Ilé ọlọ́ti ni ilé ìtura, ibẹ̀ ni àwọn ọ̀rẹ́ ti npàdé fàájì
Ibẹ̀ náà ni àwọn èké, àti ọ̀dàlẹ̀ tin pàdé ara wọn
Ti ọti bá wọra tán, ara a sì rọ̀ wọ́n pẹ̀sẹ̀,
Ìgbéraga á wá wọ̀ wọ́n lẹ́wù
ọ̀rọ̀ á wá di dánmi wò, ngó ṣe bí mo ṣe tó
Bi mí́ léèrè nsèké, ó wá di mo sọọ́ tán, àsírí tú
Ìjà ọ̀dàlẹ̀ kò sì tán bọ̀rọ̀,
ngó gbẹ̀san, ọ̀dàlẹ̀ di méjì
Tani kí a báwí? ṣé ọtí ni?
Tàbí ọlọ́bọ̀bọ̀tiribọ̀?

Adeboye Adegbenro
Comments
One response to “Ọmùtí Gbàgbé Ìṣẹ́ (Ìrònú Ọlọtí)”
[…] from Ọmọ Oòduà http://ooduarere.com/news-from-nigeria/breaking-news/o%cc%a3muti-gbagbe-is%cc%a3e%cc%a3-ironu-o%cc%a… […]