Oni ni ojo ibi Ogbeni Femi Davies, alase ati oludari MetroNews Nigeria. Igba odun, odun kan ni.
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Omo yibo sepe fun Yoruba lori oro Biafra ti won fe da sile

Awon omo Yibo ti bere si ni soko oro si iran Yoruba to ri wi pe won fe pin kuro ninu orileede Naijiria. Won fe da Biafra sile, won ni awon ko ba Naijiria se mo. E dakun, e wo ni ti Yoruba ninu oro yii? Kilode ti won ko ja ija ti won ja lakoko yii nigba ti omo won wa lori oye? www.Olayemioniroyin.com -
Awon ologun yibon fun okan lara awon to pe fun Biafra ni Pota lonii
-
Ilu Amerika gbalejo Goodluck Jonathan
-
Lobatan: Won ti n ge tomato lori foonu chinco
Awon Yoruba ni ti ogun eni ba daniloju, eniyan fi i gbari ni. Ile ise China kan ti n se foonu, OUKITEL, ti kede wi pe, eni ba foju ana wo eegun, ebora nii boru won laso. Won ni to ba je ti ojulowo foonu to je wi pe konfaamu ni, won ni foonu tuntun ti awon sese se ti n je OUKITEL U7 gan-an lodu to jawo. Koda, won ni nibi ti foonu naa da won loju de, eniyan le ge tomato, alubosa, ata, ila, efo lori re. #Lobatan
Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa
-
Igo dudu meta: Toyin Aimakhu, Muyiwa Ademola ati Eniola Badmus
E gbo, taani igo rewa ju loju re? Se Toyin ni abi Muyiwa Ademola, abi Eniola nigo naa ye ju?
-
#Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere
#Our5K ti da wahala sile lori ayelujara: Ile Igbimo Asofin ni wahala naa ti bere
Olayemi OlatilewaLojo Wesde to koja yii nile igbimo asofin agba to kale siluu Abuja gbegi dina sisan owo egberun marun-un fun awon odo ile Naijiria ti ko nise lowo.
Abadofin eleyii ti asofin Philip Aduda (PDP, FCT) gbe si iwaju ile igbimo lo tile wa tele ninu awon ileri ti Aare Muhammadu Buhari se ni akoko ipolongo idibo re.
Sugbon ohun to jo ni loju ni bi o se je wi pe awon asofin omo egbe APC, ti won je omo egbe kan naa pelu Aare Buhari lo tun wa tako abadofin naa.
Isele to waye naa bere si ni ko awon omo Naijiria lominu, nigba ti opo si gba wi pe ise ti a ran iko niko n je. Ise ti Aare ati egbe APC ran awon asofin re naa ni won musa loogun
Opolopo awon odo ni won tu si ori ero Twitter pelu akori oro #Our5k, ti kaluku won si n so edun okan won pelu bi ijoba Buhari se fe fi ona alumonkoroyi dena ileri to se.
Sugbon sa, akowe ipolongo fun egbe APC, Alaaji Lai Mohammed ni egbe APC ati Aare Buhari ko ni ye nipa ileri re lati san egberun marun-un owo naira fun awon odo ti ko nise lowo.
Gege bi alaye re, o ni alaparutu ni awon omo egbe PDP, ati wi pe awon ni won fe fi oro naa da surutu sile nipa dida ori oro naa kodo.
Lai Mohammed, eni ti won tun ti fonte lu gege bi okan lara awon ti yoo je minisita, so wi pe eto ni gbogbo nnkan. Eniyan gbodo jokoo na ko to nase, ki onitoun ma ba a fipako nale. O ro gbogbo odo wi pe ki won lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni yoo foju han laipe.
Onwoye nipa oro oselu kan, eni to gba lati ba akoroyin IROYIN OWURO soro lai safihan oruko re, so wi pe, o sowon ninu oloselu ti o mu gbogbo ileri to se ni akoko iponlogo se nikete ti agbara ba de owo re. O ni ki i se ile Naijiria nikan, bo se ri kaakiri agbaye nu-un.
Oloselu a maa so asodun oro ni akoko ipolongo idibo lati ni ero leyin bi oko akoyoyo.
Sugbon pupo ninu ileri won ni agbara won kii ka nigba ti won ba de ori oye. Nigba ti awon kan maa ye iru ileri bee sile ki opo le seku fun igbadun tara won nikan.
Orisun: Olayemioniroyin.com
-
Igbeyawo Asofin Moji Lawal niluu Eko leku!
Arabirin Moji Lawal, okan ninu awon omo ile igbimo asofin ipinle Eko segbeyawo alarinrin lopin ose to koja yii pelu oko re, John Paul to je onisowo pataki.
Arabirin Moji, eni to je obirin akoko ti o ma soju ekun Apapa nile igbimo asofin ipinle Eko naa lo je omidan kan soso laaarin awon asofinbirin saaju ko to so yigi pelu oko re lose to koja yii.
Arabirin Moji, eni to ti figba kan sise pelu gomina Ipinle Eko nigba kan ri, Bola Tinubu, gege bi oludamoran fun awon iroyin to ni i se pelu imo ero, lo lodije ninu eto idibo abele egbe APC pelu awon oludije bi ogorun ko to di wi pe o jawe olubori lati kopa ninu eto idibo gbogboogbo.
Ninu eto idibo gbogboogbo naa lo tun ti pegede lati je okan lara awon omo ile igbimo asofin Ipinle naa.
Eto igbeyawo ti won se ni ilana esin musulumi naa la gbo wi pe o waye leyin ti toko-toya naa ti lo si kootu lati lo so yigi won labe ofin.
Oniroyin: Olayemi Olatilewa
-
E wo ohun ti Gomina Fayose n se laaarin oja

Gomina Ayodele Fayose da moto re duro loja Bisi to wa ni Ipinle Ekiti lati teti si edun okan iya arugbo yii nipa ohun ti won fe ki ijoba o se fun won. Gomina fara bale lati gbo gbogbo ohun ti iya naa fe so. O si seleri lati se atunse gbogbo ohun ti won on beere lowo ijoba.
E ma je n paro tan yin, mo ti yo ife Foyose bajebaje

-
Igbe aye Oba Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi dun bi oyin

Laipe yii ni Oba Lamidi Adeyemi, Alaafin Oyo pe eni odun metadinlogorin. E le ka iroyin naa nibi:Lara awon foto ojo ibi baba mi-in to te wa lowo ni eyi ti baba ya pelu Olori Badirat Adeyemi, olori baba to kere ju lo.
Bi Oosa Oyo tile ti dagbalagba, Olori Badirat, eni to sese wo ile iwe giga Ifafiti lodun yii ko je ki ara baba o darugbo kiakia pelu awon itoju orisiirisii ti n fi n te baba lorun niyewu. Eleyii to si n mu baba dabi omo tuntun jojolo.
Ti won ba ni Oba wo lo jaye ju laye? Walahi, Oba Lamidi ni!




