Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • E wá wo isé tí Àlùbósà.

    1. _Sebí ohun tó bá jọnilójú, ni Yorùbá n sọ wí pé ó yanilẹ́nu. *Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì kan ní ìlú CHINA ti jẹ́ kó yé wa wí pé ìwádìí tuntun tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ÀLÙBỌ́SÀ (kò báà ṣe pupa tàbí funfun) le wo ÌBÀ, Ẹ̀FỌ̀RÌ ÀBAADÌ, àti gbogbo KÒKÒRÒ ara pátá, kò báà jẹ́ kòkòrò inú eyín, inú ẹ̀jẹ̀, inú ojú tàbí èyí tó wà nínú etí. Kódà, ó n ṣiṣẹ́ fún ÒTÚTÙ àti àwọn àìsàn mìí tí n bá ẹ̀dá jà nínú ara.*_

    _*Láti lo àlùbọ́sà fún ìwòsàn ara, ohun tí ẹ ó ṣe ni wí pé:-*_

    _*(1)* Ẹ ó la àlùbọ́sà náà sí méjì tàbí iye tí ẹ bá le làá sí._

    _*(2)* Ẹ́ wàá ṣí ojú àlùbọ́sà náà dé àtẹ́lẹsẹ̀ yín tí ẹ bá ti fẹ́ sùn lálẹ́. Lẹ́yìn èyí ni._

    _*(3)* Ẹ ó wọ àwọ̀tẹ́lẹ̀-ẹṣẹ̀ (sock) leé kó le mu dúró. Báyìí ni yóò wà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì._

    _*Kí ilẹ̀ tó mọ́, gbogbo kòkòrò àti àìsàn tó wà láàgò ara pátá ni àlùbọ́sà náà yóò ti fà jáde síta tí àlááfíà yóò sì dé bá àgò ara yín*. Ẹ wá le padà ṣe èyí níye ìgbà tó bá wù yín, kò sí ewu níbẹ̀ rárá._

    _*Babaláwo s’óògùn àìkú fọ́mọdé, o ní kò ṣiṣẹ́. Ẹ dákun, ṣe ọmọ náà ti kú ná ni?* Àwàdà lásán ni mo sebí nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ àbájáde ìwádìí náà, *ṣùgbọ́n nígbà tí mo padà finmú fínlẹ̀ dáada, mo ri dájú wí pé òtító ni*. Àwọn Yorùbá sìbọ̀, *wọ́n ní danwò ló bí ìyá òkèrè.*_

    _Àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dán orísìí ògùn yìí wò ni àwọn ìlú òkè òkun, *gbogbo wọn náà ló sì n jẹ́ri sí i wí pé a-jẹ́-bí-idán ni ògùn náà.*_

    _Orísìí àìsàn wo ló n ba yín jà láàgò ara, *ṣé ÀWỌ́KÁ ni tàbí ARA RÍRO? Kò bá jẹ́ kòkòrò ara tàbí AKỌ IBÀ? Ẹ̀yin ẹ sáà ti fi àlùbọ́sà sí àtẹ́lẹsẹ̀ yín sùn*, ó dájú wí pé ẹ ó padà fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọba ni. *Àlùbọ́sà ní agbára láti gbé kòkòrò tàbí àrùn míì sínú, ìdí nìyìí tí wọ́n fi n gbà wá nímọ̀ràn láti yẹra fún jíjẹ ààbọ̀ àlùbọ́sà tí wọ́n ti gé tó ti di ọjọ́ kejì.*_

  • Eniyan koni rajo kofi orire kale sile ibiti aba koriwa mase pada leyinwa oo

    Ori mi Apere
    isedami Ajifobi kan
    Amuni wale aye magbagbe Eni
    Orimi gbemi bose gbe omo alara tofidade owo
    isedami gbemi bosegbe omo ajero tofi tepaleke
    orimi gbemi bose gbe
    omo orangun ila tofidi eni apesin pitipiti
    mogbani Adurafun wape
    oriwa Asegbe funwa o
    ifa ni
    sakasala legbe leke
    Adifafun ori omo Amuwa gun boroboro
    ebo lawoni komuse osi gbebobe orubo
    eropo eroofa eyin omon
    pe orilamuwa gun awo.

    bi ori eni basunwan
    wan ani ori enida
    isedami jeki orimisunwan korimidi ori ola ati olaa ki mase se eru egbe mi oo
    # Babalawo Ifatola Sangodare Awosipe

  • Eniyan koni rajo kofi orire kale sile ibiti aba koriwa mase pada leyinwa oo

    Ori mi Apere
    isedami Ajifobi kan
    Amuni wale aye magbagbe Eni
    Orimi gbemi bose gbe omo alara tofidade owo
    isedami gbemi bosegbe omo ajero tofi tepaleke
    orimi gbemi bose gbe
    omo orangun ila tofidi eni apesin pitipiti
    mogbani Adurafun wape
    oriwa Asegbe funwa o
    ifa ni
    sakasala legbe leke
    Adifafun ori omo Amuwa gun boroboro
    ebo lawoni komuse osi gbebobe orubo
    eropo eroofa eyin omon
    pe orilamuwa gun awo.

    bi ori eni basunwan
    wan ani ori enida
    isedami jeki orimisunwan korimidi ori ola ati olaa ki mase se eru egbe mi oo
    # Babalawo Ifatola Sangodare Awosipe

    Eniyan koni rajo kofi orire kale_ooduarere.com_

  • Odún ifá àgbáyé !

    Odù ifá tí ó sòkalè ni *ìretè-ìká* ifá pé ire aya (couples blessing) ifá ní a ó se òpòlopò Odún láyé.

