Ààrẹ Buhari kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú àfaradà bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ lásìkò Coronavirus yìí
Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni kú ọdún Àjíǹde tó fi ṣọwọ́ sáwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ààrẹ Buhari ṣàlàyé pé ìgbáyégbádùn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kìí ṣé oun tó ṣe é dúnàádúrà lé lórí ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ ààbò àti àlàáfíà aráàlú ṣe kókó. Ààrẹ fi kún un pé, ó wu òun kí wọ́n jáde ṣọdún Àjíǹde, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid 19 yìí ń gbẹ́mìí kúkúrú gígùn, o sì jẹ́ ohun ìbànújẹ́. Ààrẹ wá fikún un pé,ki àwọn ènìyàn o tẹ̀lé òfin kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba ti pàṣẹ kónílé-ó-gbélé o.
Àdúrà làsìkò yí gbà pẹ̀lú ìfaradà láti ṣẹ́gun àrùn apinni léèmí Coronavirus–Ààrẹ Buhari
Ìròyìn tó bá ọ̀pọ̀ lẹ́jafùú ni ìròyìn ‘Mo ti ní àrùn Coronavirus’ èyí tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé gbé jáde ní ọjọ́ Ajé lójú òpó twitter rẹ̀.
Níbáyìí tí ó ti lo ọjọ́ méjì ní ìgbélé lẹ́yìn ìkéde yìí, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé ti ṣàlàyé pé pẹ̀lú àánú Ọlọ́run, kò sí nǹkan tí Coronavirus leè fi òun àtàwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó ní àrùn náà ṣe.
Mákindé tó ní òun dúpẹ́ fún òbítíbitì òjò àdúrà tí gbogbo èèyàn ń fi ṣọwọ́ sí òun ṣàlàyé pé àdúrà náà ti ṣọ òun di bẹ́mìídíje , ẹ̀mí òun yi gírígírí, eléyìí tó fi ń dájú pé òun àti gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ọ̀rọ̀ kan yóó rùú là.
Gómìnà Mákindé wá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà láti máa tẹ̀lé ìtọ́ni àti Ìlàkalẹ̀ Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Ìjọba gbé kalẹ̀ láti gbógun ti àrùn COVID-19 ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti leè tètè kápá àrùn náà lọ́gán ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.
Níbáyìí, èèyàn mẹ́jọ ló ti kó àrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nínú èyí tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé pẹ̀lú wọn.
Bákan náà ni wọ́n ti tú èèyàn kan sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó gba ìwòsàn lọ́wọ́ àrùn ọ̀hún.
À fi kí Ọlọ́run gbani lọ́wọ́ ẹni tó ń ṣọ́ni tá ò ṣọ́ o, ló dífá fún kójú má ríbi,gbogbo ara lòògùn rẹ̀, bí gbajúgbajà olórin wákà, Salawa Abẹni ti sọ pé, òun ti fi ẹjọ́ abani lórúkọ je tó fẹ́ fi àwòrán ìhòòhò òun léde lórí itàkùn àgbáyé sun Ìjọba.
Salawa ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn.
Ó ní òun kò mọ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ibi ọ̀hún, ṣùgbọ́n bí ikú ilé ò pani, tòde kò lè pani.
Salawa sọ pé ọkùnrin náà bá òun ṣọ̀rọ̀ lórí ìkànnì WhatsApp, tó sì sọ pé kí òun fún un lówó, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun yóó fi àwòrán ìhòòhò rẹ̀ léde fún gbogbo ayé láti rí.
Gbajúgbajà olórin wákà náà ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò tu irun kankan lara oun.
Lẹ́yìn náà ló sọ pé òun kò leè gbà kí ẹnikẹ́ni ba orúkọ òun jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó ti ń to orúkọ ọ̀hún jọ, ìdí rè é tí òun ṣe fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn agbófinró létí.
