(gbajugbaja osere oni theatre )
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Ohun méje tí ó jé èdùn okàn tí won kò so fún mi kí n tó parí ilé-èkó gíga ifáfitì.
Ohun méje (7) tí ó jé èdùn okàn tí enikéni kò so fún mi kí n tó parí ilé-èkó gíga.
1- ilé-èkó gíga ifáfitì wà fún mímo irú èèyàn tí o jé, lo àkókò àti ànfààní tí o bá ní dáadáa, láti mo ìlépa re tí ó jé wípé nígbà tí o bá se tán o kò ní fi àkókò re s’òfò.
2- ní ìlépa tó dáńgájíá.
3- tí o bá ní èbùn tàbí ohun tí o féràn láti ma se má fi àkókò s’òfò láti sin enikéni! Lépa ònà tìre.
4 – má jè é kí enikéni so fún o wípé “o kò le se é”.
5- Gbìn sínú okàn re má sì jé kí okàn re rè sí isé òòjó re : èkó lórí ara eni (self study), èkó àgbà (post grad study), isé re (courses), eré ìdárayá (sport), kíka ìwé (reading) Àpérò (seminar) ìrìnàjò (travelling), èdè (linguistic).
6- má gbé okàn lé ònà àtije kan, gbìyànjú láti ní ònà míràn.
7- tí o bá pinnu láti sisé l’ábé enikéni ó ye kí o mò wípé ìgbéga re ó dá lórí òsùwòn 40% fún isé kára kára àti 60% òsèlú tí ó sì jé wípé kò ní sú e….
Continue after the page break for English Version
-
Àwon agbésùmòmí Boko Haram pa àwon àgbè àti àwon ará ìlú ní Borno.
Ókéré jù àwon ènìyàn méèdógún (15) ni a gbó pé àwon agbésùmòmí Boko Haram pa nígbà tí won kolu ara won. Ìròyìn tí Orísun àwon figilanté gbé ni wípé òpò àwon ará ìlú ní won sì ń wá léyìn Ìsèlè tí ó selè ní Jakete ní ìjoba ìbílè Konduga, agbègbè kan ní ìpínlè Borno. Ní kété agogo méwàá òwúrò àná ni won yín ìbon pa wón nínú oko won, tí a sì ń wá àwon obìnrin àgbè méfà.
Orísun àwon figilanté ti ìbílè náà jé kí ó di mímò wípé àwon àgbè náà gbìyànjú láti bó sùgbón agbára won kò ká àwon agbésùmòmí yìí…
Continue after the page break for English Version
-
Wón pa ológun Nàìjíríà kan ní Sambisa lónìí.
Gégé bí olùrànlówó oníròyìn ti ìjoba ìpínlè Sokoto, Imam Imam òsìsé ológun (army officer) M Maiwada àwòrán eni tí ó wà lókè tí ó sèsè di Balogun (captain) ni won yín ìbon pa ní ojú ogun pèlú àwon Boko Haram lónìí ojó kejìdínlógbòn osù keje….
Continue after the page break for English Version
-
John Nani Pa Olúfà Ńlá, John Nani Tí Ó Jé Konmísónà Ní Ìpínlè Delta.
Konmísónà tí ó ń mójú tó àyíká (commissioner of environment), tí a mò sí Hon. Barr John Nani àti àwon emèwà rè kolu tí won sì pa olúfà ńlá tí ó won òsùwòn tí ó tó mítà lónà mérin ó dín mérin (3.6m) ní Awai nígbà tí won gbìyànjú àti sín kànáà (canal) láti gbógun ti omíyalé..Continue after the page break for English VersionAkékòó ilé -èkó Nwafor Orizu College Nsugbe ni àwon omo egbé òkùnkùn yin ìbon pa.
Léyìn àrídájú tó ji-n-gí-ri, mo le f’owó s’òyà pé pé ilé-èkó Nwafor Orizu College of Education Nsugbe ti pàdánù tí ó pò .Arákùnrin Mr Osaji Charles, tí ó jé Mr NASELS télè (2013/2014 session), ni won yín ìbon fún tí a kò sì mo eni tí ó yin ìbon náà níbi tí kò jìnà sí “ota Queen “. Mr Don Charles, bí ó se dáhùn lórí èro ayélujàra (facebook), ó ye kí ó parí ìdánwò àsekágbá ti eka-èkó rè ní ojó etì ojó ketàlélógún osù keje odún tí a wà yí (21st of July) tí ó sì ye kí o se ayeye ìkékòó jáde ní ojó karùndínlógbòn (25th) nígbà tí ó ti parí gbogbo ohun míràn tí ó ye kí ó se.A bá gbogbo ìdílé Osaji kédùn, pèlú àwon akékòó eka-èkó èdè gèésì English department NOCEN, pèlú gbogbo àwon ilé-èkó t’ókùn ní agbègbè náà. Àkókò yí ni inú wa bàjé púpò .Sùn -un re ooooContinue after the page break for English Version
Èsì ìdánwò alásekágbá ilé-èkó girama (waec)tí ó burúkú jù nínú odún 2017, tí a rí he.
