
Ipokipo ti eda ba wa laye, e pe ko maa dupe. Ibikibi ti ori ba da ni si ka fi ope fun Oluwa oba nitori awon kan ko tile ni ida kan ninu ogorun anfaani ti a ni. Ebi n pa awon kan, kosi si ounje fun won rara. Ogun, wahala, rukerudo ati aibale okan ti so awon ilu kan sinu adawon ayeraye. Foto yii lo lalewu lori ikanni Facebook, eleyii to n se afihan omobirin alaini, alailenikan, eni ti ko ri ounje je rara, nibi to ti n sin omo re sinu koto.
Author: oodua
-
Abiyamo Fi Omije Gbe Omo Re Sinu Koto
-
Won Fi Leta Pe Pasuma Pe Ko Wa Korin Ni Soosi Baba G.O Adegboye

Abi foto Buroda Alabi Pasuma ko ni mo n wo yii ni? Ko ma si eni ti Olorun ko le fi owo to lokan sa o. Burudo Pasuma, Orobokibo Creator, Oga Nla 1, Ijaya of Fuji, Oluwa yoo ma so agbara yin dotun oo.
-
Sayewo Omo Ita, Jaguda Ti Buhari Fi Se Oludamora Nipa Oro To N Lo Nile Igbimo Asofin
Honorebu Suleiman A. Kawu ni yii, okan ninu awon omo ile igbimo asofin ti n fo iganna nigba rogbodiyan to waye nile igbimo asofin ni akoko ti Goodluck Jonathan wa lori oye gege bi Aare ile Nigeria olominira.Maanu yii kan naa wa lara awon ti Aare Muhammadu Buhari ti yan bayii gege bi oludamoran nipa awon oro to n lo nile igbimo asoju sofin ile Nigeria.
Pelu bi oko Aisha se n pariwo wi pe awon eniyan gidi, omoluabi oloselu ati olooto ni awon eniyan ti oun fe ninu isejoba oun, nje awa le pe eniyan ti n fo iganna gege bi omoluabi alaponle bi?
-
Oko Toyin Aimakhu, Adeniyi Johnson Ti Dale Ife

Laipe yii ni omobirin naa yo oruko oko re kuro ninu oruko re. Bakan naa ni awon eniyan tun kiyesi wi pe awon foto oko re to wa lori ikanni instagram re lo ti fe e gbonyo tan.
Adeniyi Johnson ti n be iyawo re bayii, o ni oun loun jebi ohun to n fa wahala laaarin awon mejeeji. E le ka alaye re nibi: http://www.facebook.com/photo.php?fbid=881199908632560&set=gm.1037407549643887&type=1
Awon kan ni oko re se asemase kan ni, isele naa si bi Alakada ninu pupo ju.
Awon eniyan kan ti n be Toyin wi pe ko maa binu, nigba ti awon kan n naka abuko si oko re ati gbogbo okunrin gege bi olojukokoro, to je wi pe gbogbo ejo ni jije lodo won.
E tun le ka ohun ti awon ololufe Toyin n so nibi: http://www.facebook.com/photo.php?fbid=881200005299217&set=gm.1037407549643887&type=1
-
“Kini Idi Ti Fasola Fi Wu Ewu Funfun Lori Ko To Kuro Nijoba?” Ninu Iwe Iroyin Owuro Ni Idahun Naa Wa

Akole gbagada to jade lati inu iwe Iroyin Owuro ti ose yii lo n so nipa ohun to faa ti Fasola fi wu ewu lori ko to pari ijoba re nigba ti awon akegbe re bi Mimiko ati Ajimobi n dan gbirin.Awon akole mii to tun wa loju ewe akoko iwe Iroyin Owuro niyii:
*Omoge Mejilelaadota ti ko mokunrin ri se idije lEkoo
* Idi ti emi ati Tinubu fi daru- Gbenga Daniel
*Ni Akure, awon Omoota seruba Odunlade Adekola.
Ati awon iroyin mii to gbamuse.
E gbiyanju kee ra Iroyin Owuro, ogorun naira pere ni.
olayemioniroyin
-
Awon Omo Ologun Ile Nigeria Fi Emi Awon Omo Boko Haram Ti Won Woso Ologun Sorun Sofo Bi Omi Efo

Asiri awon omo Boko Haram kan ti won wo aso ologun sorun sise buburu owo won ti tu ni apa ila oorun-arewa ile Nigeria. Awon omo Ologun Nigeria yosi won ni ibuba won ti won go si, won si se won sibalasibolo. Oku awon omo Boko Haram si lefo sori ile bi oku aja. -
Adajo Ti Dajo Iku Fun Omobirin To Gbe Ogun-Oloro Pamo Si Oju-Ara Re Ni Ilu Thailand

Ile ejo ti dajo iku fun Chonmanee Laphathanawat, eni ogbon (30) odun ni ilu Thailand pelu esun gbigbe ogun oloro cocaine ni orileede Thailand.Omobirin yii ni won mu pelu bo se sin ogun-oloro ti won ti ro sinu kapusu (capsules) bi aadorin (70) si oju-ara ati inu iho idi re.
Ana, 27-08-2015, ni won da ejo omobirin naa.
Ki Oluwa oba dari gbogbo ese re jin-in.
E sora fun ogun-oloro. Ko Dara!
-
Aja Je Omo Tuntun Niluu Asaba !
Abiyamo Padanu Omo Re Kan Soso Sinu Agbara Eje

Isele kan to sele lojo Eti to koja yii ni Asaba to wa ni Ipinle Delta je eyi to ba ni lokan je jina.
Arabirin kan, eni odun metadinlogoji (37), Maureen Akowe, la gbo wi pe o padanu omo re eni osu merin bi aja re se koju ija si omo re.
Gege bi iwe iroyin LEADERSHIP ti ile Nigeria to jade lonii, Sande, se so.
Omobirin naa ko omo re, aja ati omoodo ti n ba toju omo sinu moto lati lo re e ra nnkan nile itaja igbalode to wa loju ona Okpanam niluu Asaba.
Igba ti won de ile itaja naa, iya omo jade lati lo ra nnkan ninu ile itaja nigba to fi omo re, omoodo ati aja re sinu moto.
Nibi ti iya omo ti jade lo ra awon nnkan to fe ra ni aja ti fo mo omo tuntun lojiji to si bere si ni fehin san omo naa ni gbogbo ara de ikun ati oju.
Omoodo naa figbe ta fun iranlowo awon eniyan to wa lagbegbe naa sugbon pabo naa ni gbogbo re jasi.
Awon osise alaabo ile itaja pada gbo igbe omoodo naa. Nigba ti won yoo fi sare de idi moto ti ariwo ti n jade, omo osu merin ti won pe oruko re ni Chinonso ni aja ti ba ara re je koja bo ti ye. Inu agbara eje ni won ba omo naa ki won to gbe e jade.
Oju aja to se ise ibi naa ti yi pada. O ti bere si ni se bi aja digbolugi, bee ni i gbo kikankikan bi igba ti kinihun ba n bu ramuramu. Oju re ti ranko bi ti ogidan ololaaju, bee ni ahon re yo lala sita to si n kan eje lenu balabala.
Iya omo naa pada mo nipa isele naa, kete ni won si ti gbe omo naa lo si osibitu to wa loju ona Nnebisi.
Sugbon igba ti won yoo fi de osibitu, omo eje orun alailese lorun naa ti pajude ti ko si le mi mo.
Ohun ti omoodo madaamu so ni yii:
“Madaamu gbe aja naa sinu moto nitori a fe ya gbe aja naa ri dokita eranko. Sugbon nigba ti a de supamakeeti ti madamu fi emi ati aja ati omo sinu moto, sadeede ni aja naa yanu. Eru ba mi. Mo logun pe madaamu, sugbon madaamu ko gbo igbe mi.”Gege bi iwadii awon oniroyin lowo awon molebi. Won ni odun meta seyin ti arabirin naa ti se igbeyawo ti ko si tete romo bi niyii. Okan soso ti Olorun fun un naa lo ti pada gbe senu aja yii.
Oko omobirin naa soro, bo ti n soro ni ekun kikoro n jade lenu re.
“Iyawo mi ni ise esu ni, esu un gan-an naa ni yoo ti jade nile mi. Mo ti ki i nilo nipa aja un nigba ti mo sakiyesi wi pe awon iwa aja naa ti yi pada. Ko gbo si mi lenu, o si n gbe aja naa kiri. O ni oun yoo gbe lo fun itoju. Se ri aye mi ba yii? O ti fi oriburuku ara re ko ba mi.”
-
Awon foto: Ayeye Igbeyawo Omo Gomina Abiola Ajimobi Le Ku!
Oni ojo kokanlelogun, osu kejo (Aug 21), odun 2015 ni Gomina Abiola Ajimobi n se igbeyawo fun omo re obirin, Ajibola pelu oko omo re, Ayokunle Olayiwola.
Orisirisi awon eniyan nlanla ati awon gomina lati apa iwo-oorun guusu Naijeria ni won ti pejupese sibe. Omo Baba Olowo, Davido ati Olamide ko si dake orin lati maa fi da awon eniyan lara ya.