Ṣaájú ni Salawa ti fi ọ̀rọ̀ kan léde lójú òpó Instagram rẹ̀, níbi tó ti ṣàfihàn àtẹ̀ránṣẹ́ ti ọkùnrin náà, tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Jason tẹ̀ ẹ́ sí.
Ọkùnrin ọ̀hún ṣọ pé kí Salawa fún òun lówó, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun yóó fi àwòrán ìhòòhò Salawa léde fún gbogbo àgbáyé láti rí.
Lẹ́yìn èyí ni Salawa fún ra rẹ̀ wá fi àwòrán ọ̀hún léde.
Ogún ènìyàn jàjà bọ́ lọ́wọ́ coronavirus Ìròyìn láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Ni ipinle Eko ni ori ti ko ogun eniyan yo ni ile iwosan ti won ti n toju awon ti kokoro Covid-19 n ba ja.
Bi o tile je pe won ni ko si oogun kan gbogi fun aisan naa sugbon Eledua n fun ipinle Eko se lati ni aseyori lori itoju awon alaisan naa. Ti a ko ba gbagbe, arakunrin omo orileede Italy ni o koko gba iwosan naa ki awon meta miiran, marun-un miiran ki mokanla to kun-un ni oni ojo keji, osu kerin odun ti a wa yii.
Ijoba apapo, ipinle ati ibile pelu ajo NCDC ni ki awon eniyan ma se dawo imototo duro ki onikaluku si gbe ile re fun igba die ki arun buruku naa le kase nile patapata.
Ronaldinho ń kó̩ is̩é̩ gbé̩nàgbe̩nà nínú è̩wò̩n ní orílèèdè Paraguay
Lati owo Akinwale Taophic
Ogbontarigi ninu boolu alafesegba to je omo bibi orileede Brazil ti o si ti fi igbakan ri je eni akoko ninu boolu alafesegba kaakiri agbaye, Ronaldinho, ti wa ninu Ewon ni orileede Paraguay bayii lati nnkan bi osu kan seyin latari esun wi pe o lo iwe irinna ayederu wo orileede naa pelu aburo re kan.
Lati igba naa, gbogbo awijare oun ati aburo lori ejo naa, eyin eti adajo ni o n bo si titi di akoko yi, inu ewon ni o wa ti o ti n lo Daola pelu aburo re. Iroyin fi to wa leti wi pe gbogbo awon elewon ni won ni ife re gidi gan-an, ti oun naa si n se daradara pelu won ati wi pe o n ba won gba boolu papo loore-koore lai fi ibanuje okan re han sita rara.
Ni bayii, iroyin tuntun ti a gbo ni wi pe o ti n ko ise gbena-gbena (Capentary works) ninu ewon, ti o si gba oju mo gidi gan an ni.
Ohun ti o tun je edun okan ni wi pe arakunrin yi ti se gudugudu meje ati yaaya mefa ninu boolu alafesegba kaakiri agbaye ajaaja fun orileede abinibi re-Brazil, ohun ti o le fa bi won se wa n wo niran ni ko ye enikankan di akoko yi ati wipe ojo abameta ti o koja lo yi arakunrin naa pe omo ogoji odun laye eyi ti o ba ninu ogba ewon.
Ẹni mẹ́rin mì ìn kó àrùn apinni ní mímí èèmii coronavirus ní Nàìjíríà,àfàmọ̀ kò mọ́ dà bí i ti China,l Italy— Mínísítà kìlọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìgbọrọ̀ sàn ju ẹbọ rúrú fún ẹni tó bá fẹ́ gbọ́ ni o. Ó ti di ogójì èèyàn tó ti lùgbàdì àrùn coronavirus báyìí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tí àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC kéde àwọn mẹ́rin míì tó ti ní àìsàn náà lálẹ́ ọjọ́ Ajé.
Àjọ NCDC ṣàlàyé pé mẹ́ta nínú àwọn èèyàn wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí ẹyọ kàn tó kù wá láti olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abuja.
