Home / Àṣà Oòduà / Oniroyin Meji Ti Wa Ni Kirikiri Bayii: Ise Iroyin Won Lo Ko Ba Won

Oniroyin Meji Ti Wa Ni Kirikiri Bayii: Ise Iroyin Won Lo Ko Ba Won


Alase banki Fidelity ti Nigeria, Ogbeni Nnamdi Okonkwo ni Oniroyin Seun Oloketuyi gbe saye lori ikanni re, www.naijahottestgist.com wi pe oga banki naa feran ko maa se “yodiyodi” fun awon osisebirin banki re.

O ni yato si awon osisebirin re, awon kositoma ti won ba tun je “gala” oga banki, lila ni gbogbo won lodo Okonkwo, won ni maanu naa gbadun “kerewa” pupo ju.

Seun Oloketuyi ni awon olopaa koko gbe, eleyii ti won ti lo foju re bale ejo pelu esun ibanilorukoje eleyii ti oga agba banki Fidelity fi kan an.

Lori eleyii la wa, ni Ogbeni Dare Lasisi, Jagunmolu akoroyin ti n pidan lori ikanni darelasisi.co.uk tun kede wi pe won ti gbe Chris Kehinde Nwandu, olootu ikanni www.cknnigeria.com lori esun kan naa.

Gege bi ohun ti Dare Lasisi kede re, o ni awon oniroyin mejeeji naa ti wa ni Kirikiri bayii nibi won ti n fi kondo fun won lewa olomi sooro je laaro ati lale.

Sugbon ohun kan ti awon oniroyin ile Naijeria n wa okodoro re ni wi pe, se ooto ni iroyin ti Seun Oloketuyi ati Chris Kehinde Nwandu gbe jade abi won kan fi ba maanu naa loruko je lasan ni?

Se Ogbeni Nnamdi Okonkwo n gbe igbese yii lati fi aso bo iwa eeri ara re ni abi won paro mo lotito gege bi awijare agbejoro re, barisita Olakanmi Omisope.

Olayemi Oniroyin, e je n duro nibi ko to di wi pe won yoo ni ki n wa so eyi to ku l’Alagbon. Sebi e mo wi pe mi o laapon, ati wi pe mi o laiki ewa olomi sooro.

Sebi eyin mo mi…

 

Orisun: olayemioniroyin

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

tems

Mo setán láti kú’ – Tems

Mo setán láti kú’ – Tems Mary Fágbohùn Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti safihan pe oun setan lati doju ko saare nigba ti oun fi eya orin takasufe ti gbogbo eniyan mo kaakiri orile ede sile fun R&B. Tems wi pe oun ni igbagbo pupo ninu ara oun to bee ti oun ko bikita bi oun o ba “je nnkankan tabi da enikeni” pelu R&B. Olorin ‘Essence’ naa so pe oun kan ...