Home / Àṣà Oòduà / A kú àmójúbà Osù Eréna (March) tuntun.

A kú àmójúbà Osù Eréna (March) tuntun.

Osù ìdèra, ìtèsíwájú, ìse rere ni yóò jé fún gbogbo wa. Nínú Osù tuntun yìí, àìsàn kò níí jé ìpín enìkóòkan wa. Eni yòówù tí àìlera bá n dà láàmú, Olódùmarè yóò so ó dèrò. A kò níí rí ìjà ìgbóná. Bí ó tilè wù kí ilé ó gbóná tó, Oba Adédàá yóò so ó dèrò. Àìsàn tí n gba oúnje lénu eni kò níí se wa, èyí tí n gba apá, esè, àti gbogbo èyà ara lówó eni kò níí jé ìpín wa nínú Osù yii. Àjíñde ara yó máa jé o.

Ilé tútù
Ònà tútù
A dí fá fún Olúweri-Mògétì
Àtòjò
Àtèrún
Ilé Olúweri kì í gbóná…

Ilé àti ònà kò níí gbóná mó wa nínú Osù yìí..

About Awo

One comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo