Home / Àṣà Oòduà / Bí Ẹ Bá Rí Ilá L’ọ́jà Kí Ẹ Ma Rà Fún Mi
Bí Ẹ Bá Rí Ilá L'ọ́jà Kí Ẹ Ma Rà Fún Mi

Bí Ẹ Bá Rí Ilá L’ọ́jà Kí Ẹ Ma Rà Fún Mi

Mo ní èmi ò fẹ́
Mo ní èmi ò jẹ
Bí ẹ bá rí ikàn l’ọ́jà kí ẹ ma rà fún mi
Mo ní èmi ò fẹ́
Mo ní èmi ò jẹ
Atẹ̀gbẹ̀ tí o bá délé Olódùmarè kí o ra ọmọ wẹrẹ wá fún mi
A dífá fún Àbẹ̀kẹ́ tí ń se eléwùrà l’ọ́jà tí n se elépo ní imọdẹ àgàn òde àpà
Ẹkún ọmọ lo n sun
Òun le bímo lópòlopò ni ndafa sí
Ẹbọ lawo ni kóse
Kò sí ohun tó wuyì ju ọmọ lọ
Ọmọ làdèlé ẹni
Kò sí ohun tó wuyì ju ọmọ lọ.
Ire o?

Bí Ẹ Bá Rí Ilá L'ọ́jà Kí Ẹ Ma Rà Fún Mi

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ta Ní Ó Wà Kí Ayé Tó Wà? Ìtàn Àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀dá Gẹ́gẹ́ Bí Ifá Ṣe Sọ Ó.”

Kò sí ohun ẹlẹ́mìí kankan láyé awo ilé Ayé ni ọ̀run àkọ́kọ́, ohun tí ó so kàrà tí kò sọ̀kalẹ̀, awo òde Ọ̀run ni ó ń pè é, gbogbo rẹ̀ jẹ́ òfìfo lásán, òfo pónbele, láìní ìpìlẹ̀, láìní ẹ̀dá kankan, Awo àárín gbùn-gbùn òde ni ó wí i, A dífá fún Ayé àti fún Ọ̀run, nínú ìkarawun ìgbín méjì tí ó ṣófo, kò sí ẹyẹ, kò sí ẹ̀mí tí ń gbé inú wọn, ìpìlẹ̀ kò tí ì sí, afẹ́fẹ́ kò ...