Láàrin ogún-l’ógbòn àwon akékòó tí ó tó 1,559,162 tí won jòkó fún ìdánwò àsekágbá ilé -èkó girama tí a mò sí waec ní odún 2017 tí ó jé wípé òpò ni a ti rí, tí ó sì dára …Akékòó tí ó tó 926,486 ni won gba àmì C tí a mò sí credit Ókéré jù nínú isé bíi márùn-ún tí English- language àti Mathematics wà lára rè, bí àwa se ri, ohun tí a rí ni wípé ó dára ju odún kan àti kejì séyìn lo. Tí a sì gbé òsùwòn le tí ó tó 59.23% tí ti odún tí ó lo sì jé 52.9% àti èyí tí ó lo l’ódún méjì séyìn sì jé 38.7% . Látàrí eléyìí, èyí jé kí ó di mímò wípé odoodún ni yóò ma dára si àtiwípé ó tún máa jé kí òpòlopò omo se àseyege, tí won bá le tèsíwájú láti sisé kárakára, tí won sì fi gbogbo ara si, tí won sì ní ìpinnu tí àwon olùkó won kó won dáadáa, tí agbègbè àti àwon olólùfé won sì gbárùkù tì wón, mi ò rí ìdí kankan tí won kò fi ní yege.Nígbà tí àkókó rí èsì ìdánwò yí, awá rò wípé kò sí ìdí kan tí ó ni kí akékòó tí ó ti gbáradì fún ìdánwò dáadáa máa tiraka láti ní irú èsì ìdánwò tí ó dára báyìí…Continue after the page break for English Version
Ìbon ba àwon ajínigbé nígbà tí won ń dúnà pàsípààrò lówó ní ìjoba ìpínlè Abia.
Àwon ajínigbé mérin, èyí tí won ti ń da ìpínlè Abia àti agbègbè rè láàmú. Won ti ń gbìyànjú àti parun tí àwon òtelèmúyé so mó Omoba Division ní ojó ketàdínlógún osù keje (19th July ,2017) ní Ovungwu, Isiala -Ngwa ti Gúúsù Ìjoba ìbílè ìpínlè náà.Àwon òdaràn yí ni ojó kejidínlógún osù keje odún 2017(18th July, 2017) ní Osisioma Ngwa fé fi ipá gbé arákùnrin kan tí ó ń jé Onyemaechi Mbamaonyeukwu Ijeoma ‘m’ tí ó jé Olùdarí ilé-isé Mba Hotel Aba ní inú okò rè tí ó jé Nissan Infinity Jeep tí ó jé àwò eérú pèlú Nómbà ìdámò rè GWA 807 DH tí won sì gbà á sí inú ilé àkókùn kan ní Umuajuju Ovungwu, Isiala Ngwa ní gúúsù ìjoba ìbílè náà nígbà tí won ń dúnà pàsípààrò lówó…Nígbà tí won se èyí lówó, àwon òtelèmúyé tí ògá pátápátá DPO darí won, wo ààrin àwon ajínigbé yìí, gbàrà tí won rí àwon òtelèmúyé ni won bá bèrè sí ní yin ìbon. Nígbà tí won ń yin ìbon lówó méji nínú àwon ajínigbé tí a padà mò sí Nwadibia àti Monday ni ìbon pa tí àwon tókun sì bó pèlú ota ìbon l’ára won. Wón gba eni tí won nígbà kalè láì pa lára, ìkan lára àwon òtelèmúyé náà sì F’ara pa.Àwon ohun tí a rí gbà padà ní, okò eni tí won jígbé yí tí ó jé Nissan Infinity Jeep, òkadà méjì àti èro ìbánisòrò mérin.Ara òtelèmúyé tí ìbon bà ti ń m’ókun eni tí won jígbé náà ti lo bá àwon ebí rè, tí a ò sì tíì dáwó wíwá àwon òdaràn tí ó bó dúró….Continue after the page break for English VersionÒnà tí èèyàn le gbà gbé pèlú onítìjú obìnrin. (Ways To Deal With An Introverted Wife)
Tí ènìyàn bá wà lábé òrùlé kan náà, ó ye kí won kókó gbà pé ìwà wa kò le b’ára wa mu. Nígbà kan náà o kò ní láti yí enìkejì padà kí o sì jé oníyè ara re. Kódà bí o bá gbìyànjú tí a kò rí irú rè rí, o kò leè yí enikéni padà ní ayé yìí. Àsàyàn kan péré tí o ní ni kí ènìyàn mo ìwà fún oníwà. Onítìjú obìnrin àti aláròyé okùnrin le gbé papò láìsí ìjà. Níbi tí a bá ti gbó ara eni yé ni ìfé máa ń gbé. Àwon ònà rè tí a le gbà gbé pèlú onítìjú obìnrin.
