Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Ogunda Meji/ Ejioko

Odu Ifa Ogunda Meji/ Ejioko

 |    |
|    |
|    |
| |  | |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana, bi ile oni se mo ao ri tiwa se ise wa yio si ni ibunkun lori ase.
Odu ifa OGUNDA MEJI/EJIOKO lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo to ba jade si niyanju wipe ki o rubo daradara nitori oun fo ire aje lopolopo fun, ifa ni gbogbo adawole re yio maa yori sire ni.

Odu Ifa Ogunda Meji
Ifa naa ki bayi wipe: isu gbojo isu pari koko lo se alaigburo Ojo to wa erin mole jainjain akere lo se alaigburo Ojo to fa iwerepe lorun a difa fun ope segesege lojo ti o nsukun pe oun ko laje, won ni ko karale ebo ni ko wa se eyele funfun, obi meji, ogidi ose, igba ewe ayajo ifa ope segesege kabomora o rubo won se sise ifa fun, lati igba naa ni ope segesege ti di alaje to ti di olokun to ti di onide o wa la gbo bi ile ere okin o wa njo o nyo o nyin awo awo nyin ifa, ifa wa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami nijebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa.

Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio pese fun aini wa yio si fa gbongbon ise ati osi tu kuro ninu igbesi aye wa, eledumare yio jeki a bawon we ninu odo aje ti gbogbo iya jije yio si di oun igbagbe ninu aye wa o aseeee.
ABORU ABOYE OOO.

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was great, may today bring us an abundant blessings and achievements.
It is OGUNDA MEJI/EJIOKO corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice because he forsee the blessing of wealth for him/her.

Hear what today’s corpus said: isu gbojo isu pari koko lo se alaigburo Ojo to wa erin mole jainjain akere lo se alaigburo Ojo to fa iwerepe lorun it cast divined for palm tree when she was crying of lacking of wealth she was advised to offer sacrifice, a white pigeon, two kola nuts, local soap and ifa leaves and she complied, aftermath a palm tree became wealthy and flourished she was dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

My people, I pray this morning that God in his infinite mercy provides for our lacks, uproot wretched in our life and we shall all swims in the ocean of wealth today and all our sufferings shall be gone away ase.

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

Looking at the Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá, it could be said that sometimes our detractors feel they are hurting us but they don’t know they are pushing us to wealth. Just listen to this stanza from the Odù. Òtééré ilè ńyóÒtèèrè ilè ńyòIlè ńyó ará iwájúÈrò èyìn e kíyèsí ílèAdífá fún Ìwòrì tí yóó tarí Ogbè sínù àbàtàbútú ajéKòìpé kòìjìnà, Ogbè ló wá jìn sínú ajé gbugburu Òtééré, the ground is slipperyÒtèèrè, the ground is difficult ...