Home / Àṣà Oòduà / Leta ife jade lojo ti Olamide Orente se ojo-ibi alarinrin

Leta ife jade lojo ti Olamide Orente se ojo-ibi alarinrin

Eni odun ba ba laye, e pe ko sope. Eni Edua oke ba dasi, e pe ko ke aleluya s’Olorun Oba.  Ojo nla ni ojo oni je, ojo kejila osu kokanlan odun, ojo ti Omidan Awelewa Amoke, Oba Oge Eleyinju-ege Orente, Olamide Matthew n se ayeye ojo-ibi alarinrin.

Ka ma paro, Olamide rewa lobirin. Se ehin funfun ni ka so ni abi oju to gunrege bi ti angeli Oluwa?

Eniwee, Olamide Orente ti gba leta kan pataki lati owo maanu kan pataki lonii ojo to pataki ninu odun 2015.

Leta naa si ti dowo Olayemi Olofofo, sori, Olayemi Oniroyin ni mo fe wi.

Leta naa ni yii:

Sii Olamide ololufe mi pataki,

Ohun ti eniyan ko mo, kedere ni niwaju Olorun oga ogo. Ife otito koja ohun ti won le de pamo sinu agolo. Opuro laye, inu won nise dudu n gbe. Sugbon eniyan o gbon bi Olorun lokan mi se bale.

Olamide mi, ewa re lo wu mi ju, omoluabi re ni i dami lorun bi egbin. Laakaye re ni i se mi ni kayeefi. O logbon lori, o tun ni sensi to po. Ope ni fun Oluwa to mu o ri ojo oni ninu idera. Omo olojo-ibi, tie peleke!

Iwo ni iyo to so aye mi di Ayo. Iwo nife to so mi di gbajumo laaarin awon okunrin. Titi laelae ni i ma nife re, ololufe mi atata.

Igba odun, odun kan ni fomo olojo-ibi.

Emi ni ade ori re, Olapeju Ayodele
……………………………………….»

Sii Olapeju Ayodele,

Ifemi, Ayomi, Ademi, Olowoorimi, o seun mi pupo-pupo. Iwo ni abatabutu omi odo abumu ti ko je ki oungbe o gbe mi. Iwo nigi leyin ogba to o je koju o ti mi.

Sebi iwo nife otito ti n mumi sebi oba oge loju araye. Iwo l’Ade too je kori mi wa ni kolobo. Iwo l’Oosa ti n ba mi rin laifoya.

Ololufe maa gbo, apaadi to doju kogiri, togiri ni i se. A ti toje boloosa lowo, baba eni ti o bo kan o tun si mo laye n bi. Sebi ireti mi mbe ninu Oluwa ti kii ye, Oba alasepe ti kii doju tini.

Titi laelae ni i ma nife re, ife mi owon.

Emi ni ododo ife re, Olamide

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo