Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • A kú òsè jàkúta.

    Sango oooo
    Olukoso ayanran ina
    Ina loju, ina lenu
    Sangiri, lagiri
    Olagiripapa figba edun bo
    Eefin ina la n da laye
    Ina nbe lodo oko mi lorun
    Abaabe ooooooooo
    Abaabe laba Se fun SANGO
    Emi Se SANGO labaabe
    Agbenajo, Agbenayan
    Agbenarababa kari bi Olodumare
    Imumuna eledumare itara ni gbaye
    Alaramoka ti I deru bojo
    Aduloju, Adulenu
    Ajo lagbon isale woiwoi
    Kee wolu baale ndifa
    SANGO koti wolu
    Timo fi n gbo bata leyin Odi
    SANGO gbemi, ewe gbemi
    Awalawulu,ogbojo aseru bote
    Akinkanju Akoni ti yona lenu

    Kaabiyesi Olukoso!
    Kaabiyesi Olukoso!!
    Kaabiyesi Olukoso!!!

    A kú òsè jàkúta

  • Àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó tokotayà yí ti won pàdé nígbà tí won ń sin orílè èdè won lówó ní odún mérin séyìn.

    Arábìnrin Nìjíríà kan tí a mò sí Rosemary nípa eni tí yó sèsè di oko rè Láìpé odún màrún-ùn séyìn, nígbà tí won ń sin orílè èdè won lówó ní Kaduna ti pín àwòrán kí ó tó di ojó ìgbeyàwó won.

    Wón dìjo wo aso ìsìnlú won pèlú bàtà aláwò kan náà.

  • Fúlàní darandaran pa àwon èèyàn ní ojú ònà Makarda ní òpópónà Makarda.

    Óní òun so gbangba gbàngbà ni Láì bèrù enikéni :báyìí ni Adamu Donald Dekwagh, wípé enikéni kò gbodò sùn nígbà tí igbákejì Ààre orílè èdè lo kí won ní Benue ní ànà yí tí àwon wòólì méjì àti darandaran pa. Óní àwon Fúlàní darandaran ti di p’àyàn p’àyàn.

  • Òdókùnrin kan ní àwon olópàá yin ìbon pa nígbà tí won fé parí ìjà ní Ajegunle.

    Òdókùnrin kan tí a gbó wípé ó jé omo ogún odún ni a gbó wípé won fi èsùn kàn àwon olópàá Látàrí ìbon tí won yìn pa Òdókùnrin yí, nígbà tí won ń parí ìjà lówó láàrin àwon ìkò ológun méjì ní agbègbè Ajegunle ní ìpínlè Èkó. Kí olórun te sí aféfé rere.

  • Paul Okoye níbi tí ó ti ń bá àwon ìbejì rè Nadia àti Nathan seré .

    Paul Okoye tí a mò sí Rude boy ni ó pín àwòrán tí ó rewà yí nígbà tí ó ń lo àsìkò pàtàkì pèlú àwon ìbejì rè Nadia àti Nathan seré èyí tí ó pín sí orí èro ayélujára (instagram)..

  • Kemi Olunloyo so báyìí wípé! Àwòkóse burúkú gbáà ni Linda Ikeji àtiwípé òun ni àwòkóse there.

    Kemi Olunloyo so báyìí wípé! Àwòkóse burúkú gbáà ni Linda Ikeji àtiwípé òun ni àwòkóse rere.OK olunloyo so òpòlopò àsírí nípa oyún inú Linda Ikeji àti nípa ara rè pàápàá.
    Àtiwípé Linda Ikeji ti kó bá òpòlopò òdóbínrin.

  • Sùúrù lógbà.

    Ìsé kìí se ohun àmúseré
    Ìyà kìí se ohun àmúsàwàdà
    Ebi ń pamí kìí mérìń p’ani
    Sebí ebi kìí w’onú
    Kí òrò míràn wòó

    Ojú tí ń kúkú pón isin
    Kìí se àpón ku
    Bí kòse àpónlà
    Bówù kópé títí
    Ìyà ayé eni ń bò wá d’ópin
    Sùúrù tó kúkú l’ójó ni

    Àforítì ló kúkú se pàtàkí
    B’órí bá pé n’ílè á kúkú d’ire
    Sùúrù lógbà

  • A o ni ri ogun aisan

    A o ni r’ogun aisan!
    Ifa ni:
    Pere ni tewe iyeye, aloye ni ti peregun;
    Piri l’eye olongo n ji;
    A kii b’okunrun eye lori ite;
    Gege lowu alantakun n fuye;
    Ota kii ku, ota kii run;
    Koko lara ota n le;
    Ojojo kii sokuta lale odo;
    Aluti la n lu eru oko;
    Aluti la n lu eru ada;
    Ere kii ba eri wo;
    Ko ba won wa kii ba won lo;
    Ope kii ba igi oko wo’we;
    Efun kii mu igun, edi kii mu alakan;
    Ota t’ota pa ka sai segun ota fun wa!
    Aase!
    Ao ni ba won ku iku ajoku!
    Edi, efun, asasi ko ni mu wa ati awon tiwa!
    Aaaaaaaaaaaase.

  • Iwure Ori

    Orí mi, gbe mi o! (My Orí, support me)
    Ori lo da mi (Ori is my Creator)
    Eniyan ko o (It is not man)
    Olodumare ni (It is Olodumare)
    Ori lo da mi (Ori is my Creator)

    Ori Onise (Ori, the competent Creator)
    Apere Atete gbeni ju Orisa (He who is faster in aiding one than the Orisa)
    Ori atete niran( He who instantly remembers his devotee)
    Ori lokun (Ori is valuable)
    Ori nide (Ori is jewelry)
    Ko si Orisa ti dani gbe leyin Ori eni (No Orisa can favour one without the consent of one’s Ori)
    Ori ni seni ta a fi dade owo (It is Ori that aids one for one to be crowned of money)
    Ori ni seni ta a fi tepa ileke woja (It is Ori that bless one for one to be using beaded walking stick even to the market)
    Ori ni seni ta a fi lo mosaaji aso oba (It is Ori that bless one for one to be using valuable cloths)
    Ori gbe mi (Ori, please, support me)
    Ori la mi (Ori, please, bless me)
    Ori ma pada leyin mi (Ori, please, never turn against me)
    Ase

  • Ifa naa ki bayi wipe: Emi ote, Iwo ote

    Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin ku ose ifá toni, emin wa yio se pupo re laye ase.
    Gegebi a se mo wípé oni ni ose ifá, e jeki a fi odù ifá mimo eji elemere yi se iwure ti aaro yi.
    Ifa naa ki bayi wipe:
    Emi ote
    Iwo ote
    Igbati ote di meji lo dododo a difa fun baba olorire malese ire igba iwase eleyi ti ori re nfojojumo ngbare sugbon ti ese mejeeji ko lo gba ire naa, won ni ko karale ebo ni ki o wa se nitori bi ori re ba tile gba ire ki ese re mejeeji naa baa le lo maa gba ire naa, obi meji…….. baba kabomora o rubo won se sise ifa fun nigbakugba ti ori baba bati wa gba ire ese re mejeeji yio wa lo gba ire naa, baba wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
    Baba wa fiyere ohun bonu wipe:
    Nje bi okan bayo ninu igbo a bona wa ire kasai wami wa o ire
    Bi aba bu Omi sori a bese wa ire kasai wami wa o ire.
    Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ire gbogbo yio maa sawari wa, ese wa mejeeji koni lodi sori wa, ao segun amubo, aseti, ijakule ati ki won ba eniyan da majemu ki won ma fise o aaaseee.
    ABORU ABOYE OOO.

    English Version
    Continue after the page break