Ní òní mo gbèrò láti tún ilé àti àyíká Adìe mi se, ni mo pàdé afayàfà yí, mo sá eré bí mo se le sa mo. Nítorí ìgbà àkókò mi rè é tí mà rí ejò ńlá báyìí láàyè, tí kìí bá se lopélopé omokùnrin kan tí mo pàdé, mo rò wípé ejò náà kò bá bó mó mi lówó.
Èyin tí e n’ìfé Ejò n’ílé irú èyà wo ni eléyìí báyìí..
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Ejò tí mo pa nínú ilé Adìe mi lóòní.
-
Ogún-l’ógbòn àwon baba ńlá ìran yorùba l’ójé alágbára, lára won ni *Timi Àgbàlé olófà iná*.
Timi Àgbàlé, olóde tí ó sì jé jagunjagun tí Aláàfin rán lo sí ìlú Ede láti dáàbò bo àwon ènìyàn ibè.
Alágbára ènìyàn ni Timi jé , tí a sì mò ó sí *Timi Àgbàlé olófà-iná*,gégé bí ìtàn se so, ó jé okùnrin tí ofà rè má yo Iná. -
Odó kàyééfi ńlá tí ó wà ní *ADO AWAYE*.
Ìlú kéréje kan wà ní ìpínlè Oyo tí orúko ìlú náà sì ń jé *ADO AWAYE*, òdó kàyééfi kan wà ní ìlú yí tí ó jé wípé bí ènìyàn bá ti esè kan bo inú rè yóò fa eni náà tí a kò sì ní mo ibi tí eni náà ma jásí.
Bí ènìyàn bá bu omi òdó yí tí ó se àdúrà si tí ó sì mun-ún gbogbo ohun tí ó bá toro ni yóò rí béè. Orúko odò náà ni *ODÒ ÌYÀKÉ*
Àwòrán odò náà rè é n’ísàlè…
-
Òdómokùnrin odún mókàndílógún (19 years) fé odómobìnrin odún méèdógún (15 years) ní ilè àríwá (North) ní orílè èdè Nàìjíríà.
Àwòrán tí ó gba aféfé ni ti àwon tokotayà yí tí oko jé odún mókàndílógún tí ìyàwó sì jé odún méèdógún ní ilè àríwá orílè èdè Nàìjíríà.
Ò n lò èro ayélujàra kan ni ó pín àwòrán tokotayà yí, tí ó sì kí won kú oríre… -
Àwon apàse ilé-ìwé Obafemi Awolowo University (OAU) pàse kí won mú àwon akékòó látàrí àtakò àláfíà (peaceful protest) tí won ń se.
Ogbà Obafemi Awolowo University (OAU) ti kó sí inú dàrúdàpò nígbà tí òpò akékòó tò lo sí àgó olóòpá tí ó wà ní Moore ní ìlú ile-ife láti bèèrè fún ìdásílè àwon akegbé won tí àwon ìgbìmò ìdábòbò Ogbà náà ti mú, tí won sì ti tì wón mó àgó olóòpá tí ó wà ní Moore .
Ó máa wà nínú àkosílè wípé ní ojó kàrún osù kewàá odún 2017 (5/10/2017) ni àwon akékòó se àtakò àláfíà látàrí ohun èlò tí kò sí ní inú Ogbà. Ní ojó kejì àtakò yí, àwon ìgbìmò ìdábòbò ilé-èkó yí sáré lo sí ààrin àwon akékòó yí tí won sì mú méwàá nínú won, tí igbákejì ààre akékòó ifáfitì yí “Jacob Tosin(Emerald)”sì wà láàrin won…
-
Àwòrán ìsìnkú Odudu Davis, olóòpá tí ìbon àwon olóòpá ojú omi bà tí ó sì kú ní ìpínlè calabar.
Ní’sàlé ni àwòrán ìsìnkú olóyè nínú ológun (Corporal) Odudu Davis tí ìbon pa nígbà tí osù kàrún di ogbòn ní inú odún yìí (30/5/2017)láti owó àwon olóòpá ojú omi (naval officer) nígbà tí àwon olóòpá àti àwon olóòpá ojú omi kolu ara won ní àgó olóòpá tí ó ń jé Akim (Akim police station)… -
A kú àyájó odún *Òmìnira* ti *orílè Èdè Nàìjíríà* ?? lónìí ooo.
A kú àyájó odún *Òmìnira* ti *orílè Èdè Nàìjíríà* ?? lónìí ooo. Èmí wa yóò se púpò rè láyé.
E jòwó, e má sì gbàgbé láti se *ìwúre* fún orílè èdè *Nàìjíríà* ?? nítorí wí pé *”Ìròrùn igi ni ìròrùn eye”*. Àgbájo owó la fi ñ sòyà, àjèjé owó kan kò gbérù dórí.A sì tún kú àmójúbà *osù Òwàwà (October) tuntun*. Osù aláyò ni yóò jé fún wa láse Èdùmàrè. Èmi ò ní dòkú, èyin náà ò ní dòkú, gbogbo wa ni a yóò rí òpin odún yìí láyò àti àlááfíà… *(Ase! )*
????????
*omo oòduà rere ń kì I yín… -
Ìyàwó mi dára sùgbón kò n’ìfé ìbálòpò léyìn ìgbeyàwó.
Ìyàwó mi dáa tí mo sì le pè ní aya rere sùgbón kìí gbà kí á bá ara wa lò nígbà tí ó ye, lóòtó aní omo okùnrin pèlú obìnrin. E jò ó kí ni mo le se? Mo ti gbìyànjú àwon nkan tí mò ti kà ní orí èro ayélujàra Kódà a tún jo lo sí ibi àpérò láti le jé kí ó yí padà sùgbón kò yí padà… E jò wó mi ò so eléyìí láti bà á jé sùgbón ònà yí nìkan ni mo gbèrò kí ó yí padà .
Egbàmí n’ímòràn e jò ó!!!

