Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Enikan ti Buhari gbagbe lati fun ni ipo misita

    Ohun ti Ogbeni Yanju Adegboyega ko nipa maanu naa ni yii:

    “Walaaahi!
    Mo sese gbagbo loooto ni pe, alaimoore lo po julo ninu awon oloselu. Olorun n gbo, alaimoore ni Aare Buhari ati egbe oselu APC.
    Eyin o gbagbo?

    O daa naa, ipo minisita wo ni won fi okunrin yi, eni to f’emi ara re wewu lati fese rin lati ilu Eko lo siluu Abuja nitori ti Aare Buhari ati egbe oselu APC bori ibo.

    Mo fe fi asiko fun aare orileede yii, Muhammadu Buhari ati egbe oselu APC ni gbedeke ojo meje lati wa ipo kan fun okunrin yii tabi ki won da ileese ijoba kan ti yoo maa ri si “Irin-are” sile. Ki won si fi maanu yi se olori re.

    Bi bee ko! E ma jee ki n so nnkan ti yoo sele. Nitori, maa mobilaisi lati yo Ibadan kuro lara orileede Nigeria ni o.”

  • Okiki fi Oore Ofe gbe Femi Solar jade: Fidio orin tuntun yii leku!

    Femi omo Oladele ti gbobo eniyan mo si Femi Solar ti fi gbogbo awon ololufe re lokan bale pelu fidio orin re tuntun to pe ni GRACE nigba to n fi die ninu fidio naa to won lenu won.
    Gege bi alase Sunshine Jasa Band se so, o ni kesekese ni awon eniyan ti n ri ninu ka se agbekale fidio orin to joju-n-gbese. O ni awo orin GRACE yii ni a le se apejuwe re gege bi kasakasa to je “godfather” kesekese.

    “Dare Zaka lo ya fidio orin tuntun naa. Fun awon to ba si mo Dare Saka pelu awon fidio to n ti n sebo seyin, o ye ke e gba pelu mi wi pe ojumo kan ara kan lo fi n sise opolo. Ki ise eleyii tun le yato laaarin agbo amuludun agbaye, a tun se amulo awon ohun kan ti enikeni ko lo ri ninu fidio orin. Ko ni wu mi ki n so gbogbo re bayii, sebi eni a n gbe iyawo bo wa ba, won ni kii gbe ori iganna woran”, Solar fi kun alaye re bee.

     

    Okiki Films ni yoo gbe fidio orin naa jade nigba to ba jina tan. Olayemi Oniroyin ni o kede re nigba to ba gori igba. Eyin ati idile yin ko si ni padanu OORE OFE nigba to ba doju iworan yin. Ase
  • “E ma fi mi we Messi mo”- C. Ronaldo

    Ogbontarigi agbaboolu Real Madrid, Christiano Ronaldo ti ro awon ololufe ere boolu agbaye lati dekun ati maa fi we akegbe re lati inu egbe agbaboolu Barcelona, Lionel Messi.Bi o tile je wi pe gbogbo awon ololufe ere boolu ki i ye gbe awon akoni ori odan meji naa yewo sira won, sugbon lenu ojo meta yii ni awuyewuye naa tun ru jade bi omi seleru eleyii to gba gbogbo iroyin agbaye kankan.
    “Oun ni sitayi tie, emi naa ni sitayi temi. Bi awon eniyan se n fi wa wera wa ko je tuntun si mi mo.Sugbon lopo igba mi-in awon iroyin naa maa n ta mi leti nitori ohun kan naa ni awon eniyan n ran monu ni gbogbo igba”– C. Ronaldo
    Olayemioniroyin.com
  • O se o Eledua ! Alaafia ti n pada sara Oliseh

    Akonimoogba egbe agbaboolu Super Eagles, Sunday Oliseh, si wa ni ile iwosan niluu Belgium nibi to ti n gba itoju lowo.
    Iroyin tuntun to te Olayemi Oniroyin lowo lati enu awon dokita isegun oyinbo ti n toju re fi ye wa wi pe alaafia ti n pada si ara Oliseh, eni to je okan lara egbe agbaboolu Julius Berger tilu Eko lodun 1990.

    Ti e ko ba gbagbe, ojo kejilelogun osu kewaa odun yii (22/10/15) ni won gbe Oliseh digbadigba wo ilu Belgium nigba ti ipo ilera re bere si ni yoro koja bo ti ye.

  • Oko ajagbe jale moto kekere lori ni Pota

    Ijamba oko yii lo waye lale oni ni masose ilu Port Harcourt si Aba. Oko ajagbe kan lo yi le mo kekere kan lori eleyii ti eniyan wa ninu re.

  • Omidan to n wa ore tuntun fi leta ati Foto re ranse

    Omidan Toyin lo kowe si wa wi pe oun fe ore, ko so wi pe oun wa oko o. Awon ore tuntun lo n fe, eni ti won yoo jo maa takuroso lasan.
    Awon to ba nife sii le fi number tabi bb pin won sile nigba ti Toyin yoo ma kan si awon to fe lati ba won dorepo. Yoo dara ki e se alaye die nipa ara yin pelu. E se.

  • Leta ife jade lojo ti Olamide Orente se ojo-ibi alarinrin

    Eni odun ba ba laye, e pe ko sope. Eni Edua oke ba dasi, e pe ko ke aleluya s’Olorun Oba.  Ojo nla ni ojo oni je, ojo kejila osu kokanlan odun, ojo ti Omidan Awelewa Amoke, Oba Oge Eleyinju-ege Orente, Olamide Matthew n se ayeye ojo-ibi alarinrin.

    Ka ma paro, Olamide rewa lobirin. Se ehin funfun ni ka so ni abi oju to gunrege bi ti angeli Oluwa?

    Eniwee, Olamide Orente ti gba leta kan pataki lati owo maanu kan pataki lonii ojo to pataki ninu odun 2015.

    Leta naa si ti dowo Olayemi Olofofo, sori, Olayemi Oniroyin ni mo fe wi.

    Leta naa ni yii:

    Sii Olamide ololufe mi pataki,

    Ohun ti eniyan ko mo, kedere ni niwaju Olorun oga ogo. Ife otito koja ohun ti won le de pamo sinu agolo. Opuro laye, inu won nise dudu n gbe. Sugbon eniyan o gbon bi Olorun lokan mi se bale.

    Olamide mi, ewa re lo wu mi ju, omoluabi re ni i dami lorun bi egbin. Laakaye re ni i se mi ni kayeefi. O logbon lori, o tun ni sensi to po. Ope ni fun Oluwa to mu o ri ojo oni ninu idera. Omo olojo-ibi, tie peleke!

    Iwo ni iyo to so aye mi di Ayo. Iwo nife to so mi di gbajumo laaarin awon okunrin. Titi laelae ni i ma nife re, ololufe mi atata.

    Igba odun, odun kan ni fomo olojo-ibi.

    Emi ni ade ori re, Olapeju Ayodele
    ……………………………………….»

    Sii Olapeju Ayodele,

    Ifemi, Ayomi, Ademi, Olowoorimi, o seun mi pupo-pupo. Iwo ni abatabutu omi odo abumu ti ko je ki oungbe o gbe mi. Iwo nigi leyin ogba to o je koju o ti mi.

    Sebi iwo nife otito ti n mumi sebi oba oge loju araye. Iwo l’Ade too je kori mi wa ni kolobo. Iwo l’Oosa ti n ba mi rin laifoya.

    Ololufe maa gbo, apaadi to doju kogiri, togiri ni i se. A ti toje boloosa lowo, baba eni ti o bo kan o tun si mo laye n bi. Sebi ireti mi mbe ninu Oluwa ti kii ye, Oba alasepe ti kii doju tini.

    Titi laelae ni i ma nife re, ife mi owon.

    Emi ni ododo ife re, Olamide

  • Gobe Sele Nigba Ti Omo Yari Wi Pe Oun o ni fohin

    Yorùbá Dùn shared the following link and had this to say about it: Oloorun ni omo naa, ko fe ki won ba fohin re lero ni won ba mu lele fun un. Nje ohun to buru wa ninu igbese ti won gbe yii?  E dahun awon eniyan wa nibi:

  • Yinka Ayefele ti pada sile orin: Keresimesi odun yii ma minringindin

    Yinka Ayefele ti pada sile orin: Keresimesi odun yii ma minringindin

    Olayinka Joel Ayefele ti pada si yara agbara orin lati gbe orin tuntun jade fun awon ololufe re kari aye. Gege bi awon ololufe orin Gospel Tungba se mo, ti odun tuntun ba ti n sun mole ni Ayefele, eni ti aare ana, Goodluck Jonathan fi ami-eye M.O.N.dalola, maa n gbe awo orin tuntun jade.

    Ogbeni David Adeboye, agbenuso fun Ayefele lo kede eleyii nigba to n salaye akitiyan ti alase ati oludari ile ise Fresh Radio n se lati te awon ololufe re lorun doba. Awo tuntun ti won ko ti kede akole re yii la lero wi pe yoo jade kii odun keresimesi to wole de.

    Ayefele, eni ti awon kan tun feran lati maa pe ni OJA tun fi kun un wi pe alujo inu awo orin oteyii tun maa yato si ohun ti awon eniyan mo tele. Nitori wi pe ise ti yato, alujo si ti sun siwaju.

    Olayemi Olatilewa

  • Ambode naa ti pada si ni se bi Fayose: Gomina Eko ti pada sigboro aye

    Gomina Akinwumi Ambode lo da awako akero kan ti n wa moto lona aito duro lonii nigboro Eko.  Se kii se wi pe gomina naa fe ma se bi Ogbeni Ayodele Fayose?