NCDC ní àwọn méjì nínú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ rìnrìn àjò dé láti òkè òkun ni.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé àjọ NCDC lójú òpó Twitter rẹ̀, èèyàn méjì nínú àwọn ogójì èèyàn tó lùgbàdì àrùn Covid-19 ní Nàìjíríà ti kúrò nílé ìwòsàn.
Èèyàn kan ti dèrò ọ̀run nínú àwọn tó lárùn náà ní Nàìjíríà, ọjọ́ Ajé ni ọkùnrin náà ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin kú.
Ohun tí a gbọ́ ni pé ọkùnrin ti ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà àti àrùn jẹjẹrẹ lára tẹ́lẹ̀ kí ó tó lùgbàdì coronavirus.
Ní báyìí, èèyàn méjìdínlọ́gọbọ̀n ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó nínú ogójì tó lárùn náà ní Nàìjíríà, méje Èèyàn méjì wá láti ìpínlẹ̀ Ogun, nígbà tí ìpínlẹ̀ Èkìtì, Oyo àti Edo ni ẹyọ kọ̀ọ̀kan.
Ẹ̀wẹ̀, mínísítà fún ètò ìlera, Dókítà Osagie Ehanire ti sọ pé àfàìmọ̀ kí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà náà ó má dàbí ti orílẹ̀-èdè China àti Italy lórí bí ọ̀rọ̀ coronavirus ṣe ń lọ yìí.
Mínísítà ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ní àrùn coronavirus ni wọ́n ń déjú mọ́lé, dípò kí wọ́n jáde fún ìtọ́jú kí àrùn náà má ba à ran àwọn mìíràn.
Àwọn fíìmù òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú
Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ẹgbẹ́ burúkú ba ìwà rere jẹ́.
Ajíyìnrere Felicia Iyabode Ogunsola tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Efúnsetán Aníwúrà, Ìyálọ́de ìlú Ìbàdàn nínú eré, ti kìlọ̀ fáwọn òṣèré tíátà láti dẹ́kun àṣà ṣíṣíra sílẹ̀ nínú fíímù.
Efúnsetán ní àṣà burúkú gbáà ni. Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe ohun tó dára kí àṣírí ọyàn máa hàn síta,iṣẹ́ Èṣù ni.
Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá nígbà tí òun fi ń ṣeré lábẹ́ ògbóǹtarìgì òṣèré, olóògbé Iṣhola Ogunsola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Isho Pepper.
Iyabode Ogunsola ní àṣà àìbìkítà, àti àìlójútì gbá à ni. Ó ní àṣà àwọn òyìnbó ni àwọn òṣèré òde òní ti gbé wọ eré tíátà Yorùbá.
Àgbà òṣèré náà ní àṣà kí á máa yìnbọn pò pò pò nínú fíímù ló kọ́ àwọn ọmọ lólè láyé òde òní, dípò kí àwọn ọmọdé máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀.
Ó rọ ọ̀pọ̀ òṣèré tí wọn kò tíì lọ kẹ́kọ́ọ̀ eré tíátà ṣíṣe níbì kankan pé kí wọ́n yára tètè lọ se bẹ́ẹ̀ nítorí kò sí òṣèré kan tí kò kẹ́kọ́ọ̀ lábẹ́ ẹnìkan nígbà tàwọn náà.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ojú òpó ìkànsíraẹni Twitter ti dásí ọ̀rọ̀ láàrin Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi àti àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà.
Èyí kò sẹ́yìn lẹ́tà tó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kìlọ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti láti ṣọ́ra ṣe, ki o si tẹlẹ jẹjẹ.
Ìròyìn ohun jáde pé, Gómìnà Fayemi ni wọ́n ló fi ìwé wítẹnuùrẹ ránṣẹ́ sí àwọn ọba mérìndínlógún ní ìpínlẹ̀ nítorí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí òun lẹ́nu.
Fayẹmi ni wọ́n ló sọ pé àwọn ọba náà kọ̀ láti wá si ìpàdé àwọn lọ́balọ́ba àti Ìjọba láti Oṣù Kẹjọ, ọdún 2019 nítorí náà, kí wọ́n sọ ìdí tí wọ́n fi gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Àmọ́ Aláàfin nínú lẹ́tà tí wọ́n ló kọ sí Fayẹmi sọ wí pé, àgbáríjọpọ̀ àwọn ọba ní ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ló fọwọ́sowọ́pọ̀ fi ìkìlọ̀ náà ránṣẹ́ sí gómìnà náà, láti máṣe fi orí adé tẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀.
Aláàfin ní inú àwọn ọba náà kò dùn nítorí pé Gómìnà Fayemi fi ọba tó kéré ní ipò jẹ adarí ẹgbẹ́ àwọn lọ́balọ́ba nípìńlẹ̀ náà, Ìdí sì nìyí tí wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.
Àmọ́ àwọn ènìyàn to fèsì lórí Twitter sí lẹta náà sọ wí pé, ohun tí Aláàfin ń sọ yìí ló ń kìlọ̀ fún Fayemi wí pé, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣẹ̀ ìpínlẹ̀ Kano tí gómìnà ti ń yọ Emir, tí yóó sì le kúrò ní ìlú nígbà tó bá wù ú.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn míràn sọ wí pé, ìbẹ̀rù bojo mú àwọn ará Èkìtì nítorí Fayemi fẹ́ yọ Èwí ti ìlú Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe àti àwọn ọba mọ́kànlá míràn, tó ń fapá jánú sí gómìnà ìpínlẹ̀ náà.
Awon onpitan wu itan Emir Kano ana jade. Won ni oro re dabi egun ti baba baba re ti se sile. Won ni odun 1963 ni ede aiyede waye laare Emir Mohammed Sanusi to je baba eni ti gomina yo ni ana yii pelu Amenh Oboni ti ilu Igala.
Rogbodiyan yii naa ni o yo baba Sanusi ana kuro lori oye. Odun ketadinlogota naa ree bi ana, ti gomina Gaduje tun yo Emir Sanusi kuro bi eni yo jiga. Loju ese naa ni won fi omo Aminu Ado Bayero dipo re.
Orisiirisii esun ni ijoba ipinle Kano fi kan Emir Sanusi, won ni o se owo rogunrogun kan maku maku ti ko si alaye gidi Kankan lori re. Won ni ko ki n gboro si ijoba ipinle naa lenu rara. Gbogbo eyi ni won ko po ti ijoba ipinle naa fi ni osuwon re ti kun.
Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn
Ọjọ́ kẹjọ ọdọọdún ni àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé níbi tí gbogbo àgbáyé tí ń kọjú sí àwọn obìnrin láti yòǹbó àwọn iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n gbé ṣe láì nọ́ọ́ní onírúurú ìpèníjà, ẹ̀dùn ọkàn àti Ìlàkàkà wọn fún àṣeyọrí gbogbo Ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin pẹ̀lú ìdọ́gba pẹ̀láwọn ọkùnrin ló gbòde gẹ́gẹ́ bíi ohun òjútáyé lásìkò àjọyọ̀ àyájọ́ obìnrin lágbàáyé ti ọdún yìí.
Àkọmọ̀nà àyájọ́ náà fún ọdún yìí ni “ajàfẹ́tọ̀ ìbáradọ́gba ni mí: mímú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ṣẹ.”
Nínú ọ̀rọ̀ tiwọn, àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé rọ àwọn èèyàn gbogbo láti jí gìrì gbógun ti àwọn ìpèníjà sísọ àìdọ́gba láàrin ẹ̀yà ẹ̀dá gbogbo.
Nínú ọkàn ò jọ̀kan ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣọ ní ìrántí àyájọ́ yìí, àwọn obìnrin ní oríṣìríìṣí Ìlànà iṣẹ́ ajé gbogbo sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà tí wọ́n ń dojúkọ; paàpá jùlọ láàrin àwọn ọkùnrin lẹ́nu iṣẹ́ ajé gbogbo léyìí tí ò jẹ́ adínàgboòkú.