Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Oríkì ìbejì

    Oriki Ibeji:
    Wíníwíní lójú orogún
    Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
    Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
    Ẹdúnjobí,
    ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
    Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
    Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
    Ó bé sílé alákìísa,
    Ó salákìísà donígba aṣọ.
    Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
    Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.

    Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
    Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
    Táyélolú ni àbúrò,
    Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
    Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
    B’ayé dára , bi ko dára

    O tọ́ ayé wò,
    Ayé dun bi oyin
    Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
    Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
    O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
    Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.

    Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l’ọ́mọ,
    èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w’ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo…

    Àmín àṣẹ

  • Ìfé Mi (My Love)

    Ìfé Mi (My Love)

    Eni bíi okàn mi
    Adúmáradán orenté
    Olólùfé mi àtàtà
    Ìfé re ní n pa mí bí otí òyìnbó
    Lá ì gbó ohùn re
    Mi ò lè sùn mi ò lè wo
    Léyìn re kò sí e lò míràn
    Mo wo òtún mo wo òsì
    Mo wo iwájú mo wo èyìn
    Mi ò rí arewà omoge
    Tó ní’wà bíi ìwo
    Iwájú ù re
    À wò da tó ní enu bíi òdòyò
    Èyìn re
    À wò ká’wó mó rí kó sí kòtò
    Bí o bá sá’ré whàálà
    Bí o bá rora rìn ìjòngbòn
    Ìwo ni mo fé
    Ìwo ni okàn mi yàn
    Mo máa ní ìfé è re tí tí di ojó ikú mi ni
    Olólùfé mi
    Mo ní ìfé re
    Nítorí ìwo ni ÌFÉ MI.

  • ORÍLÈ ÈDÈ MI

    ORÍLÈ ÈDÈ MI

    Nàìjíríà ìlú mi pàtàkì
    Ìlú t’ókún fún ogbón
    Pèlú òpòlopò àwon òjògbón
    Ilé ogbón
    Tí a ti n hun àgbòn ìwà ìbàjé
    S’ogúndogójì di ààyò àwon òdó
    Òsèlú di ohun wón k’èyìn sí
    Egbé òsèlú di ìkan kò gbé’kan
    “Birds of a feather”
    Bí àwon olóyìnbó se máa n so
    Iró n pa’ró fún iró
    Ìtànje lásán làsàn
    Ní àti ojó tí a ti gba òmìnira
    Omi ìnira ni àwon olórí wa n fún wa mu
    Màá se eléyìí
    Màá se tòún
    Sí bè…
    Ìsé òun òsì
    Kò tán ní àwùjo wa
    Kílódé, kí ló se wá
    PDP se ìjoba ó ya mó won lówó
    APC ò sun wòn
    Tani yóò gbà wá ní owó àwon jegúdú jerá wònyí
    Tí wón n pe ra won ní olórí wa
    Àkókò náà tó wàyìí
    Ó tó géé oní bàtá kan kìí dá Orin
    Èyin òdó, àsìkò náà ti tó
    Láti GBA ìjoba
    Ní owó àwon alágbára a tó kú má kùú a mònà òrun má lo
    2019! E jé kí á dìbò fún
    Òdó langba kí ìtèsíwájú leè
    Dé bá gbogbo wa.

  • Awakò kan tí kò fi ara balè ní ojú pópó ti fi okò fó orí omokùnrin kan ni ìpínlè Edo.

    Òdókùnrin kan ni ó se àgbákò ikú òjijì ní ojó mélòó séyìn ní ìlú Jatu ní ìpínlè Edo, nígbà tí ó n gbìyànjú láti fònà sí òdì kejì, arákùnrin yí ni okò tí o n sáré fó ní orí tí ó sì pa á lésèkesè.
    Ìsèlè burúkú yí ni a gbó wípé ó n fa wàhálà ní agbègbè náà kí ó tó di wípé won gbé òkú náà kúrò lónà.

  • Reekado banks wà pèlú àwon òdóbìnrin tí won yááyì “ka bíbélì re kí o sì gbàdúrà lójojúmò.

    Ìkan lára àwon omo olórin abé ikò Marvin, Reekado banks pín àwòrán sí orí èro ayélujára tí a mò sí instagram, èyí tí ó yà pèlú àwon òdóbìnrin tí won férè wà ní ìhòhò. Tí ó sì ko síbè pé Ka bíbélì re kí o sì gbàdúrà ní ojojúmó.

  • Oríkì Ìjẹ̀bú

    Oríkì Ìjẹ̀bú

    Ìjẹ̀bú ọmọ alárè,
    Ọmọ awujálè,
    Ọmọ arójò joyè,
    Ọmọ alágemo Ògún,
    Ọmọ aladìye ògògòmógà,
    Ọmọ adìye bàlókùn,
    Ara òrokùn,
    Ara ò radìye,
    Ọmọ ohun ṣéní,
    òyòyò mayòmo ohun ṣéní,
    olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí,
    Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo,
    Ọmọ mo ní isunle mamalobe,
    ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ,
    Ọmọ onígbò ma’de,
    Ọmọ onígbò mawo mawo,
    Ọmọ onígbò ajoji magbodowo,
    Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.
    Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà,
    Ọmọ olówó ìṣèmbáyé,
    Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí,
    kelebe Ìjẹ̀bú owó,
    ìtò Ìjẹ̀bú owó ,
    Dúdú Ìjẹ̀bú owó ,
    Pupa Ìjẹ̀bú owó,
    Kékeré Ìjẹ̀bú owó ,
    Àgbà Ìjẹ̀bú owó.
    Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni,
    Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni,
    Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni,
    Ayépé Ìjẹ̀bú,
    Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe,
    Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá ,
    Ìjẹ̀bú Ọmọ aláso ńlá.

  • Arákùnrin ológun tí ó rewà ti setán láti fé ààyò okàn rè, e wo àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó won.

        “Àkókò ti wá tó báyìí kí arákùnrin yí fi ìyá àti bàbá rè sílè láti gbárùkù ti ìyàwó rè, kí àwon méjèèjì sì di òkan.
    Láì dóònà p’enu, eni wa, Okeoma Daniel Onyenaturuchi ti setán láti lo ìgbésí ayé rè pèlú egungun ìhà rè.
    E wo àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó won.

  • Arábìnrin kan tí ó jé omo Liberia ni ó gé nkan omokùnrin òrékùnrin rè tí òrékùnrin rè sì pa á.

    Arábìnrin kan tí ó jé omo Liberia ni ó gé nkan omokùnrin òrékùnrin rè tí òrékùnrin rè sì pa á. Èyin òré wa, ejòwó e jé kí á máa fura nítorí a kò mo irú àwon obìnrin tí à n gbé nísinyí.
    Arábìnrin yí ni ó gé nkan omokùnrin òrékùnrin rè tí òrékùnrin rè sì pa á fún èsan.

  • Davido àti òrébìnrin rè tí a mò sí Chioma Alvrid ní Barbados.

    Davido àti òrébìnrin rè, Chioma wà ní Barbados báyìí báyìí láti ya àwòrán Orin tuntun tí Davido sèsè ko.
    Ó ti pín àwòrán òun àti arábìnrin yí ní orí èro ayélujára tí a mò sí instagram tí ó sì ko síbè pé àsedúró ayérayé.