Category: Àṣà Oòduà

Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.

  • Oniroyin Meji Ti Wa Ni Kirikiri Bayii: Ise Iroyin Won Lo Ko Ba Won


    Alase banki Fidelity ti Nigeria, Ogbeni Nnamdi Okonkwo ni Oniroyin Seun Oloketuyi gbe saye lori ikanni re, www.naijahottestgist.com wi pe oga banki naa feran ko maa se “yodiyodi” fun awon osisebirin banki re.

    O ni yato si awon osisebirin re, awon kositoma ti won ba tun je “gala” oga banki, lila ni gbogbo won lodo Okonkwo, won ni maanu naa gbadun “kerewa” pupo ju.

    Seun Oloketuyi ni awon olopaa koko gbe, eleyii ti won ti lo foju re bale ejo pelu esun ibanilorukoje eleyii ti oga agba banki Fidelity fi kan an.

    Lori eleyii la wa, ni Ogbeni Dare Lasisi, Jagunmolu akoroyin ti n pidan lori ikanni darelasisi.co.uk tun kede wi pe won ti gbe Chris Kehinde Nwandu, olootu ikanni www.cknnigeria.com lori esun kan naa.

    Gege bi ohun ti Dare Lasisi kede re, o ni awon oniroyin mejeeji naa ti wa ni Kirikiri bayii nibi won ti n fi kondo fun won lewa olomi sooro je laaro ati lale.

    Sugbon ohun kan ti awon oniroyin ile Naijeria n wa okodoro re ni wi pe, se ooto ni iroyin ti Seun Oloketuyi ati Chris Kehinde Nwandu gbe jade abi won kan fi ba maanu naa loruko je lasan ni?

    Se Ogbeni Nnamdi Okonkwo n gbe igbese yii lati fi aso bo iwa eeri ara re ni abi won paro mo lotito gege bi awijare agbejoro re, barisita Olakanmi Omisope.

    Olayemi Oniroyin, e je n duro nibi ko to di wi pe won yoo ni ki n wa so eyi to ku l’Alagbon. Sebi e mo wi pe mi o laapon, ati wi pe mi o laiki ewa olomi sooro.

    Sebi eyin mo mi…

     

    Orisun: olayemioniroyin

  • Iresi Gomina Ayodele Fayose Tun Pada Wo Ipinle Ekiti

    Ikere Ektiti ni won ti pin. Atomode atagba, arugbo naa gba ninu iresi Fayose.

    Ohun ti awon eniyan so nipa re wa nibi:

  • Oko Ajagbe Eleru Leyin Jabo Lati Ori Afara Ojuelegba: Emi Awon Eniyan Ba Lo

    Oko ajagbe eleru leyin kan jabo lati ori afara to wa ni Ojuelegba niluu Eko losan-an oni. Eniyan meji to wa ninu oko ti ajagbe naa jabo le lori fi ile aye sile loju-ese ti isele naa waye nigba ti awon kan fara pa koja bo ti ye.

     







  • Oriki Ibeji : Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún

    Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún.
    Ẹdúnjobí

    Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi

    Ọ́-bẹ́-kẹ́ṣé-bẹ́-kàṣà,
    Ó fẹsẹ̀ méjèèjì bẹ sílé alákìísa;
    Ó salákìísà donígba aṣọ.

    Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
    Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọ́mọ.

    Wínrinwínrin lójú orogún
    Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.

    Tani o bi ibeji ko n’owo?

    Orisun

  • Odaju Abiyamo Fi Ina Jo Omobirin Eni Odun Merindinlogun Loju Ara: O Ni Omo Naa N Se Agbere


    Omobirin odaran kan ni owo awon olopaa ti te ni agbegbe Ketu niluu Eko pelu bo se fi ero ayoonu iloso jo omo egbon re ti n gbe pelu re, Bimpe Badmus, omo odun merindinlogun, nidi pelu esun wi pe omobirin naa n ba omo lanloodu won lajosepo.