Ònà tí a le gbà gbé pèlú onítìjú obìnrin rè é.
1 . Ó fé dáwà : tí ó bá wípé kí o fi òun sílè, má bínú si. Tí ó jé onítìjú obìnrin, ó kàn fé dáwà ni kìí kú se wípé kò fé kí bí ó se wà pèlú rè. Onítìjú nílò ìdáwà láti leè mú padà àti láti se ohun tí ó tó. Àkódá àti ìmólára tí won gbodò se ni, má Sì í gbó tí ó bá s’àdéédé dáké tàbí tí ó dáwà.
2. Jé kí ó wà lórí owó rè: sáà jé kí ó wà lórí owó rè, wò ó bóyá o leè gba ìgbésí ayé rè. Ó dára tí o bá leè jé kí ó gbé fúnra rè, tí ó bá fé kí o bá òhun sòrò, fúnra rè ló máa wá dìmó o gbàgì. Nígbà míràn o ti se oríre tí ó bá bá e se àwon eré kan tí onítìjú máa ń se.
3. Má fi agbára báa jo sòrò : tí ó bá dáké má fi agbára báa jo sòrò onítìjú máa dásí òrò tí ó bá dùn sùgbón won se èyí nígbà tí ó bá wù wón se kìí se tí ìwo bá fé, báyìí, nígbà míràn tí o bá bèrè sí ní so àwon òrò tí ó dùn, má rò wípé kí ó máa dunnú sí ní gbogbo ìgbà tí inú rè bá dùn e jo ma sòrò yín lo sùgbón tí ó bá tún yí sí bí ó se máa ń wà, ó kàn máa rora rérìń ni tí ó sì máa díbó bí eni tí ó ńgbó, tí o bá kàn jé kí ó wà lórí owó rè ó máa n’ìfé re si tí o bá se èyí.
4. Má fi agbára mu kí ó n’ìfé afefeyèyè : onítìjú máa ń se afefeyèyè sùgbón nígbà tí ó bá wù wón ni, báyìí, ònà wo ni à ń gbà gbé pèlú onítìjú obìnrin? Má fi agbára mu kí ó bá e lo sí òde ìròlé àti ohun afefe míràn tí ìwo kún fún. Sùgbón o leè bií Sé ó máa lo láti dáhùn wípé béèni tàbí béèkó , ìyàwó rè kò le dàbí re ní gbogbo ònà . Bòwò fún un lónà tí ó tó jáde pèlú àwon Òré re, ní tòótó, onítìjú obìnrin dára ju aláròyé obìnrin lo dáa dáa.
5. Fún un láyè díè :tí o bá leè fun ní yàrá òtò nínú ilé re, ònà kan gbòógi rè é tí o fi leè gbé pèlú onítìjú obìnrin. Ó máa ń n’ìfé ìpamó, má fura sí I, kò ní ohun tí ó ń fipamó fún o ó kàn máa ń gbádùn ibi tí ó dáké róró ni, báyìí, ó ye kí ó ti yé e yín ònà tí a le gbà gbé pèlú onítìjú obìnrin.
Ònà rè é láti gbé pèlú onítìjú obìnrin…..
Continue after the page break for English Version
Ìresì àsèpò Nàìjíríà (Nigerian jollof rice) ti gbé igbáorókè níbi ìdíje àjòdún Washington DC jollof.
Ìresì àsèpò Nàìjíríà (Nigeria jollof rice) ti kéde gégé bi ipò àkókó nínú ìdíje àjòdún Washington DC jollof. Ní ojó kejì osù keje odún 2017(july 2, 2017) omidan Atinuke Ogunsalu ti Queensway Restaurant &catering in Maryland US, ti se ipò kínní tí kò selè rí (jollof Hackathon) ti 1/0 se agbáterù rè níbi ayeye àjòdún ní Washington DC. Afropolitan insight ló se àgbékalè ètò náà.
Omidan Ogunsalu fi hàn fún gbogbo èèyàn wípé ní tòótó àwon ènìyàn Nàìjíríà le se ìresì àsèpò tí a mò sí jollof nígbà tí ó bá orílè èdè rè gbé igbáorókè. Àwon tí won jo figagbága ní orílè èdè Cameroon, Ghana àti Sierra Leone. Òkòòkan àwon tí ó wo ìpele tí ó kéyìn yí, ni a fún ní ìséjú márùn-ún márùn-ún Láti gbé ohun tí won ti se síwàjú, Adájó tí ejó won dà lórí I Akópa; ohun tí won fé se; tí tó wò àti bí ó se sè é.
Olùgbadé tuntun omidan Ogunsalu gba Dólà lónà egbèrún kan (US$1000) gégé bi olùbásisé pò láti owó olùbá-da-isé-pò 1/0 spaces àti àwon ànfààní láti di alásè ní jollof caviar African Fusion Restaurant èyí tí won sí ní Washington DC ní odún 2009…..
Continue after the page break for English version




