Gégé bí ìròyìn se so, arábìnrin tí àwòrán rè hàn ní ìsàlè yí tí ó wá láti Amuda Isuochi ní ìpínlè Abia, ni ó ti ń pa àwon èèyàn ìlú rè, ò n lò èro ayélujára tí ó pín àwòrán àti ìtàn yí jé kí ó di mímò wípé òun ni ó tilè pa ìyá tí ó bíi l’ómo. Arábìnrin kan pèlú omo rè mérin tí ó pa ni ó jé kí àsírí tú. Àwon ará ìlú mu yíká ìlú láti fi se èsin.
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Ẹ̀kọ́ àti Ọgbọ́n ni Ọ̀rọ̀ Àgbà lati Ẹnu Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ lórí Ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán Òpómúléró
Bi a ba fi eti si ọ̀rọ̀ ti àgbà Yorùbá Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ni ori ẹ̀rọ “Amóhùnmáwòrán Òpómúléró”, ni ori ayélujára, a o ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọnyi:
Video Player
Nínú ìtàn lati ẹnu agba, a o ri pé Bàbá loye lati kékeré. Nkan bàbàrà ni ki ọmọ jade ni ilé ìwé giga ni ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ki ó si gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n. Ni ọdún Ẹgbàádínméjìdínlógójì, Gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ẹ̀kọ́ Ìṣirò, Ìjọba Ipinlẹ Ìwọ Oòrùn ayé ìgbà yẹn kò sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ kéré jú lati fún ni ipò Alaṣẹ lóri iṣẹ́ Ìdàgbàsókè Ìtọ́jú Owó.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ fihàn pé, lai si ni ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, kò ni ki á di ọ̀tá bi ti ayé òde òní. A ri àpẹrẹ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ ṣe súnmọ́ Olóògbé Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tó, bi ó ti jẹ́ wi pé wọn kò si ninú ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, àwọn méjèèji jẹ olootọ ti ó si ni ìgboyà.
Ọgbọ́n ki i tán, bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ti kàwé tó, Bàbá ṣi ńkàwé lati wá ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ọgbọ́n púpọ̀ wà ni ọ̀rọ̀ àgbà yi, ẹ ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yi lóri Amóhùnmáwòrán Òpómúléró.
ENGLISH TRANSLATION
Continue after the page break -
Arákùnrin àti arábìnrin IPOB gun òkadà léyìn tí won lo se àbèwò Nnamdu kanu.
Arákùnrin àti arábìnrin IPOB gun òkadà léyìn tí won lo se àbèwò Nnamdu kanu.
Àwon èèyàn yí kò kúkú ní pa mí, arákùnrin Kan tí a mò sí Nwaiwu Chiukwuebuka ni a rí pèlú arábìnrin Kan lórí òkadà Kan náà.
-
Murphy Afolabi se ayeye ojó ìbí rè nígbà tí ó pé odún kerin lé l’ógójì ní Toronto, Canada.
Òsèré orí ìtàgé, Murphy Afolabi se ayeye ojó ìbí rè ní ojó mélòó séyìn.
Òré àti ojúlùmò tí won jé èníyàn pàtàkí, gbajúgbajà Òsèré, adarí eré abbl ti se ayeye ìjònilójú fún omo bíbí ìpínlè Osun tí a bí ní odún 1974. -
Akékòó odún kerin tí ó rì s’ómi ní Yankari.
Gabriel Emmanuel Chinoso, tí ó jé Akékòó olódún mérin tí se Akékòó eka èkó onímò nípa ohun amáyé rorùn tí a mò sí electrical engineering ní ilé-èkó gíga Tafawa Balewa university, Bauchi ni ati gbó wípé òkú sí inú odò ìwè ní Yankari.
Ó rì s’ómi nígbà tí ó n wè lówó ní ojó àìkú tí alukoro àwon olópàá tí a mò sí Dsp kamal Abubakar nàà ti jérìí si.
-
Àwòrán okò Mercedes Benz tí Obafemi Awolowo fi se ìponlogo ní ìgbà tí ó fé lo fún Ààre orílè èdè Nàíjíríà.
Obafemi Awolowo tí ó jé ògbóntarìgì àti adarí àwon olósèlú, tí ó sì kó iPa takuntakun láti jé kí orílè èdè yí di olómìnira.
Làra àwon ohun tí ó wà ní ibi tí won kó nkan ìsèńbáyé sí tí a mò sí Museum, ni okò tí a mò sí Mercedes 230:6.
