Home / Àṣà Oòduà / Mo Ti Fi Ẹjọ́ Abani Lórúkọjẹ́ Tó Fẹ́ Fi Àwòrán Ìhòòhò Mi S’órí Ìtàkùn Àgbáyé Sun Ìjọba – Waka Queen

Mo Ti Fi Ẹjọ́ Abani Lórúkọjẹ́ Tó Fẹ́ Fi Àwòrán Ìhòòhò Mi S’órí Ìtàkùn Àgbáyé Sun Ìjọba – Waka Queen

À fi kí Ọlọ́run gbani lọ́wọ́ ẹni tó ń ṣọ́ni tá ò ṣọ́ o, ló dífá fún kójú má ríbi,gbogbo ara lòògùn rẹ̀, bí gbajúgbajà olórin wákà, Salawa Abẹni ti sọ pé, òun ti fi ẹjọ́ abani lórúkọ je tó fẹ́ fi àwòrán ìhòòhò òun léde lórí itàkùn àgbáyé sun Ìjọba.

Salawa ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn.

Ó ní òun kò mọ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ibi ọ̀hún, ṣùgbọ́n bí ikú ilé ò pani, tòde kò lè pani.

Salawa sọ pé ọkùnrin náà bá òun ṣọ̀rọ̀ lórí ìkànnì WhatsApp, tó sì sọ pé kí òun fún un lówó, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun yóó fi àwòrán ìhòòhò rẹ̀ léde fún gbogbo ayé láti rí.

Gbajúgbajà olórin wákà náà ṣàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò tu irun kankan lara oun.

Lẹ́yìn náà ló sọ pé òun kò leè gbà kí ẹnikẹ́ni ba orúkọ òun jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó ti ń to orúkọ ọ̀hún jọ, ìdí rè é tí òun ṣe fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn agbófinró létí.

Ṣaájú ni Salawa ti fi ọ̀rọ̀ kan léde lójú òpó Instagram rẹ̀, níbi tó ti ṣàfihàn àtẹ̀ránṣẹ́ ti ọkùnrin náà, tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Jason tẹ̀ ẹ́ sí.

Ọkùnrin ọ̀hún ṣọ pé kí Salawa fún òun lówó, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, òun yóó fi àwòrán ìhòòhò Salawa léde fún gbogbo àgbáyé láti rí.

Lẹ́yìn èyí ni Salawa fún ra rẹ̀ wá fi àwòrán ọ̀hún léde.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

One comment

  1. @fowosereomoba .Follow me and get followed back immediately

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...