Looking at Odu Ifa, “Irosun Oyeku” cast today for Ose Ifa, I can advise all Priests and Priestesses to imbibe calmness in their characters so that they can always achieve their desires. Secondly, the stanza contains one of the Yoruba wise sayings which is to prove again that Ifa is the encyclopedia of the Yoruba language. Just listen to the verse as follows:-
Igba kele kii fo Awo kele kii ya Aso kele kii gbonya Ohun a ba feso mu kii baje Ohun a ba fagbara mu nii le koko bi ota Adifa fun Orunmila Baba nlo ree gbe Kele niyawo Ki la fi mu kele dele more Eso eso nla fi nmu kele de’le Eso eso
Calabash handled with care does not break Ceramic handled with caution does not shatter The garment worn with elegant care does not shred abruptly Things handled with caution do not spoil Those enforced violently present stony difficulties Divine message to Orunmila When courting Kele for a wife How did we win Kele’s hand ultimately Gentleness and perseverance, that was how we won Kele’s hand Patience and gentleness.
Ifá gba gbogbo akápò re niyanju wípé ki won o rubo nitori ki a baa le ri orí ayé wa, ki a baa le de ile ileri, ifá ni nkan yio soro tabi le die fun awon ti won ba koti ogboin sebo, ifá ni atirise tabi ri ona lo yio fe soro funwon, ifá ni ki a rubo nibe, ifá ni tiwa koni soro se, ifá ni ao ri ona lo laye.
Ifá ni ki a bo ògún lákayé, ifá ni ògún lákayé yio lana funwa o, obi meji, ako aja, agbata emun, epo ati iyo, ti a ba si ti bo ògún lákayé yi tan ki a gbe orí aja naa le lori. Ifá si tun sope ki a rubo, ki a ni aporipo/karahun orí ewure ati sakiti aro, ki a fi rubo nibe nitori ki a baa le gun oke olà.
Ifá naa ki bayi wípé: Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi ògún lákayé ba pa igba aja, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi Ìja ba pa igba akuko, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi Òsun ba pa igba erukuku, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi Sango olukoso ba pa igba agbo, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi Obàtálá ba pa igba etú, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi osanyin mole lakodi ba pa igba ahun, orí re ni yio maa jàwá
Òrúnmìlà lo di àjàwárí Moní o di àjàwárí Òrúnmìlà ní bi òun èdú alájogun ba pa igba ideregbe, orí re ni oun yio maa jàwá
Moní Òrúnmìlà kaa mehùnrìn Moní kilode ti o fi nfo bi èdè ti o fi nfo bi èyò? Òrúnmìlà ní oun ko fo bi èdè, beeni òun ko fo bi èyò bi ki nse akápò toun ti won dafa fun Moní toba je bi ti akápò tire ni nko, kini nkan to maa se to maa fi ja rori ayé re? Òrúnmìlà ní ki won sofun akápò toun wípé ki o lo ni aporipo orí ewure, ki o ni sakiti aro ki o maa fi rubo, oni yio ja rori ayé re Akápò kabomora o rubo won se sise ifá fun, lati igba naa ni akápò ti rori ayé re to ti de ibi ire re, o wa njo o nyo o nyin babaláwo awon babaláwo nyin ifá, ifá nyin Eledumare, oni nje riru ebo a maa gbeni eru àtùkèsù a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami ni jebutu ire, jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
AKOSE IFÁ NAA: Ao ki sakiti aro mo inu iho ori ewure nibi ti a ti yo obuntun re yen ti yio kun, ao fiyerosun tefa yi soju opon, ao ki ese ifá yi si ao se adura si daadaa ao bu iyerosun naa si gbogbo ara aporipo orí ewure naa, ao lo gbe soju atana(oju ona), tabi ki a beere ibiti a maa gbesi lowo ifá ti koba si oju ona ti a maa gbesi. Eyin eniyan mi, mose ni ìwúre wipe Eledumare yio jeki a ja rori ayé wa o, eleda wa yio jeki a goke olá, orí ire ati igbega koni je eewo funwa, ao ri ona lo laye o aaasee. ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o Eledumare ninu aanu re yio fi ire gbogbo wa wari loni o Àse. Ifá yi gbawa niyanju wipe ki a bo ifá pelu obi meji ati agbebo adiye, ki a si se akose ifá yi ki a fi sin gbere si orokun wa mejeeji yika, ifá ni oun koni jeki a rogun ejó o, ogun wahala koni je tiwa, ifá ni ejo yi yio fe sele laarin awa ati eniyan kan tabi egbe si egbe, ifá ni mura nibe ki a ma baa sewon tabi gbere itiju o. Ifá naa ki bayi wípé:
“Otín ni otín ejó” Obì ni obì ìmòràn Emun àìrírí ni emun àràjoòjo A difa fun kéreré ìpàpò a bu owo kan fun àgbàgbà ìpàpò lojo ti won nlo si ikunle ejó, àwon méjèjì ni won jijo nbarawon ja ti won nbarawon nsota, won ni ki kéreré ìpàpò rúbo nitori ki won baa le segun àgbàgbà ìpàpò, won ni ki àgbàgbà ìpàpò náà rúbo nitori ki won baa le segun kéreré ìpàpò, obi meji, agbebo adiye ati apolukuluku sugbon kéreré ìpàpò nikan lo rúbo ti won si sin gbéré ifá funwon, àwon àgbàgbà ìpàpò mawo niro won pesu lole won koti ogboin sebo, kee pe seni won ranse si àwon méjèjì lati ile olofin wípé ki won wa ro ejó enu won, nigbati àwon méjèjì dele olofin won duro won koju sira won, àwon kéreré ìpàpò ro ejó bee náà ni àwon àgbàgbà ìpàpò ro ejó sugbon ejó enu kéreré ìpàpò nikan ni olofin gbo, kéreré ìpàpò nikan ni won da lare won si segun àgbàgbà ìpàpò, àwon kéreré ìpàpò wa njo won nyo won nyin babalawo àwon babalawo won nyin ifá, ifá nyin Eledumare won niti won gbo riru ebo ti won rúbo ti won gbo eru atukesu ti won tu ti won si gbo ikarara ebo ni hiha ti won si ha, nje riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Àwon kéreré ìpàpò wa fiyere ohun bonu wípé: Ojó ti mo bawon ru mo ro mo segun o ojó ti mo bawon ru mo ro mo se won Ogun ki nja ko ja kéreré ìpàpò oni ni maa ro masegun Òrúnmìlà ni to ba se bi ise ti akápò toun ni, oni sebi adiye ki ni orókún ejó Oni sebi oju kan ni apolukuluku njoko si njare oloko.
AKOSE IFÁ NAA: Leyin igba ti a ti fi adiye naa bo ifá tan, ao ge orokun won lotun losi ti ibi oju orokun naa yio wa laarin, ao ge ojuke ewe apolukuluku naa bee die, ao lo papo mo orokun adiye mejeji naa ti yio kunna daadaa, ao fi iyerosun teye ifá yi soju opon ao pe ifá yo si ao se adura si, ao da iyerosun naa si eleyi ti a lot yen lori ao po papo, ao fi sin gbere yika orokun wa mejeeji.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wípé Eledumare koni jeki a ri ogun ejó o, ao segun gbogbo ogun toba doju kowa ako ni ri inira ninu odun yi lase Eledumare aaase. ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.
Òsùn gbó ríró, kí o má dubúlẹ̀ Òòró gangan laa bósùn Òsùn dé o Alàwòrò Ọlọ́run ọba ma jẹ kí gbogbo wa saarẹ
Mo sé ní ìwúre fun orí kọ̀ọ̀kan wa ní ojúmọ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tòní wípé àìsàn kéré tóbi aráyé kò ní fí se wá tọmọ tọmọ tebí tará Ọlọ́run kò ní jẹ́ ka dùbúlẹ̀ àìsàn tọmọ tọmọ Gbogbo àìsàn arawa Olódùmarè yoo wòwá sàn kí ọ̀sẹ̀ yí tó parí
Tàgiiri ma yí nìsó Ara rẹ lokùn Ara rẹ ní ajé gbe ńso
Gbogbo ara tàgiiri fín so ajé Mo wá se ìwúre lo ní wípé ire owó yoo ma wọlé wa wa oooo Gbogbo iṣẹ́ tí abá se,owó rẹpẹtẹ ní a o ma rí ní èrè láṣẹ Olódùmarè Àsẹ
Yiyẹ̀ lonyẹ́ ẹ̀yẹ̀lé, Ayé ayẹ̀ wá kàlẹ̀, Rirọ lonrọ àdábà lọrún, Ayé yio rọrún fún wá jẹ̀, Tùtù ni omi àfi owúrọ̀ pònri, Ao ni mo inira layé ti àwá, Alanú kàn toju igba àlànú lọ, Yio wa wari, Mogbà làdúrà pe oké ti àwá ao ni jabọ, Ninu ọsẹ̀ yi ao ri owún tọkàsi ni rèrè, LAGBARA OLODÚMÀRÉ ỌBA TODA AYE TOFIFUN ỌRÚNMILA,
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku isinmi ana o, adura wa yio gba, ori buruku koni je tiwa loni o Àse. Mo nfi akoko yi nki gbogbo onisese patapata kaakiri agbaye wipe aku aseyori odun ifá agbaye o , a ku odun a sin ku iyedun o, emin wa yio se pupo re ninu ola ati idera lase Eledumare. Gegebi a se mo wípé odù ifá mímó osa alawure lo hu loke olota ni Adó-Ekiti Ekiti state, ti Otua meji naa si hu ni oke itase ni Ile-Ife lodun yi, adupe lowo Òrúnmìlà fun ohun rere to fo funwa. Awon odu ifá mejeeji naa lo dara, sugbon mo rowa wipe e jeki a tele ilana ti awon odu naa la sile, ki a se etutu ti won so ki a sin pa ofin mo, ifá yo gbewa o. Laaro yi mo maa koko fi enu ba odu ifá osa alawure to je odu akoko to hu loke olota, ki a to tun maa fi enu ba ti oke itase lojo miran. Ifá fore nibi ti a gbe ri odu ifá osa alawure, ifá ni awon eniyan yio la lodun yi, ifá ni odun yi ni odun ola awon babaláwo, ifá ni ki a se akose ifá yi ki a fi we ori wa nitori ki idiwo idena baa le kuro loju ona ire wa, ki ire ati igbega baa le wole de funwa. Ifá naa ki bayi wipe: Orunmila ni awure Moni awure Orunmila ni awure ni alara fi we ori omo tire ti omo tire di olowo
Orunmila ni awure Moni awure Orunmila ni awure ni ajero kinosa fi we ori omo tire ti omo tire di olola
Orunmila ni awure Moni awure Orunmila ni awure ni owa orangun aga fi we ori omo tire ti omo tire di oloro, ti won kole mole ti won ra ile mole
Moni Orunmila kilode ti o fi nfo bi èdè ti o fi nfo bi èyò? Ewi ile Adó, erinmi lode owo peepee lode asin Orunmila loun ko fo bi èdè o loun ko fo bi èyò, oni akapo toun loun nbawi wipe ki o lo we ori re ki o baa le di olowo, oloro ati olorire laye Mo wani toba je biti akapo tire ni nko, kini nkan to maa fi se ti yio fi di olorire laye? Oni ki o lo ni ewe alukerese, ewe ajé, ew akinsa, ewe ire ati eyele funfun ki won maa fi se sise ifá fun, maari maa mude oni ori akapo yio di ori owo, ori orò ati ori ire gbogbo laye o.
SISE RE: Ao gbo awon ewe wonyen sinu Omi ao pa eje eyele funfun yen sinu agbo naa ao gbaye ifá naa si ao fi fo ori wa toba si je wípé ose ni a fe fi se, ao pa eyele yen sinu abo kan ao gba eje re ao wa gun ori eyele ati awon ewe yen papo ao gbaye ifá naa si ao maa fi we ori nikan, nire ba de. Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe eledumare yio bawa we ìsé ati òsì ori wa danu, ori buruku koni je tiwa, ao jeeyan laye o, awure yio je funwa o aaaseee. ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.
Mo sé ní ìwúre wípé gbogbo ọ̀tá tí o bá ń robi tàbí sebi sí èmi àti ẹ̀yin lẹ́yìn yoo ma fí orí ara wọn gbe láṣẹ Ọlọ́run Olódùmarè Àsẹ
Eu oro para que qualquer inimigo planeje o mal para mim e você será recompensado com o mal instantaneamente e lá cairá sobre eles pela graça de Deus Um homem