Home / Àṣà Oòduà / ORÍLÈ ÈDÈ MI

ORÍLÈ ÈDÈ MI

ORÍLÈ ÈDÈ MI

Nàìjíríà ìlú mi pàtàkì
Ìlú t’ókún fún ogbón
Pèlú òpòlopò àwon òjògbón
Ilé ogbón
Tí a ti n hun àgbòn ìwà ìbàjé
S’ogúndogójì di ààyò àwon òdó
Òsèlú di ohun wón k’èyìn sí
Egbé òsèlú di ìkan kò gbé’kan
“Birds of a feather”
Bí àwon olóyìnbó se máa n so
Iró n pa’ró fún iró
Ìtànje lásán làsàn
Ní àti ojó tí a ti gba òmìnira
Omi ìnira ni àwon olórí wa n fún wa mu
Màá se eléyìí
Màá se tòún
Sí bè…
Ìsé òun òsì
Kò tán ní àwùjo wa
Kílódé, kí ló se wá
PDP se ìjoba ó ya mó won lówó
APC ò sun wòn
Tani yóò gbà wá ní owó àwon jegúdú jerá wònyí
Tí wón n pe ra won ní olórí wa
Àkókò náà tó wàyìí
Ó tó géé oní bàtá kan kìí dá Orin
Èyin òdó, àsìkò náà ti tó
Láti GBA ìjoba
Ní owó àwon alágbára a tó kú má kùú a mònà òrun má lo
2019! E jé kí á dìbò fún
Òdó langba kí ìtèsíwájú leè
Dé bá gbogbo wa.

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo