọ́rùn!
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu ìfẹ́ mu jọ̀wọ́ jàre!
Àdúmáadán mo fẹ́ ká jọ ma mẹ́mu ìfẹ́ pọ̀!
©#Ká_rìn_ká_pọ̀ -
Odù Ifá Mímọ́ Ọ̀bàrà Bubu
Ekáàrọ̀ọ́ ẹ̀yin ènìyàn mi, aojiire bi? Oni a sanwa o, ao rí tiwa se loni, gẹ́gẹ́bí òní ṣe jẹ ọjọ́ àíkú, gbogbo wa koni kánjú ku lágbára Olodùmarè àṣẹ.
E jékí a fi odù ifá mímọ́ ọ̀bàrà bubu yi ṣe ìwúre ti aarọ yìí.
Ifá náà ki báyì wípé:
Òkún ṣàn
Ó relé òkun
Òsá ṣàn
Ó relé ọ̀sà
Óní Alárá nwọ ogun lọ o pa ìyán lórí òun
Óní Ajerò nwọ ogun lọ o pa ìyán lórí òun
Óní sebi òun lo se òun ọ̀pẹ̀ èlìjù ti imọ̀ orí òun wá kù jééré
Òrúnmìlà ni kí wọn mú ajá kan ki wọ́n wẹ lagbo ifá ki wọn sọ orúkọ ajá náà ni “ojú ọ̀pẹ̀”
Moni moti ṣe bẹẹ bara mi àgbonmìrègún
Òrúnmìlà ni ṣé mo mọ orin tí màá máa kọ?
Moní rárá èmi kò mọ́
Òrúnmìlà ni kí ma so wípé:
Mí tì bímọ
Mí tì lọ́yà
Ojú ọ̀pẹ̀ mèi ò( ojú ọ̀pẹ̀ ni mo nwo)
Ojú ọ̀pẹ̀
Ééye
Ojú ọ̀pẹ̀ mèi ò
Ojú ọ̀pẹ̀.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, mosè ni ìwúre laarọ yi wípé ifá kòní dójú ìwúre tìwa lọ́jọ́kọ́jọ́, gbogbo ìbéèrè wa lọ́wọ́ ọ̀pẹ̀ ni yio máa wá sí ìmúse lágbára Eledumare, gbogbo àwa ti a ntẹle ifá ni ao máa lẹ́nu ọpẹ̀ nínú àṣeyọrí ati ìgbéga nigba gbogbo lasẹ Eledumare ááse.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.English version when you continue after the page break
-
Fayose kò mo̩ bò̩ò̩lì àti àgbàdo je̩ tó mi,àmó̩… – Fayemi
Gomina ipinle Ekiti, Dr Kayode Fayemi lo n salaye yii nibi eto ori telifison Kan ti arabinrin Morayo Afolabi n dari re.
Leyin ti gomina dahun orisiirisii ibeere ni arabinrin naa wa tun beere asepo to wa laarin oun ati gomina ana ni ipinle naa, Alagba Ayodele Fayose.
Fayemi ni asepo to dan moran wa laarin awon. O ni koda awon pade ni ode kan ti Ojogbon Afe Babalola ti lo gba ebun laipe.
O ni awon si soro daadaa, koda awon tun da apara.
Fayemi ni ko si ija tabi ita laarin awon. Ibe naa ni gomina Fayemi tun ti dahun ibeere iyato to wa laarin awon ti kii se eebu. O ni Olorun lo da onikaluku ni otooto.
O ni gbogbo nnkan daadaa ti Fayose n je ni oun naa le je, o ni koda Fayose gan-an mo pe ko lemii oun nibi agbado ati booli jije. O ni amo oun ko le maa jee laarin oja bii tire. -
E fun mi ni owe to ni Ile(house) ninu ?
Edakun gbogbo ile, e fun mi ni owe to ni ile(house) ninu.
E seun.
-
Owonrisogbe – Ifá Naa Ki Bayi Wipe: Biijo biijo…
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku orire osu Ògún tuntun to bawa layo ati alaafia, osu naa yio sanwa sowo, somo, sile kiko, moto rira, ire oko/aya ati aiku baale oro yio je tiwa, Ògún lákayé yio lana funwa o Àse.
E jeki a fi odù mímó Owonrisogbe you se ìwúre ibere osu yi.
Ifá naa ki bayi wipe:
Biijo biijo
Biayo biayo a difa fun agbado lojo ti nroko alere odun, won ni ko karale ebo ni ki o wa se nitori ki o baa le ko ire bo wa sile, obi meji, eru eko, eru akara, igbin, irukere, obuko ati igba ewe ayajo ifa, agbado kabomora o rubo won si se sise ifa fun nigbati agbado doko aloro odun won fi fole nigbati o maa di ojo karun agbado bere sini nwu Omi igbin to fi rubo lojo kini ana esu odara nto Omi naa sidi agbado, agbado wa dagba o yomo irukere to tun fi rubo lojo kini ana esu odara fi le Omo agbado lowo, awon Omo agbado dagba won dogbo won si tobi daradara inu agbado dun o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa, o wa fiyere ohun bonu wipe; nje kini agbado mu toko bo? Igba Omo lagbado mu toko bo igba omo, kini agbado tun mu toko bo? Igba aso lagbado mu toko bo igba aso.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi ati ninu osu tuntun yi wipe oro ayo ati idunnu yio je tiwa, ako ni ri oro ibanuje igbesi aye wa yio so eso rere, gbogbo adawole wa yio yori si rere ninu osu yi, ao ni ayo ayeraye aaaseee.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO. -
Iya mi Osun Sengese
Iya mi Osun Sengese Ladekoju Ebora ti n gbenu omi
Lagbolodo,Iwo ni mo nkee si o.
Osun ma n bo o
Yago lona o.
