Home / Àṣà Oòduà / Ayeye Ojo Ibi Oba Lamidi

Ayeye Ojo Ibi Oba Lamidi

Oba Alhamis Olayiwola Atanda Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo, pe eni odun metadinlogorin (77) lojo keedogun osu kewaa odun yii loke eepe.

Ayeye ojo ibi Oba Lamidi ni Omooba Akeem Adeyemi, eni to je okan lara awon omo ile gbimo asoju-sofin to wa l’Abuja se fun baba re lati fi dupe fun didasi ti Edua oke da baba re si.

Lara awon eto to waye ni ifilole gbongan nla kan nibi ti awon odo ilu naa yoo ti maa ko nipa imo ayarabiasa komputa.

Awon ori ade naa o gbeyin kaakiri ile Yooba, eleyii ti won dide lati bu ola oun iyi fun omo bibi inu Adeniran. Lara awon oba alade ti won ye Alaafin si ni Oba Osolo ti Isolo, Oba Kabiru Adelaja ati akegbe re lati ilu Eko, Oba Idowu Abiodun Oniru.

Ojo keedogun osu kewaa odun 1938 ni won bi Oba Lamidi. Ojo kejidinlogun osu kokanla odun 1970 lo gori ite baba re leni odun mejilalogbon (32).

Oba Lamidi Olayiwola to je okan lara awon oba alagbara ju lo ni ile Yoruba naa ni alaga igbimo lobaloba ipinle Oyo.

Olarewaju Adepoju, okan lara awon akewi ile Yoruba, se apejuwe Oba Lamidi lodun 1980, ni akoko odun kewaa oba Lamidi lori ite, gege bi Oosa yato si igbakeji Oosa ti awon eniyan n pe e.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo