Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Ìgbéyàwó ìbílè ti Oludamilola Osinbajo àti Oluseun Bakare ní Aso Rock.

    Ìgbéyàwó ìbílè ti Oludamilola Osinbajo àti Oluseun Bakare ní Aso Rock.

    Èyí ni àwòrán láti òdò igbákejì Ààre, professor Yemi Osinbajo, omobìnrin rè Oludamilola Osinbajo níbi ìgbéyàwó ìbílè rè èyí tí ó wáyé ní ilé Ààre orílè èdè Nàíjíríà. Igbákejì Ààre, ìyàwó rè àti àwon àlejò míràn ló oé síbè.

    Aya tí n bò lónà, Damilola ní ojó ketàdínlógún ní osù Erénà, 2018 tí yóò di aya Oluseun Bakare, Alagba ní ìjo Redeemed Christian Church of God àti omo Bola Shagaya tí ó jé sòwòsòwò àti gbajúgbajà…[starlist][/starlist][starlist][/starlist]

  • Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola

    Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola ni wọn bí ní ọjọ́ kẹrìnlélọ́gún oṣù Ọ̀pẹ ọdún 1939 (24 December 1939) wọn jẹ́ òsèsé, ohun kọ̀wé, Oluṣiṣẹ nípa èdè Yorùbá. A mò wón sí kíkọ ìwé ni èdè Yorùbá, wón sì tún gbé èdè Yorùbá lárugẹ.
    Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola ni wón bí ní ìlú Ìbàdàn, wón lọ sí ilé ìwé Labode Methodist àti Wesley College. Wọ́n lọ sí ilé ìwé gíga Fáṣítì Ìbàdàn níbi tí wọ́n tí kó nípa èdè Faransé (French), bàbá tún lọ sí Fáṣítì Ẹ̀kọ́ láti lọ kó nípa lítírésọ̀ èdè Yorùbá ni odun 1978 kí wón tó sise ní Fáṣítì Obafemi Awolowo ni ìlú ilé Ifẹ̀.
    Wọ́n yan Akinwumi Ishola ni Ọ̀jọ̀gbón ni Fáṣítì Obafemi Awolowo ni ọdún 1991. Bàbá Akinwunmi Ishola kọ eré onise Efúnsetán Aníwúrà láàrin ọdún 1961 sì 1962 nígbà tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni Fáṣítì Ìbàdàn. Kò pèé ni wón kọ ìwé Ó lekú ní ọdún 1986.

    Bàbá tún kọ orin ẹ̀rí ilé ìwé gíga tí wọ́n ń kọ ní ilé ìwé gíga Wesley Ìbàdàn lónìí.

    Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola tún kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré onise àti ìwé. Bàbá tún sise olugbohunsafefe, wọn tún dá ilé isẹ ìgbé eré ìjáde leyi tí ó jé kí wọn ṣe àwọn ìwé tí wọ́n kọ sí eré tí wọ́n ń gbé jáde lórí móhùnmáwòrán. Bàbá kọ ìwé ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì tú sí èdè Yorùbá.

    Ní ọdún 2000 bàbá gba àmìẹyẹ fún isẹ takuntakun wọn (National Merit Award) lẹ́yìn tí wọ́n tún lọ kàn sí Ọ̀jọ̀gbón Fáṣítì Georgia ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

    Ọ̀jọ̀gbón Akinwunmi Isola fẹ́ ìyàwó tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́rin.
    Ọ̀jọ̀gbón AKINWUMI ISHOLA kú ní ọjọ́ mẹ́tàdínlógún oṣù Ẹ̀rẹ̀lẹ́ ni odun 2018 sí ìlú Ìbàdàn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

    Kí èdùmàrè ó gba àbọ̀ bàbá, iwájú tí wọ́n dójú ko yìí ó dára, ẹ̀yìn tí wọ́n fi sílè kò ní bàjé.[starlist][/starlist][starlist][/starlist]

  • A kú àmójúbà Osù Eréna (March) tuntun.

    Osù ìdèra, ìtèsíwájú, ìse rere ni yóò jé fún gbogbo wa. Nínú Osù tuntun yìí, àìsàn kò níí jé ìpín enìkóòkan wa. Eni yòówù tí àìlera bá n dà láàmú, Olódùmarè yóò so ó dèrò. A kò níí rí ìjà ìgbóná. Bí ó tilè wù kí ilé ó gbóná tó, Oba Adédàá yóò so ó dèrò. Àìsàn tí n gba oúnje lénu eni kò níí se wa, èyí tí n gba apá, esè, àti gbogbo èyà ara lówó eni kò níí jé ìpín wa nínú Osù yii. Àjíñde ara yó máa jé o.

    Ilé tútù
    Ònà tútù
    A dí fá fún Olúweri-Mògétì
    Àtòjò
    Àtèrún
    Ilé Olúweri kì í gbóná…

    Ilé àti ònà kò níí gbóná mó wa nínú Osù yìí..

  • Àwon ológun orílè èdè Nàíjíríà ya àwòrán pèlú ejò rògbòdò léyìn tí won pa á tán .

       Àwon ikò ológun ni inú won n dùn tí won sì n yò léyìn tí won pa ejò nla rògbòdò kan níbi tí won tèdó sí .

    Àwon Akoni yí ya àwòrán pèlú eranko afayàfà yí nígbà tí inú won n dún .

  • Alágbárí òdómokùnrin kan tí a mò sí yahoo boy lo omo ègbón rè okùnrin tí kò ju omo odún méje lo láti fi se ògùn owó ní ìlú èkó .

        Òdómokùnrin kan ni owó àwon agbófinró tè nígbà tí ó n lo omokùnrin ègbón rè láti fi se ògùn owó ní ìlú èkó.

    Gégé bí a se gbó, orúko òdómokùnrin tí a fi èsùn kan ni Tunde Owolabi tí ìnagije rè n jé owó n sòrò ( money talk) . Owó ti tè é nígbà tí ó n lo omokùnrin ègbón rè tí ó jé obìnrin tí ó jé omo odún méje lówó ní ìlú Ikoyi ní ìpínlè Eko . Ó wà ní àhámó àwon olópàá báyìí….

  • E wo nkan tí ilé-èkó gíga ifáfitì ti ìlú Èkó tí a mò sí UNILAG se! Sé eléyìí kò ní jé kí àwon òdómobìnrin wa n’íìfé ohun afefe yèyè si báyìí.

       Nígbà míràn kò ye kí á bá àwon òdómobìnrin wa tí won n’íìfé ohun ayé wí jù, nígbà tí ó jé wípé àwon àwùjo wa kò kúkú mú orí eni tí n se isé takuntakun wú. Ká sisé kára bí eni máa kú, kí won bò wá lówó àti kí á fi àkókò sòfò láti múra láti fi dàbí egbin, kí a sì gba èbùn gbàngba ! Sí ò .

    Eni tí ó gba òdómobìnrin arewà jùlo àti òdómokùnrin arewà jùlo ti ilé-èkó gíga ifáfitì ti ìlú Èko ní odún 2014 gba okò bògìnì tí eni tí ó sì mo ìwé jù gba èbún laptop.

  • Ifá náà ki bayi wípé: Adaku Adaoku

    Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi, aku ise ana o, a si tun ku imura toni, gegebi a se mo wípé oni je ojó isegun, ogun buburu yio se ninu igbesi ayé wa loni o Àse.

    E jeki a fi odù ifá mimo ogundarikulola yi se iwure ti aaro yi.
    Ifá náà ki bayi wípé:
    Adaku
    Adaoku
    Ada toko nbo o daku gbonrangandan bi oko a difa fun Aikulola eyiti nse wole wode orisa, Aikulola ni koni ominira lodo orisa Eledumare, se lo ba gba oko alawo lo latari nkan ti o maa se ti yio fi di ominira, won ni seni ko lo maa ni gbogbo nkan to je èèwò orisa Eledumare ki o lo ko fun orisa, Aikulola si se béè looto, nigbati o ko àwon nkan náà de odo orisa Eledumare inu bi orisa lopolopo nitori èèwò orisa Eledumare ni àwon nkan náà, bi Orisa Eledumare se sofun àwon iranse re pe ki won di Aikulola lowo ati lese ki won gbe seyinkule ile pelu gbogbo nkan wonyen, won si di Aikulola looto won gbe seyinkule, e wo ògún tinrin moko alagada ogun to nbo lati oja ejigbomekun nibiti o tilo jagun, bi ebi se npa ni oungbe ngbe, gbogbo ara ògún lákayé lo gbe, ògún lákayé lo ni ki oun ya nile orisa ki oun ki Orisa Eledumare ki oun to maa lo sile, nigbati ògún lákayé de eyinkule orisa se lo ba Aikulola ti won de ti won si ko àwon eroja etutu re ti sibe, inu ògún dun o si bere sini jehun o je gbogbo re yo tan , bi ògún se mu ada re niyen bi o se ja okun owo ati ese Aikulola niyen o, ògún lákayé wa wole sodo orisa Eledumare o wa sofun orisa wipe oun ti da Aikulola sile orisa si gbasi lenu, bi ògún lákayé se da Aikulola sile niyen o, oun ni won se npe odù ifá yi ni “ogundarikulola sile”

    Aikulola wa njo o nyo o nyin babalawo àwon babalawo nyin ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.

    Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe ògún lákayé yio tu gbogbo wa sile ninu ide omo araye, ako ni ri ibinu ògún lákayé loni ako si ni sun ninu agbara eje o aaase.
    ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

    English Version
    Continue reading after the page break

  • Oko àti ìyàwó se ayeye ojó ìbí won nígbà tí won pé ogóòrún (100) àti márùndínlógóòrún papò.

       Bàbá bàbá kan tí ó jé bàbá orílè èdè Nàìjíríà àti ìyá ìyá ni won se ayeye ojó ìbí fún nígbà tí won pé ogóòrún àti márùndínlógóòrún. Gégé bí olùsòrò kan lórí èro ayélujára se so àti olùsòrò gbogbogbò tí a mò sí Chris Ogedengbe. Àwon tokotayà yí tí mùsèmúsè won tún gbá músémúsé, tí won sì tún le rìn, lo sí ilé-ìjosìn àti wípé ìyá tún se óúnje fún bàbá (oko rè). Àwa náà ki yín kú ojó ìbí o tokotayà .

  • Àwon tí won ti yo kúrò àti àwon tí won lé ní BBNaija ti se àyéwò sí ilé-ìfowópamó tí a mò sí Heritage bank.

        Àwon Alábagbélé àti olùgbépò télè ti big brother Naija, àwon tí a mò sí Vandora, Princess, Dee one , Bitto àti àwon tí won lé kúrò Khloe àti k Brule se àbèwò sí ìkan lára àwon ilé-isé tí ó rán wón lówó láti gbé won ga .

  • Òkan l’ára àwon anamoyayà (civil defence officer) ni àwon fúlàní darandaran pa ní ìpínlè Benue tí won sì sin ín pélú omijé.

    Anamoyayà (civil defence officer) ni àwon Fulani darandaran pa ní ìjoba ìbílè Guma ní ìpìnlè Benue ni won ti sín pèlú òpòlopò omijé. Àwon emèwà rè ti sin ín tomijé tomijé.