Ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà Yoruba to tí ta gbòǹgbò káàkiri àgbáyé ni Alhaji Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogogo ọmọ kúlódò jẹ́. Nítorí náà kò ya ni lẹ́nu nígbà tí ètò lónírúurú gbode kan fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún tó ṣe. Lára àwọn ètò náà ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin ikọ̀ ogogo, (Ogogo All stars) àti ikọ̀ to jẹ́ ti olórí Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko, ( Obasa All stars). àá áà àà éé èè ẹ́ ẹ́ẹ̀ù ùẹ̀ ùẹ̀ ẹ̀ẹ̀ íí ìì óó òò ọ́ọ́ ọ̀ọ̀ ọọ úú ùù àà Nígbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà yóó fi parí ní pápá ìṣeré Agége, góòlù méjì làwọn ikọ̀ Obasa All Stars fi gbẹyẹ mọ́ ikọ̀ Ogogo lọ́wọ́ o.
Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbé Soworẹ lásìkò tí ó fi ń léwájú ìwọ́de “Revolution now”. Ìtúsílẹ̀ rẹ̀ ń wáyé lẹ́yìn tí ó ti lo ọjọ́ márùndíláàdóje ní hàhámọ́ àwọn DSS.
Onírúurú ìdájọ́ ló ti wáyé èyí tí àwọn Ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní kí wọ́n fi sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ DSS kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú onírúurú àwáwí. Àmọ́sá ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki iléeṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ó tú u sílẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún
Ìrètí wà pé yóó tún farahàn ní Ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Ẹtì nítẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 2019 ni àwọn agbófinró DSS lọ gbé Ọmọyẹle Soworẹ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣagbátẹrù àwọn ìwọ́de “Revolution now” eléyìí tó ń bèèrè fún ìṣèjọba rere lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní kẹfa oṣù Kọkànlá ni ọ̀gbẹ́ni Soworẹ kọ́kọ́ mú ìlérí béèli àkọ́kọ́ tí Ilé ẹjọ́ fún ṣẹ ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kò túu sílẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìfisáhámọ́ Sowore ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ ilẹ̀ òkèèrè àti ti Nàìjíríà pẹ̀lú láti kígbe sí Ìjọba àpapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún òfin ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kùnà láti tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ ìṣaájú láti ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ DSS tún dá Olawale Bakare náà sílẹ̀.
Àwọn méjéèjì yí ni Ìjọba àpapọ̀ ń fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kàn.
Obi ni n biku Obi ni n bi arun Obi ni n bi ofo Obi ni n bi gbogbo ibi. Olodumare abawa fi obi biku, bi arun, bi ofo, bi gbogbo ajogun ibi aye wa o. Ase edumare.
Cola nut helps to avoid death Cola nut helps to avoid disease Cola nut helps to avoid lost Cola nut helps to avoid all kind of problems. I pray Olodumare will use Cola to take away all the problems in our life. Ase edumare.
Èmi àti àwọn èèyàn Ọyọ yóò máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun.. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé inú dídùn ń ni yoòbá níí mórííya àti pé yiinínú,níí jẹ́ kẹ́ni fẹ́ ṣèmìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti fí èrò ọkàn rẹ̀ hàn pé, ìjọba òun àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóò tẹ̀síwájú láti máa fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà fún ìdàgbàsókè àwùjọ.
Makinde sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó péjú síbi ayẹyẹ ìsíde ìdíje ìbọn yínyìn láàrin àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ológun (NASAC), èyí tó wáyé ní iléeṣẹ́ ọ̀wọ́ kejì ológun ti Adekunle Fajuyi tó wà ní àdúgbò Òdogbó Ọjọọ, nílùú Ibadan.
Makinde ní ìnú òun dún fún àyẹsí tí wọ́n fún òun, àti pe, òun àti àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó túbọ̀ máa fọwọ́sowọ́pọọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ológun. ” Mo gbàdúrà pé gbogbo àwọn akópa nínú ètò náà ni yóó se àṣeyọrí, tí ètò náà yóó sì jẹ́ mánigbàgbé fún wọn ní ìpínlẹ̀ Oyo.”
Ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kò sọ pàtó ẹni tó jáwé olúborí láàrín Makinde àtiAdelabu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kángun kàngùn Kángun, bọ́ pẹ́,bọ́ yá, ó gbọ́dọ̀ kángun síbìkan, bẹ́ẹ̀ ló súmọ́ kí ọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, látàrí àgbéjáde ilé ẹjọ́. Tí Ilé ẹjọ́ kan kò bá wá fìdíi ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní pàtó nípa ìdájọ́ ohun ta gbé lọ síwájú rẹ̀, kínni ó yẹ ká ṣe? Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nílùú Ibadan tó ń gbẹ́jọ́ láàrin Gómìnà Seyi Makinde àti akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ du ipò Gómìnà, Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ́ òsèlú APC.
Kókó ọ̀rọ̀ tó jáde nípa ìdájọ́ tí adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta ilé ẹjọ́ náà fi lélẹ̀ ni pé àwọn fọwọ́ rọ́ ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ ìdìbò sẹgbẹ kan ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ kò sọ ojú abẹ níkòó bóyá Makinde tàbí Adelabu ló jáwé olúborí.
Ní ti Adelabu, ń se ló ń sọ pé kí Ilé ẹjọ́ wọ́gilé èsì ìdìbò tó gbé Makinde wọle kó sì kéde òun gẹ́gẹ́ bí Gómìnà. Àmọ́ báyìí tí Ilé ẹjọ́ náà kò ì sọ bóyá òun ni Gómìnà tàbí Makinde ni, ohun tó kàn fáwọn méjéèjì ni kí wọ́n gba Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ láti yànànà ọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Lójú òpó Twitter, ohun tí Ilé ẹjọ́ yí sọ tí ń mú ìríwísí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá táwọn èèyàn sì ń gbìyànjú láti tú ohun tí Ilé ẹjọ́ sọ bó ṣe yé wọn mọ. Kódà àwọn kan ti ń fi ohùn ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari àti ẹgbẹ́ APC pé kí wọ́n má ṣe dásí ọ̀rọ̀ náà tí wọn ò bá fẹ́ kan àbùkù
Bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe wà báyìí,ohun tó dájú ni pé ilé ẹjọ́ kò sọ ẹni tó jáwé olúborí bẹ́ẹ̀ sì ni kó kéde pé wọn yóó tún ìbò mìíràn dì Bí a bá ní ká tẹ̀lé ọ̀rọ̀ táwọn agbẹjọ́rò olùdíje méjéèjì yí sọ báyìí, ààyè ṣì wà nílẹ̀ fáwọn láti kọrí sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ láti sọ bí iṣu ṣe kú, bọ́bẹ ṣì ṣe pá. Kókó kan ṣoṣo tó hànde lórí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ yìí ni pé Ilé ẹjọ́ gíga ló máa yanjúẹ̀.
Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní ,bí Ọlọ́run bá rí ọ, jéèyàn náà ó sẹ̀ríìrẹ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí,bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti fọwọ́ gbáyà pé òun yóó sa gbogbo ipá òun láti rí i dájú pé àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba òun.
Gómìnà Makinde fi ọwọ́ idaniloju ọ̀hún sọ̀yà nínú ọ̀rọ̀ apilẹkọ rẹ̀ níbi ìpàdé ìta gbangba lórí ètò ìṣúná ọdún 2020 tó wáyé ní ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Ọ̀yọ́, ní gbọ̀ngàn Atiba, nílù Ọ̀yọ́. Makinde ní Ìjọba òun ti setán láti se àtúntò ìlànà ìṣèjọba, kí òun sì se àgbékalẹ̀ ìpínlẹ̀ tó lóòrìn fún ìṣèjọba alájùnmọ̀ṣe tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóó sí sílẹ̀ fáwọn aráàlú.
Gómìnà Makinde. ẹni tí olórí òṣìṣẹ́ lọ́ọ́fìsì Gómìnà, Olóyè Bisi Ilaka ṣojú fún ṣàlàyé pé àfojúsùn ìpàdé ìta gbangba náà ni láti jẹ́ kí ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹnu nínú ìṣèjọba, kí Ìjọba sì le ní ìmọ̀ nípa ohun tí Ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ń pòùngbẹ rẹ̀ nígbaradì fún àmúsẹ ètò ìṣúná ọdún 2020.
