Home / Àṣà Oòduà / Oriki Ibeji : Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún

Oriki Ibeji : Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún

Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún.
Ẹdúnjobí

Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi

Ọ́-bẹ́-kẹ́ṣé-bẹ́-kàṣà,
Ó fẹsẹ̀ méjèèjì bẹ sílé alákìísa;
Ó salákìísà donígba aṣọ.

Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọ́mọ.

Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.

Tani o bi ibeji ko n’owo?

Orisun

About Lolade

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

“Ta Ní Ó Wà Kí Ayé Tó Wà? Ìtàn Àkọ́kọ́ Ìṣẹ̀dá Gẹ́gẹ́ Bí Ifá Ṣe Sọ Ó.”

Kò sí ohun ẹlẹ́mìí kankan láyé awo ilé Ayé ni ọ̀run àkọ́kọ́, ohun tí ó so kàrà tí kò sọ̀kalẹ̀, awo òde Ọ̀run ni ó ń pè é, gbogbo rẹ̀ jẹ́ òfìfo lásán, òfo pónbele, láìní ìpìlẹ̀, láìní ẹ̀dá kankan, Awo àárín gbùn-gbùn òde ni ó wí i, A dífá fún Ayé àti fún Ọ̀run, nínú ìkarawun ìgbín méjì tí ó ṣófo, kò sí ẹyẹ, kò sí ẹ̀mí tí ń gbé inú wọn, ìpìlẹ̀ kò tí ì sí, afẹ́fẹ́ kò ...