Tag: ifa

  • “Ta Ní Ó Wà Kí Ayé Tó Wà? Ìtàn Àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀dá Gẹ́gẹ́ Bí Ifá Ṣe Sọ Ó.”

    “Ta Ní Ó Wà Kí Ayé Tó Wà? Ìtàn Àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀dá Gẹ́gẹ́ Bí Ifá Ṣe Sọ Ó.”

    Kò sí ohun ẹlẹ́mìí kankan láyé

    awo ilé Ayé ni ọ̀run àkọ́kọ́,

    ohun tí ó so kàrà tí kò sọ̀kalẹ̀,

    awo òde Ọ̀run ni ó ń pè é,

    gbogbo rẹ̀ jẹ́ òfìfo lásán, òfo pónbele,

    láìní ìpìlẹ̀, láìní ẹ̀dá kankan,

    Awo àárín gbùn-gbùn òde ni ó wí i,

    A dífá fún Ayé àti fún Ọ̀run,

    nínú ìkarawun ìgbín méjì tí ó ṣófo,

    kò sí ẹyẹ, kò sí ẹ̀mí tí ń gbé inú wọn,

    ìpìlẹ̀ kò tí ì sí, afẹ́fẹ́ kò tí ì mí.

    Èdùmàrè ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀,

    òun nìkan ni okùnfà àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá,

    òun nìkan ni ìpele tí Ayé ń dúró lé,

    òun nìkan ṣoṣo ni ọlọ́gbọ́n ní Ọ̀run,

    ẹni tí ó dá ènìyàn láti inú òfo,

    nígbà tí kò ní ẹgbẹ́, tí kò ní olùrànlọ́wọ́,

    ó lo ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ náà ní ìbẹ̀rẹ̀,

    ọgbọ́n ni ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀, kí ìparun má bà à wọlé,

    òun nìkan ṣoṣo ni ó wà ní gíga Ọ̀run.

    Orúkọ Èdùmàrè ni èyí, ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo,

    ẹ gbé ọpẹ́ fún ọkàn-ìmọ̀ kanṣoṣo,

    ìwọ nìkan ni o dá ẹ̀dá ènìyàn,

    a gbọ́ tẹnu ẹnìkan, o sì dájọ́,

    gbogbo ènìyàn ní ìtẹ́lọ́rùn, Àṣẹ!

    ohun tí o pinnu, kò sí ẹni tí ó yí i padà,

    Ọ̀rọ̀, okùnfà àníyàn ńlá,

    fún ọlọ́gbọ́n àti fún àgbà tí ó ti ní ìrírí,

    Àṣẹ.

  • Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

    Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

    Òní laó roko létí opón
    Òla laó sákà lágbèrù
    Kùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòni
    Káyáa múlé pontí
    Kámú òdèdè rokà
    Káfi agbada dínran
    Àwèje wèmu nípón omodé wòyí lójú
    Òrìsà lópabuké tán
    Lódákún sábaro nídìí
    Omo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjo
    Omo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjo
    Ilé-ifón kògba obàtálá
    Èlàgboro kògba òrìsà
    Ojúgboro ni tàfín
    Èlàgboro ni tòrìsà
    Omi níti ojú-omi rúwá
    Èròyà wáàpon
    Èròyà wáàmu
    Rúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkò
    Erú kùnrin won nííjé bánakú
    Erú bìnrin won nííjé wòrúkú
    Dimúdimù aleìgbò
    Okùnrin yàkàwú orí ìgbá
    Ìgbá kòwó
    Okùnrin yàkàwú kòsòkalè
    Òní laóko igbó olú-kóókó-bojo
    Òla laóko igbó olú-kóókó-bojo
    Akogbó olú-kóókó-bojo tán
    Apa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtí
    Wónní kí ákun-un
    Kágbé oríirè fún obanídòó ejèrùwà-ìlèkè
    Kágbé gègè àyàarè fún obaléyò ajòòrí Omo ajorí emi gbára
    Kágbé gegelúge ìdíirè fun olúléhùnpejìgá Omo iná abara húta òjò palami okà se yèrìyèrì
    Enití nbá perí obanídòó orí gbogbo amón-on fówon iwéréré-iwéréré
    Enití nbá perí obaléyò ajòrí àyà gbogbo amón-on jìnwón igìrìrì-igìrìrì
    Ènìyàn tí nbá perí olúléhùnpejìgá ìdí won yíò món-on lu agbè yàba ikunkun-ikunkun
    Ogun obanídòó niná
    Teléyò loòrùn
    Ogun olúléhùnpejìgá logun Oba tínkówon iróro-iróro
    Àpagbé awo ojó díáfún ojó
    Àràngbé awo òòrùn díáfún
    Tóbádi ojókan soso òjò
    Yíóborí egbegbèrún òdá
    Tóbá pawón tan
    Apogun won ibíti-ibíti
    Adífáfún olófin àyàngbo-àsè
    Èyítí wónní kósáré losí òkè ohùnkò
    Kólorèé jáwé abílè tíkòníkú wá
    Ikú kò ikú kògbodò pa babaláwo
    Àìsè àjà gbonhun
    Húnró gbonhun lésè oba òrìsà
    Kínni óní kíbi óyè lórí awo ?
    Èjì-òyè òtító nikú yè lórí awo
    ÈJÌ-ÒYÈ.
    Ikú kòní pawá ní rèwerèwe ooo