Makinde ní àfojúsùn ìjọba òun ni láti mú ètò ìlànà ìṣèjọba onídàgbàsókè tí yóó gbà tó ogún ọdún, èyí tí yóó wà fún Ìjọba mi àti àwọn ìṣèjọba tí yóó tẹ̀lé mi.
“Bákan náà ni mo tún fẹ́ mú àgbéga bá okùn àjọṣepọ̀ láàrin ìjọba àti àwọn aráàlú nípa bíbèèrè èrò wọn lórí ìṣúná ọdún tó ń bọ̀.” “Yàtọ̀ sí pé màá rí i dájú pé a lo àwọn ohun àlùmọ́ọ́ní fáwọn iṣẹ́ àkànṣe tó nítumọ̀ sí aráàlú, àti àmúsẹ àwọn ètò tí yóó mú ìlọsíwájú bá ètò ìlera àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ yìí, máa tún tiraka láti rí i dájú pé aráàlú ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba mi.”
Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ i ìkínni káàbọ̀ rẹ̀ Kọmísánà fétò ìṣúná àti ààtò ọ̀rọ̀ ajé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Amòfin Adeniyi Farintọ mẹ́nubàá pé ìpàdé ìta gbangba náà se kókó nítorí ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Ìjọba kan àti àwọn aráàlú yóó jókòó papọ̀ láti jíròrò lórí ètò ìṣúná kan kí wọ́n tó gbé e kalẹ̀. Farintọ ní Ìjọba Seyi Makinde yóó tẹ̀síwájú láti máa kó àkóyawọ́ láì fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú, nínú àwọn ìlànà tó bá gbékalẹ̀, tí yóó sì máa gba èrò aráàlú láàyè.
Nígbà tó ń dáhùn sí àwọn ìbéèrè aráàlú lásìkò ìjíròrò náà, Makinde sèlérí pé òun yóó pèsè ojú ọ̀nà tó já gaara sí ẹkùn ìdìbò náà. Ó ní òun yóó tún se àgbékalẹ̀ ẹ̀ka àjọ tó ń se àtúnṣe ojú ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSTROMA sí ẹkùn náà pẹ̀lú bí àfikún se bá owó t’íjọba ìpínlẹ̀ náà ń gbà láti ọ̀dọ̀ ọ Ìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú bílíọ̀nù márùn náírà.
Lórí ọ̀rọ̀ LAUTECH, Makinde ní wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí bí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó se gba àkóso Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ladoke Akintola tó wà nílùú Ogbomọsọ pátápáta.
Ṣé ko ko ko là á ránfá adití,àti pé ó ń bọ̀, ó ń bọ̀,ojú ni wọ́n ń mú tó o. Èyí ló mú kí Ààrẹ orílẹ̀ yìí Muhammadu Buhari má a ké tan tan tan saájú ìdìbò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Kogi àti Bayelsa lọ́jọ́ Sátidé ọ̀sẹ̀ yìí, fìkìlọ̀ léde fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò láti dènà àwọn jàǹdùkú tó bá fẹ́ jí àpótí ìdìbò gbé.
Buhari nínú àtẹ̀jáde tó fi síta láti ọwọ́ olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Garba Shehu, sọ fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, kí wọ́n rí i pé àwọn èèyàn dìbò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ ọ wọn. Ààrẹ Buhari sọ pé gbogbo ọ̀nà ni káwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ìdìbò fi dènà ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jí àpótí ìdìbò gbé.
Ààrẹ ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dúnkokò mọ́ ẹnikẹ́ni tàbí dènà ẹnikẹ́ni láti dìbò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ wọn. Bákan náà ni Ààrẹ Buhari képe àwọn olùdìbò ní ìpínlẹ̀ Bayelsa àti Kogi láti ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ níbùdó ìdìbò, kí wọ́n sì dìbò lálàáfíà gẹ́gẹ́ bí òfin ti làá kalẹ̀. Buhari sọ pé, ”níbi gbogbo tí ètò ìdìbò ti ń wáyé ni olùdíje kan yóó ti jáwé olúborí, tí òmíràn yóó sì fìdí rẹmi, ti Bayelsa àti Kogi kogi náà kò gbọdọ̀ yàtọ̀.”