    Ifá ní kí á rúbo lópòlopò wípé Odún yìí yóò sàn wá fún ajé, aya, Omo, ogbó ató àti àìkú tí se baálè orò .

    Àsèyí se àmòdún ooo

  • Ooni ti ile-ife ní ìdí òpe àgùnká .

    Ayeye Odún ifá àgbáyé eléyìí tí ó wáyé ní òkè-ìtase ní ilú ilé-ifè.   Ooni rèé ní ìdí òpe àgùnká ní ibi tí mùtúmùwà ti ń se àdúrà sí ìsèdá won, kódà oba náà kò jáfara.
  • Ìwúre Òṣù Tuntun

    Bí ÒṢÙ bá yọ loke terutọmọ niiri,
    omi ajipon kiiru, ninu ÒṢÙ kẹfa yi aye gbogbo wa yio toro minimini, bi Ọgẹdẹ ba pọn ará aa dẹẹ, ara oni ni emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, àtijẹ atimu koni jẹ inira fún wa, tọtuntosi ni ẹiyele fi nko ire wale, ire owo ire ọmọ ire ile tuntun ire ọkọ àti aya tuntun yio wọle wa wa, nibikibi ni origun mẹẹrẹrin ayé, tí àwọn ooloore wà wá, Ọlọrun tio ṣé àwáàrí Aake nínú omi, nínú ÒṢÙ yi ooloore wà yóó wá wá rí, yio sí fí ire wá l’ewa lọwọ,
    Kọkọrọ Ayọ rẹ yio tẹ ẹ lọwọ,
    Bí akeregbe bá fọ ŃṢE nii dẹ̀hìn lẹ́hìn odo, ori buruku yio dẹ̀hìn lẹ́hìn gbogbo wa, Ipọnju, aṣeeri, amubọ, ijakulẹ, afaa’to, idiwọ, idena, àti ẹti yio dẹ̀hìn lẹ́hìn wa, ìbànújé, ẹkun ajọsun, ẹkun adasun, ẹkun asunrin koni jẹ ti’wa, àṣẹ oooo,
    ogun idile, ogun ile binukonu, ogun ibi ìṣẹ, ogun arinako nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣẹ wọn wọlẹ pátápátá nínú aye wá àmìn, Ohùn Ayọ tí yio mú inú wá dùn tí ọpọlọpọ ènìyàn yio bawa se ajọyọ rẹ nínú ÒṢÙ yi Ọlọrun yio ṣé fún wa nínú ÒṢÙ tuntun yìí iṣẹlẹ iyanu Ayọ tí kó i ti ṣẹlẹ rí nínú ẹbí wá yio ṣẹlẹ nínú aye emi àti Ìwọ oluka àtèjìṣẹ mi yi, tí àwọn ènìyàn yio fí máa fí orúkọ tuntun pé wa. Àmìn.
    Ọmọ wá kóni Kú,
    Ọkọ wá kóni Kú,
    Aya wá kóni Kú,
    Ojú kiipọn iṣin ki o má LÀ afaila ọjọ bí ọjọ bá tí LÀ gbogbo wà ni láti LÀ, ṣẹkẹrẹ kì bá wọn rode ìbànújé, ìbànújé oni kàn wá lagbara elédùà, àṣẹ gun. Ao ṣégun oṣo ilé àti ajẹ ode, ao rẹyín odi.
    Otiri bẹẹ, nítorí bẹẹ lewurẹ nke kó’ni yí padà. NÍ opin ÒṢÙ kẹfa yi ao Jọ gbé igba Ọpẹ Àmín oooo ooo

    A ku ÒṢÙ tuntun o, yio tuwa Lára ooo koni le koko mo wa Àmín àṣẹ oooo.

  • Oríkì Fún Ọba

    Kábíyèsí Ọba Olúwayé,
    Ọ̀dúndún aṣọ̀’de d’ẹ̀rọ̀,
    Ọba adé-kí-ilé-r’ójú
    Ọba ade-kí-ọ̀nà-rọrùn,
    Arówólò bí òyìnbó,
    Ó fi’lé wu ni,
    O f’ọ̀nà wu ni.
    Ògbìgbà tí n gba ará àdúgbò
    Ọba at’áyé-rọ bí agogo.

    Olubadan

  • Ifá náà ki bayi wípé: Eye òkun, Eye òsà

    Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku amojuba osù tuntun òkudù yi, osù tuntun náà yio sanwa sowo, somo ati si aiku baale orò o, mosi tun fi asiko yi ki gbogbo awa onisese lagbaye wípé aku odun bara mi agbonmiregun kaakiri agbaye, bi a se se odun yi ao tun se ti eemin ninu ire gbogbo o àse.
    E jeki a fi odu ifá mimo osa alawure yi se iwure ti ibere osù tuntun yi.
    Ifá náà ki bayi wípé:
    Liili eye òkun
    Liili eye òsà
    A difa fun Òrúnmìlà baba felo joye atáyése won ni ko karaale ebo ni ki o wa se, obi meji…. Òrúnmìlà kabomora o rubo won se sise ifá fun, lati igba náà ni Òrúnmìlà ti bere sini ntayese, baba wa njo o nyo o nyin awo àwon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare, oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje kee pe kee jina ifá wa bami ni jèbútú ire nje jèbútú ire ni a nbawo lese obarisa.
    Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wípé Òrúnmìlà yio tun aye wa se o, gbogbo isoro ti a nkoju yio di nkan igbagbe ninu osù tuntun yi, ao rije ao rimun losu yi, gbogbo oke isoro wa yio di petele lase Eledumare aaaase.
    ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

    English Version

    Continue after the page break