Home / Àṣà Oòduà / Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba – Seyi Makinde

Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba – Seyi Makinde

Màá ṣa ipá láti mú káwọn aráàlú nígbẹkẹ̀lé nínú ìjọba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní ,bí Ọlọ́run bá rí ọ, jéèyàn náà ó sẹ̀ríìrẹ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí,bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti fọwọ́ gbáyà pé òun yóó sa gbogbo ipá òun láti rí i dájú pé àwọn èèyàn rere ìpínlẹ̀ náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba òun.


Gómìnà Makinde fi ọwọ́ idaniloju ọ̀hún sọ̀yà nínú ọ̀rọ̀ apilẹkọ rẹ̀ níbi ìpàdé ìta gbangba lórí ètò ìṣúná ọdún 2020 tó wáyé ní ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Ọ̀yọ́, ní gbọ̀ngàn Atiba, nílù Ọ̀yọ́.
Makinde ní Ìjọba òun ti setán láti se àtúntò ìlànà ìṣèjọba, kí òun sì se àgbékalẹ̀ ìpínlẹ̀ tó lóòrìn fún ìṣèjọba alájùnmọ̀ṣe tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóó sí sílẹ̀ fáwọn aráàlú.

Gómìnà Makinde. ẹni tí olórí òṣìṣẹ́ lọ́ọ́fìsì Gómìnà, Olóyè Bisi Ilaka ṣojú fún ṣàlàyé pé àfojúsùn ìpàdé ìta gbangba náà ni láti jẹ́ kí ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹnu nínú ìṣèjọba, kí Ìjọba sì le ní ìmọ̀ nípa ohun tí Ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ń pòùngbẹ rẹ̀ nígbaradì fún àmúsẹ ètò ìṣúná ọdún 2020.

Makinde ní àfojúsùn ìjọba òun ni láti mú ètò ìlànà ìṣèjọba onídàgbàsókè tí yóó gbà tó ogún ọdún, èyí tí yóó wà fún Ìjọba mi àti àwọn ìṣèjọba tí yóó tẹ̀lé mi.

“Bákan náà ni mo tún fẹ́ mú àgbéga bá okùn àjọṣepọ̀ láàrin ìjọba àti àwọn aráàlú nípa bíbèèrè èrò wọn lórí ìṣúná ọdún tó ń bọ̀.”
“Yàtọ̀ sí pé màá rí i dájú pé a lo àwọn ohun àlùmọ́ọ́ní fáwọn iṣẹ́ àkànṣe tó nítumọ̀ sí aráàlú, àti àmúsẹ àwọn ètò tí yóó mú ìlọsíwájú bá ètò ìlera àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ yìí, máa tún tiraka láti rí i dájú pé aráàlú ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ìjọba mi.”

Ṣaájú nínú ọ̀rọ̀ i ìkínni káàbọ̀ rẹ̀ Kọmísánà fétò ìṣúná àti ààtò ọ̀rọ̀ ajé nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Amòfin Adeniyi Farintọ mẹ́nubàá pé ìpàdé ìta gbangba náà se kókó nítorí ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Ìjọba kan àti àwọn aráàlú yóó jókòó papọ̀ láti jíròrò lórí ètò ìṣúná kan kí wọ́n tó gbé e kalẹ̀.
Farintọ ní Ìjọba Seyi Makinde yóó tẹ̀síwájú láti máa kó àkóyawọ́ láì fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú, nínú àwọn ìlànà tó bá gbékalẹ̀, tí yóó sì máa gba èrò aráàlú láàyè.

Nígbà tó ń dáhùn sí àwọn ìbéèrè aráàlú lásìkò ìjíròrò náà, Makinde sèlérí pé òun yóó pèsè ojú ọ̀nà tó já gaara sí ẹkùn ìdìbò náà.
Ó ní òun yóó tún se àgbékalẹ̀ ẹ̀ka àjọ tó ń se àtúnṣe ojú ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYSTROMA sí ẹkùn náà pẹ̀lú bí àfikún se bá owó t’íjọba ìpínlẹ̀ náà ń gbà láti ọ̀dọ̀ ọ Ìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú bílíọ̀nù márùn náírà.

Lórí ọ̀rọ̀ LAUTECH, Makinde ní wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí bí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó se gba àkóso Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ladoke Akintola tó wà nílùú Ogbomọsọ pátápáta.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...