  • Òyèkú bìwòrì

    Òyèkú bìwòrì

    Òyèkú bìwòrì,
    Gbóró,gbóró,gìdì ? òyèkú b’ìwòrì?
    Ajan gbóró gìdì
    Adífáfún lájosìn
    Omo ab’oya ríre
    Èyí tio bo òrìsà obìnrin là
    Èròpo àti tòfà
    B’ifá bá..bíni níbè
    Oya ni ko maa bo

    ~Translation ~

    Òyèkú bìwòrì
    Gbóró gbóró gìdì
    Ajan gbóró gìdì
    Cast ifá for lájosìn
    The one that worship oya with blessings
    The one that is destined to worship oya to be successful
    People going to ipo, People going to offa
    Whenever someone is born with this odù ifá
    Must worship òrìsà oya and take her as his or her priority
    For him or her to be successful in life.

    Àse òrìsà?

  • Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

    Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

    Looking at the Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá, it could be said that sometimes our detractors feel they are hurting us but they don’t know they are pushing us to wealth. Just listen to this stanza from the Odù.

    Òtééré ilè ńyó
    Òtèèrè ilè ńyò
    Ilè ńyó ará iwájú
    Èrò èyìn e kíyèsí ílè
    Adífá fún Ìwòrì tí yóó tarí Ogbè sínù àbàtàbútú ajéKòìpé kòìjìnà, Ogbè ló wá jìn sínú ajé gbugburu

    Òtééré, the ground is slippery
    Òtèèrè, the ground is difficult to walk on
    The ground has made the frontline people to slip
    Those coming behind should be cautious
    Cast divination for Ìwòrì who will push Ogbè into a deep trench of treasures
    In a short time, Ogbè fell into a pit of prosperity.

    Short story- Ìwòrì betrayed his friend Ogbè as a result of envy and greediness by pushing him into a trench so that he could inherit all the profits they made in their business not knowing that it was a trench of prosperity. May our enemies push us to the land of joy.

    Happy Òsè Ifá today to you all.
    Stay blessed From Araba of Oworonsoki land Lagos Nigeria

  • Ifá ní yini yini kí eni le se òmíràn

    Ifá ní yini yini kí eni le se òmíràn


    Adífáfún ifátérú tí se omokùnrin ìgódó,
    Èdùmàrè àwa yìn ó kí o tún le se òmírán.?????
    I give thanks to Elédùmarè, for everything he has done for me, orí modupe, Ifa modupe, Egbe aye ati t’òrun modupe lowo yin.??????

    Thanks to everyone who wished me yesterday despite their tight schedule, thanks for the messages, calls, gifts, prayers, posts???? I am really grateful ?????May God bless you all?????I love you all❤️❤️❤️?

  • Ògúndá Méjì: Odù

    Ògúndá Méjì.
    It is a fact that there is anxiety all over the World as a result of coronavirus pandemic. This is a challenge to all faiths. What else can we do other than supplication and offering.

    Looking at Odù, “Ògúndá Méjì, cast for today’s Òsè Ifá, Olódùmarè shall heal the World by sending out the rain. Just listen as follows:-

    Igún ńse dìgbó
    Àkàlà ńse dìgbó
    Adífá fún Olákanrígbò tíí se Yèyé Ayé
    Olákanrígbò mámà jáyé ó ra
    Bó bá kù dèdè káyé ó ra, òjò a rò
    Olákanrígbò mámà jáyé ó ra o
    Ìpòrì Ayé kìí jé káye ó ra
    Olákanrígbò làápe Olódùmarè
    Ayé làápe Ilé Ayé

    Ògúndá Méjì
    Ògúndá Méjì

    Igún ńse dìgbó ( name of sage)
    Àkàlà ńse dìgbó ( name of sage)
    Cast divination for Olákanrígbò, the mother of Mother Earth
    Olákanrígbò, don’t let the Earth perish
    If its likely for the Earth to perish, rain shall fall
    Olákanrígbò, please don’t let the Earth perish
    The guardian spirit of the Earth will not allow the Earth to perish
    Olákanrígbò is the name of Olódùmarè
    Mother Earth is the World.

    May Olódùmarè heal the World.
    Bàbá( Our Heavenly Father), send out the rain.