Okò yí ni Awolowo lò láti fi se ìponlogo àti láti fi rin gbogbo ìrìn àjò ní odùn 1979 àti 1983, tí okò náà jé ríra ní odún 1970…. -
Ifa naa ki bayi wipe: Òkàn sá
Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Mo lero wipe gbogbo wa la sun dokan daradara aku isimi opin ose, mosi fi asiko yi ki gbogbo àwon ore mi ti won je omo leyin kristi wípé eku odun eku iyedun emin yio se pupo re laye ninu ola ati idera o Àse.
Ifá yi gba wa niyanju, tabi eni to ba bi nigbodu/itenifa niyanju wipe ki o se etutu daradara ki won si se akose ifa yi fun ki o fi sin gbere sorun owo re mejeeji ki a si tun se akose elemun fun akápò yi ki o maa mu dani fun sise adura lararo nitori ki o ma baa maa se Ogun amubo ati aseti ki gbogbo nkan to ba ndawole baa le maa yori si rere.Ifá yi gba okunrin ti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o se etutu naa ki o ma baa maa se amubo iyawo , ki iyawo ba le ba gbele dojo ale, ti o ba si je obinrin naa lo jade si ki o se etutu naa daradara o ki o ma baa ni isoro Oko ki won ma baa maa gbe lagbeju sile ki o ba le lade lori dojo ale re.
Ifa naa ki bayi wipe:
Òkàn sá
Èjì sá babalawo àsá dífá fun àsá lojo ti o nroko iwaje, beeni asa nse Ogun amubo o nse Ogun aseti o wa goke ijeti ile Orunmila “won gbódo wálè àgbède òrun ro” won ni ko karale ebo ni ki o se ki o ma baa maa se amubo ati aseti mo ki o baa le maa ri eran obi meji……..sile meta owo ati igba ewe ayajo ifá, àsá kabomora o rubo won ni ko gbe lo sorita meta ajaloko àsá si se bee, nigbati o dorita meta o wa nse adura si etutu ni esu odara de, o wa beere lowo asa wipe kini isoro re? Asa ni Ogun amubo ati aseti lo nba oun finra pe kosi gbogbo nkan toun ba mu ti ki nbo lowo oun, esu ba mu ikan ninu emu ti asa fi rubo yen o fi ikan si lowo otun o fi ikan si lowo osi oni kosi nkan to bati mu ti yio bo lowo re mo inu asa ba dun to ba wati ri nkan to fe gbe àsá a so wipe;
Àpasà?
maa ni o han só,
Oni òkò àsá nko?
Mani ki nbale nsanwo, lati igba náà ni àsá ti segun Ogun amubo ati aseti o wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe ire ayé wa koni bo danu lowo wa mo, ao maa ni aseyori lori gbogbo adawole wa, gbogbo obinrin ti won nse amubo Oko yio di asegun loni e o si lade lori dojo ale yin, gbogbo okunrin ti won nse amubo iyawo won yio di alaya ni odede, ako ni sanwo ire gbogbo mo laelae, laalaa wa koni jasi asan lase Eledumare aaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.English Version:
Continue after the page break
-
Genevieve Nnaji ya àwòrán pèlú àwon agbófinró obìnrin méjì .
Genevieve Nnaji ya àwòrán pèlú àwon agbófinró obìnrin méjì .
Gbajúgbajà òsèré, Genevieve Nnaji tí ó dàbí egbin nígbà tí ó ya àwòrán pèlú àwon agbófinró obìnrin méjì yí .
Òsèré yí ni ó pín àwòrán yí sí orí èro ayélujára …. -
Àwòrán èyìn Chidinma Ekile tí ó rewà .
Òrò tí ó gbòde kan ni wípé Chidinma Ekile ti darapò mó egbé burúkú àti wípé ó ti n kégbékégbé látàrí wípé ó ya tàtúù dí èyìn rè .
Chidinma Ekile níbi ayeye kan tí ó wo aso tí ó sí èyìn sílè èyí tí ó gbé àwòrán tí ó yà sí èyìn rè jáde, tí ó sì ya òpò lénu sùgbón àríyànjiyàn ti wà wípé làálì lásán làsàn ni sùgbón àwon kan ta ko èyí. -
Arewà tí ó se ìgbéyàwó láì kun nkankan sí ojú ní ojó èye rè .
Èyin òdóbìnrin ; njé èyin le múra báyìí ní ijó ìgbéyàwó yín bí? Gbogbo obìnrin ni ó máa n gbèrò láti dàbí egbin ní ojó ìgbéyàwó won , gbogbo ònà ni won yóò sì wá láti jékí èróngbà won di síse .
Sùgbón ìyàwó yí ní tirè gbèrò láti kun nkankan ní ojó èye rè .Èyin obìnrin n’íta njé èyin le se èyí bí….