    Isele to sele ni opopona Ogunjimi ni obirin naa ti fi ayoonu iloso jo Bimpe loju ara, ikun ati itan omo naa pelu iranlowo awon awon ore meji kan ti won ba a mu omo naa duro.

    Gbogbo awon onise ibi naa ni won ti wa ni gbaga awon olopaa bayii nibi ti won ti n jo “azonto” nigba ti Bimpe wa ni osibitu.

    Lara oro Bimpe, “Iro ni gbogbo oro naa, ko si nnkankan laaarin emi ati omo lanloodu.”

  • Awon Foto Lati Ibi Ijamba Oko Ofurufu Awon Omo Ologun Niluu Kaduna

    Awon aworan Oko ofurufu Dornier 228 ti awon omo ologun ile Nigeria ti a kede wi pe o jabo loju orun laaro oni ni yii. Awon eniyan meje ti won wa ninu oko ofurufu naa lo parun patapata.



  • Aso Oge Funke Akindele Ta Lenu Yeriyeri: Jenifa Pe Omo odun Mejidinlogoji (38)


    Aworan Funke Akindele niyii niluu Oba nibi to ti n yo ayo ojo ibi re to ko laipe yii (August 24). Ka ma paro, Funke Akindele ta lenu! Lati irun ori re de bata to wo sese ni i sana bi ti ina elentiriki.

    Aso kaba to wo tun leku! Aso naa kii se tile yii, toke okun ni. Aso ti won fi goolu ati owu dudu ran pelu bata onile gogoro lese.

    Aso naa o de orunkun re; ilaji itan lode. Eleyii to fi anfaani sile lati ri ilaji itan ese re nita. Itan omoge naa tutu loju bi edo eran ti won ko jade lati inu omi bee lo mo lolo lailabawon bi ara omo tuntun jojolo.

    Yato si eyi, aso oge re tun rora si igbaaya re sile ferefe, eleyii to je wi pe ko si okunrin ti o gboju sona ibe ti ko tun ni fe tun wo leekan si.

    Atike oju re ko poju, iwonba naa si tun ni itote pupa enu re.

    Eniyan dudu ni Funke sugbon o dabi eni wi pe oju re ti n funfun.

    Odun 1977 ni won bi Olufunke Ayotunde Akindele si agbegbe Ikorodu to wa niluu Eko.
    Ojo aje to koja yii lo si pe omo odun mejidinlogoji (38).

    A ki Jenifa wi pe oku ori ire. Igba odun, odun kan ni

    Source

  • Oko Ofurufu Helicopter Ti Awon Omo Ologun Ti Jalule Ni Ilu Kaduna


    Oko ofurufu helicopter eleyii ti awon ologun n lo fun idanileko lo jabo ni ibuba awon omo ologun to wa ni Kaduna leyin iseju mewaa to gbera soke.

    Ilu Abuja lagbo wi pe oko ofurufu naa n lo ki lala re to lo soke to pada wale loju kan naa mbe.
    Gege bi itopinpin Olayemi Oniroyin, awon eniyan bi meje ti won wa ninu baalu naa la gbo wi pe won parun.

    E ku etileko fun akotun iroyin.

    Orisun Iwe Iroyin

  • Osise Arik Airline Ba Naija Loju Je Niluu London: Won Ka “Lafun Funfun Alata’ Mo o Lowo


    Owo ti te CHIKA EGWU UDENSI, okan ninu awon osise ile ise oko ofurufu ARIK Airline ni papako ofurufu HEATHROW ti ilu London pelu ogun oloro kokeeni.

    Ogun oloro ti won ka mo bobo naa lowo ni won ni iye owo re yoo to nnkan bi ogorun milionu owo naira.

    Oruko Nigeria ti emi n gbiyanju lati tun se ni awon kan si n gbinyaju lati maa yimo inu erofo loju awon ebo.

    Laaarin emi ati CHIKA EGWU UDENSI ija sese bere ni o.