    From Araba of Oworonsoki land Lagos Nigeria

  • Ìjọ Ọ̀rúnmìlà Ifákáyéjọ afi òtítọ́ ayé hàn

    Àwa ni ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo Ìjọ mímọ́ Ọ̀rúnmìlà ní gbogbo àgbáyé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí àńpè ní Ifá ni a fín to Ìjọ tiwa

    Ifá(ọ̀rọ̀ Ọlọ́run)ni afi kó ayé jọ
    Ọ̀rúnmìlà(aṣíwájú rere)ní abá ni táyése

    Ẹ wá bá ọ̀rọ̀ ẹnu Ọlọ́run tí àńpè ní Ifá pàdé nínú ìjọ wa, kí ìtumọ̀ sí bá ìgbésí ayé rẹ lọ́dún titun

    Awóyemí Ọlọ́run wà 1
    Ṣókinlójú arẹ̀mọ ẹ̀dú
    Aníkin ajé níkùn 1
    Small but mighty
    CEO Gbasky bitter

    Mo sé ní ìwúre sí Ọlọ́run fún orí kọ̀ọ̀kan wa lókùnrin lóbìnrin lọ́mọdé àti àgbàlagbà wípé gbogbo oun tó sokùnkùn nínú ayé wa,pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè ìmọ́lẹ̀ yóò tàn nínú ọdún titun,okùnkùn yóò sì wábigbà

  • Òlódumarè les bendiga, que tengan una feliz y bendecida tarde.

    Ẹ̀là mo yìn bọrú.
    Ẹ̀là mo yìn bọyè.
    Ẹ̀là mo yìn bọ’ṣíṣẹ.

    Òlódumarè les bendiga, que tengan una feliz y bendecida tarde.

    Ijuba. Doy reverencia.

    Ìdà kí si ònà ní nse ejó lè yín
    A’dífá’fún Esin ohun Agbo
    Ti wòn nse Awo losí ilé oní Alákétu
    Njó tó jí ti kò ojúnbà Bàbá
    Ti kò ojúnbà Yèyé
    Ìbà Bàbá
    Ìbà Yèyé
    Ìbà Olówò
    Ìbà Ojù’gb’ònà……
    Ìbà apásá pà aso má nrò ó
    Ìbà ó kú tè gbogbo a rò so má ojúnbà.
    Aya má n’fohun táábadase
    Koro man saìgbá… Àsè

    Si la serpiente no cruza el camino rápidamente la matan con el machete
    Realizaron Adivinación de Ifá para el caballo y el carnero
    Cuando se iban de viaje de adivinación a la casa de Alákétu
    En el día que se despertaba sin darse la reverencia al padre
    Sin darle reverencia a la madre
    Yo le doy reverencia al padre
    Yo le doy reverencia a la madre
    Yo le doy la reverencia al rey
    Yo le voy la reverencia a la Ojù’gb’ònà
    Yo le doy la reverencia al montón de ñame que se le cubre con muchas hojas sin amarrarles
    Al menos que hagamos algo sin dar la reverencia
    Que el ritual o la ceremonia sea aceptado y exitoso… Àsè

    Ki Edumare fi ese mi mule ninu igbagbo yi. Àsè ooo

    A los pies del Creador yo bebo de la Tierra y hago un pacto con esta creencia… Así sea

    Por un mejor entendimiento de la Religión Yorùbá.

    Fá’nimoko Idin funfun.

  • E ku Ose Ifa

    Aráká-Ajaga
    Aràkà-Ajaga
    Adifun Eniyan Ti Mú Iyè Meji Sin Èdú
    Ènìyàn Ti O Sin Èdú,Ko Ma Se Iyè Meji
    Aráká-Oku-Ajaga
    Aràkà-Oku-Ajaga

    ??Ase Tedumare??

    ?Ifabukky Care?

  • Odu Ifa,”Irosun Oyeku” Cast Today For Ose Ifa

    Looking at Odu Ifa, “Irosun Oyeku” cast today for Ose Ifa, I can advise all Priests and Priestesses to imbibe calmness in their characters so that they can always achieve their desires. Secondly, the stanza contains one of the Yoruba wise sayings which is to prove again that Ifa is the encyclopedia of the Yoruba language. Just listen to the verse as follows:-

    Igba kele kii fo
    Awo kele kii ya
    Aso kele kii gbonya
    Ohun a ba feso mu kii baje
    Ohun a ba fagbara mu nii le koko bi ota
    Adifa fun Orunmila
    Baba nlo ree gbe Kele niyawo
    Ki la fi mu kele dele more
    Eso eso nla fi nmu kele de’le
    Eso eso

    Calabash handled with care does not break
    Ceramic handled with caution does not shatter
    The garment worn with elegant care does not shred abruptly
    Things handled with caution do not spoil
    Those enforced violently present stony difficulties
    Divine message to Orunmila
    When courting Kele for a wife
    How did we win Kele’s hand ultimately
    Gentleness and perseverance, that was how we won Kele’s hand
    Patience and gentleness.

    Happy Ose Ifa today to you all.

    Stay blessed.