Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Ijamba oko waye ni Victoria Island lonii

    Ijamba oko to waye lonii ni agbegbe. Ozumba Mbadiwe, VI, niluu Eko.
    Oko ajagbe akeru naa run mo awon oko bi merin kan nigba ti bireki re ko muu mo.

    Enikeni ko fara pa, dukia lasan lo sofo.

  • Obalufe, igbakeji Oba Okunade Sijuwade ti dagbere faye lonii

    Obalufe ti Iremo-Ife, Oba Samuel
    Omisakin, eni to kangun si Ooni Ile-Ife, Oba Okunade Sijuwade gege bi igbakeji, to tun je olori awon afobaje ti ilu Ile-Ife naa ti dagbere faye lonii [15-10-15].

  • Oserebirin onitiata wo ni yii?

    #Oniroyin  Olayemioniroyin.com

    Taani obirin to wa ninu foto yii?

    obirin

  • Ore idunnu wole fun awon ti Boko Haram pa lekun nipinle Borno

    Arabirin yii bi ibeta (omo meta) ni ipago ti won pese fun awon eniyan ti Boko Haram so di alainile lori to wa ni Bama ni ipinle Borno.

    E wo linki isale yii:

    @OlayemiOniroyin

     

  • Owo awon olopaa te ole ajipata ati komu niluu Ibadan

    Ero o gbese ni olu ile ise awon olopaa ipinle Oyo to wa ni Eleyele nigba ti won se afihan awon igara olosa ajipata ati komu gbe fun awon oniroyin niluu Ibadan.

    Awon ole bi merin yii lagbo wi pe won lo fo soobu ti won ti n ta awotele awon obirin loru Ojobo mojumo ojo Eti to koja yii ni agbegbe Sango to wa niluu Ibadan.

    Leyin ise buruku owo won, awon figilante adugbo naa to ipase won lo si ibuba won to wa ni agbegbe Apete ni ijoba ibile Ido, ko to di wi pe won fa won le awon agbofinro lowo.

    Bolanle Ogunmiye, onisowo ti awon ole naa ja soobu re ti bere si ni bu omi ope mu fun komisanna awon olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adeleye Oyebade fun iranwo ti won se lati ri awon ole naa mu.

    Ile ise olopaa ipinle naa si fi da awon oniroyin loju wi pe awon ole naa ko ni i foju bale ejo lati lo foju wina ise owo won.

  • Ori iya mi ooooo! Ukwu ore Yemi Alade ti da gobe sile o.

    Wahala ti bere si ni sele lori ayelukara bayii, eleyii si bere nikete ti Yemi Alade se afihan foto re pelu awon ore, eni to se apejuwe won gege awon ololufe orin re. Awon eniyan ko tile soro nipa Yemi Alade, “apoti aje” ti ore re gbe seyin gan-angan lo fa rigimo oun surutu bayii.

    olayemioniroyin.com

  • Won we ose awure fomo Poli Ibadan


    Eniyan le fi ebi kose owo, sugbon ko rorun lati febi kawe. Wahala igo ni o pa alasuota. Ise akanse, ka ji kawe loru, lo soke lo sode, ka sare wo kilaasi losan pon ganrin-ganrin ni o je komo ile iwe o nisimi.

    Bi won ba wa jade, ayo nla ni.

    Okan ninu awon omo Poli to wa ninu Ibadan, Shina Shiba, lo se afihan foto ati akole yii: “Finally log out from polystressnic(polytechnic) Ibadan” Adura mi wi pe ki Edua oke ba mi so ona won dayo, ki won ri taje se, ki ona won o la sire.

    Ase !

  • #OGULUTU: Olaju ti so ogbon aye atijo di omugo patapata


    E ku asiko yii eyin eniyan mi, ko to di wi pe n maa se alaye ara mi tabi abala Ogulutu to je tuntun to gori Iwe Iroyin Owuro.

    E je n sare bi yin nipa oun ti won pe ni “olaju.”

    Kini olaju? Olaju je iyipada igbe aye awon eniyan nipa ohun eelo, irori tabi bi won se n ronu, imo ati ibasepo won pelu awon eniyan awujo; eleyii to yato si ti aye igba iwase.

    A tun le so wi pe olaju je wi wo inu aye otun lati inu aye atijo pelu igbagbo wi pe aye otun dara ju aye atijo lo.

    Awon kan tun se alaye olaju gege bi irin ajo lati inu igbe aye kan bo sinu igbe aye mi-in, eleyii to n tesiwaju laiduro rara.

    Ohun pataki kan tun wa nipa olaju to ye ko ye gbogbo wa. Ti awujo ba n yi pada, o di dandan ki awon eniyan inu re yii.

    Nitori wi pe ayipada to de ba igbe aye awon eniyan gan-an lo mu ki awujo o maa yi pada.

    Ti igba ba wa n yi pada, ti awon eniyan awujo ba ko lati yi pelu igba, dandan ni wi pe ikolura tabi isoro yoo waye ninu igbe aye awon eniyan awujo.

    Ki alaye mi le ye yin, e je n gbe opele ewi mi sanle. Eleyii wa lara awon ewi ti mo ke nikete ti a n mura lati jade ile iwe:

    “Aye laelae lomo mi roju kawe ko gboye nla.
    To o ba gboye, ise n be ni sekite f’alakowe to de tai morun.
    Boya leyin mo wi pe alakowe to de tai morun o rise mo.
    N se ni gbogbo won fese e tale kiri.
    Ebi won kuku ko,
    Sebi ise ni o to nnkan, omi lo se bee po joka”.

    Bi o tile je wi pe iwe se pataki, sugbon o ti ye ki oye ye opolopo wi pe iwe nikan o to mo lati di eniyan atata lawujo bi ti aye atijo.

    Igba n yi pada, olaju ti wole de. Ise egberun eniyan ti di ise ti enikan soso le se pelu iranlowo ero igbalode. Bee iye awon eniyan n posi kaakira agbaye lojoojumo.

    Oye yii gbodo ye wa, a si gbodo wa ni imurasile lati ba igba yi, ati lati dogba pelu olaju to wole de.

    Ti a ba ko lati se bee, afaimo ki awo ma sun lebi.

    Olayemi, ojo ti n ro ti o ti da ni, Edua oke nikan lo mo iye eni ti o pa. Mo n meye bo lapo, e ni dudu ni, e ni funfun ni. Eni a n gbe iyawo bo wa ba, awon agba ni kii gbe ori iganna woran.

    Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ogulutu oro to ba denu afefe dandan ni ko fon de gbogbo ilekile. Sultan Akoroyin kaabo!

    E ma gbagbe, bi eniyan ba fe gbe igbe aye ode oni ko pegede, onitoun ni lati kogbon aye ode oni to je gidi. Bawo ni eniyan se le ko ogbon aye ode oni?

    E pade mi lose to n bo lagbara Eledumare oba mi oke. Ire o!
    Olayemi Olatilewa
    www.olayemioniroyin.com

  • Kayeefi niluu Eko: omokunrin ti o lese n wa danfo

    Kayeefi niluu Eko: omokunrin ti o lese n wa danfo. E le ka ero awon eniyan nipa okunrin yii nibi:

  • Ere Opolo: Matimatiisi to gbona felifeli

    Ile itaja kan n ta masiini okada ati keke maruwa. Apapo gbogbo oja ti won ni je. meje (apapo okada ati keke maruwa), gbogbo oja won lapapo si ni taya mokandinlogun.

    Nje o le so iye okada ati keke maruwa to wa ninu soobu naa, to ba je wi pe taya meji ni okada ni ti keke maruwa si ni meta?