Ààrẹ Buhari rọ àwọn olùdíje láti gba èsì ìdìbò tí yóó wáyé bí ó bá ṣe rí láì dá rògbòdìyàn sílẹ̀. Ààrẹ ní olùdíje tí ètò ìdìbò kò bá tẹ́ lọ́rùn láṣẹ láti gba ilé ẹjọ́ lọ dípò kí ó dá wàhálà sílẹ̀.
Kùkùlajà ètò ààbò,Gani Adams ní OPC àtàwọn míì ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò nílẹ̀ Oòduà (Yorùbá) Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé Oòduà (Yorùbá) bọ̀ wọ́n ní ọmọ onílùú kìí fẹ́ ò tú. Gbogbo áwọn àgbààgbà nínú ẹgbẹ́ ajìjàgbara ẹgbẹ́ OPC àti Àgbẹ́kọ̀yà àtàwọn irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ní àwọn ti gbaradì báyìí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Ààrẹ Gani Adams tó jẹ́ olórí OPC tilẹ̀ sọ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Oòduà (Yorùbá) làwọn ń retí láti sètò ìgbésẹ̀ ètò ààbò tó mọ́yán lórí tí àwọn pe orúkọ rẹ́ ní Operation Àmọ̀tẹ́kùn”.
Àkànṣe ètò ààbò yìí ni ìròyìn sọ pé ó jẹ́ àjọmọ̀ àti àjọrò gbogbo Gómìnà ní ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) lójúnà àti pèsè ètò ààbò tó péye fún mùtú mùwà káàkiri ilẹ̀ náà. Èrò àwọn Gómìnà yìí ló dá lórí bí ìjínigbé àti ìpànìyàn ṣe wọ́pọ̀ ní ẹkùn náà tí wọ́n sì gbèrò láti mú òpin débá ìwà burúkú bẹ́ẹ̀. Ṣé ní nǹkan bíi oṣù Kẹwàá ọdún yìí ni wọ́n gbèrò láti kó ìmọ̀ náà jáde bí ọmọ tuntun. Ààrẹ Gani Adams ṣàlàyé síwájú síi pé ”Operation Àmọ̀tẹ́kùn” wà láti ṣèkúnwọ́ fún àwọn àjọ ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Àwọn àgbáríjọ ẹgbẹ́ tí wọ́n yóó lò ni ẹgbẹ́ OPC, Àgbẹ́kọ̀yà, Fijilanté, àtàwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) àti ọlọ́de káàkiri ìletò.
Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí ti wá gbà láti ṣiṣẹ́ papọ̀ bẹ́ẹ̀ wọ́n ti kọ̀wé sí gbogbo Gómìnà, àtàwọn olórí elétò ààbò káàkiri ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá). Àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí ni wọ́n tí ṣe púpọ̀ ìpàdé ní ìlú Eko tí wọn yóó sì tún ṣe ní ìlú Ibadan , tíí ṣe Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí.
Ó ní kò sí bí ọ̀rọ̀ ètò ààbò yóó ṣe ṣeéṣe láì sí àwọn irinṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ tó dájú. Ó ní àwọn ọkọ̀ ti wà, àwọn ọlọ́pàá sì ti wà nílẹ̀ àṣẹ àwọn Ọlọ́pàá ni wọ́n ń dúró dè.
Ó ní nígbà tí kò ti sí Ìpínlẹ̀ kan lórílẹ̀-èdè yìí tó ní àṣẹ láti ra ohun ìjà olóró, tó sì jẹ́ pé àwọn Gómìnà ti setán láti ṣe gbogbo ohun àmúyẹ láti ra ohun tó bá kù.
Ó wá ṣàlàyé pé, kò tíì sí àrídájú pé bóyá ọkọ̀ òfurufú kékeré yóó wà lára ohun tí wọ́n fẹ́ lò ṣùgbọ́n pé Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ekiti ti ra ọkọ̀ bíi ogún sílẹ̀ fún ètò náà.
Alukoro fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ogun, Kunle Somorin ṣàlàyé pé Gómìnà kọ̀ọ̀kan ni yóó kó ọkọ̀ ọgọ́rùn sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ètò náà.
Ọrẹ Fálọmọ , irúnmọlẹ̀ ìṣègùn tó dáńtọ́ nínú ìràn Oòduà(Yorùbá) wọ káàlẹ̀ lọ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Hùn! Báakú làá dère,èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Ni báyìí, gbogbo ọmọ Oòduà(Yorùbá) ló tí ń sun rárà ọlọ́kan ọ̀ jọ̀kan lẹ́yìn in Dókítà Ọrẹ Fálọmọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí oníṣègùn M.K.O Abíọ́lá nígbà ayé rẹ̀. Adarí ẹgbẹ́ Afenifẹre Ayo Adebanjọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sàlàyé pé iṣẹ́ ribiribi ní Ore Fálọmọ ti ṣe nínú ìràn Oòduà(Yorùbá), àti pé ìran Oòduà(Yorùbá) ti sọ ògo ńlá kan nù. Adebanjọ fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ìran Oòduà(Yorùbá) jí gírí láti gbé ògo ìran rẹ̀ ga bi Ọrẹ Fálọmọ ṣe se nígbà ayé rẹ̀, papàájùlọ gẹ́gẹ́ bíi Dókítà Abiola, ó dúro ti Abíọlá gidigidi lásìkò ìsòro, kò kẹ̀yìn sí bí àwọn tó kù ṣe ṣe nígbà náà.
Ó fí kún-un pé àwòkọ́se rere ni Fálọmọ jẹ́ nígbà tó fi jẹ́ Ààrẹ àwọn ẹgbẹ́ Dókítà ní Nàìjíríà, àmúyangàn ni àsìkò rẹ̀ jẹ́ fún ìdarí rẹ̀ àti ipò tí ọ̀rọ̀ ìlera wà lásìkò náà. Afẹnifẹre ní Dókítà Fálọmọ kìí ṣe ẹni tí ìràn Oòduà(Yorùbá) gbọdọ̀ gbàgbé ní kíákíá.
,A bí Dókítà Oluwatamilore Fálọmọ lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún 1942 nílùú Minna tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Niger báyìí. Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ lọ ilé ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ní Baptist Primary School, ìjàyè láàrin ọdún 1948 si ọdún 1955. Ilé ìwé girama Methodist Boys High School ní ìpínlẹ̀ Eko ni Fálọmọ lọ láàrin ọdún 1956 sí ọdún 1960. Fálọmọ tẹ̀síwájú ẹkọ rẹ̀ nílé ìwé St. Andrew College, nílùú Dublin lórílẹ̀-èdè Ireland láàrin ọdún 1961 sí 1962 kí ó tó lọ kàwé ní “Royal College of Surgeons ní Ireland” láti ọdún 1962 sí 1968.
Ó tún padà sí ilé ìwé “Royal College of Surgeons” nílùú Dublin lọ́dún 1978. Ọ̀gbẹ́ni Fálọmọ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Folashade Ṣorunkẹ lọ́dún 1968.
Dókítà Fálọmọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé ìwòsàn Park Hospital, Davyhulme ní Manchester lọ́dún 1969 sí 1970.
Ó tún ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ètò ìlera ìpínlẹ Eko lágbègbè Surulrere lọ́dún 1971 sí 1972, kó tó lọ ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Ìjọba ní Ikeja lọ́dún 1972 sí ọdún 1973. Dókítà Fálọmọ di olùdarí ilé ìwòsàn Oníkòyí Clinic ní Yaba lọ́dún-un 1974 sí 1979 Fálọmọ jẹ́ Alága ẹgbẹ́ àwọn Dókítà lọ́dún 1971 sí 1974, ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Dókítà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì àti orílẹ̀-èdè Ireland.
Ó ṣiṣẹ́ ní Ilé ìwòsàn Maryland Specialist Hospital fún ọ̀pọ̀ ọdún. Dókítà Fálọmọ jẹ́ Dókítà fún olùdíje fún ipò Ààrẹ lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òsèlú SDP nínú ìbò Ààrẹ ọdún 1993 ní Nàìjíríà, MKO Abiola.