Kí á dijú ká se bí eni tí ó kú kí á wo eni tí yó se ìdárò eni
Ká fi esè ko gbàù kí á wo eni tí yó seni pèlé
Ayé laó ti mo eni tí ó ń fé teni
Ayé La Ó ti mo èèyàn àtàtà
Nítorí ojú larí kòdénú
Ìbá jé wípé inú se sín bí igbá ni à bá kúkú mo èèyàn àtàtà
Àfi kí á se rere
Kí á tún te ilè jéjé
Nítorí Alágemo tí ó se jéjé ikú paá ábàlètànsé òpòlò tí ó gbé ara è sánlè
Ará mi ayé le.
Category: Àṣà Oòduà
Àṣà Oòduà, Asa Ibile Oòduà. Oòduà (Yoruba) je okan ninu awon eya ti o laju ju lode aye yi. Lati igba ti alaye ti daye ni won ti ni eto ati ilana to kun nipa ohun gbogbo ti won nse ni igbesi ayee won.
-
Alágemo tó se jéjé ikú pa á.
-
Grace Oyelude, obìnrin àkókó tí Ó kókó gba àmì èye omidan arewà ní orílè èdè Nìjíríà.
Grace Oyelude, obìnrin àkókó tí Ó kókó gba àmì èye omidan arewà ní orílè èdè Nìjíríà.
Ìyáawa Grace Atinuke, tí won bí ní ojó kerìndínlógún osù beelu ní odún 1931, tí a mò sí eni tí ó kókó gba àmì èye omidan arewà ní orílè èdè Nìjíríà ní odún 1952.
Lóòtó ìlú Kogi ní won tí bí màmá, ìyáawa oyelude ni a bí sí ilé Kano sí ìdílé James Adeleye Olude àti Marthan Dantu tí àwon méjèèjì jé omo bíbí Isanlu, tí a mò sí ìpínlè Kogi báyìí.
Arewà ni ìyá ní tòótó e wo bí won se tún re wà.
-
Irú kí ni eléyìí báyìí, àfi kí olúwa olódùmarè .
Nìjíríà àfi kí olórun gbà wá lówó gbogbo hílàhílo tí ó ń selè yí, irú kí leléyìí báyìí .
Eléyìí ló selè ní Oghara. arábìnrin kan ni ó ún gun òkadà lo tí ó sì gbé epo beetíròlù séyìn nígbà tí okò tí a mò sí Lexus jeep, epo beetíròlù yí dànù arábìnrin yí sì jóná di eérú.
Olórun, olódùmarè dárí jìwá ní orílè èdè yí..
-
Ojó mánigbàgbé ní ilé-èkó gíga Obafemi Awolowo university (OAU).
Ojó mánigbàgbé ní ilé-èkó gíga Obafemi Awolowo university (OAU).
Ìsèlè burúkú gbáà ní Óní selè ní ojó kewàá osù keje odún 1999 ní ilé-èkó gíga ifáfitì Obafemi Awolowo university nígbà tí èmi oní inú ire sì gba ibè lo.
Afrika se béè Ó ta èjè rè sílè fún àwon akékòó ilé-èkó yí láti dènà egbé òkùnkùn láti ìgbà náà ni àláfíà, ìfòkànbalè ti wà nínú ogbà yí. Njé ó wá ye kí á gbàgbé ojó yí bí?
Èní lópé odún mókàndínlógún tí Afrika kú fún wa, kí ló wá dé tí a kò le polongo “kí egbé òkùnkùn wá sí òpin ” kí lódé tí a kò le rántí èjè tí Óní kú fún akékòó?
Akoni ni Afrika ejé kí á se ayeye ìrántí fun, kí á kí àwon ebí rè wípé wón kú afárárekù eni rere..
Njé Ìwo tí setán láti gbógun ti egbé òkùnkùn bí?.
-
AJE NIMO FẸẸ!
.
AJE NIMO FẸẸ!
Ohun aje f’oju miri ẹnu o le sọ;
Oju miri to lori ọrọ aje;
Owo(business) f’ẹgbin rẹmi lara;
Ninu ẹgbin lọla fiṣe ile;
Ọrọ kobakungbe inu iṣẹ-aje ni ngbe.
Aje ogugu ni sọ;
Onisọ iboji o;
Aje jọwọ fi ile mi ṣe’bugbe;
Bi eṣu ọdara ṣe gbajumọ to;
Ko gbajumọ to owo;
Aje fi ile mi ṣe’bugbe o;
Ẹja o ni tobi titi;
K’omi magbe mi;
Ẹyin lọmọ adiyẹ n tọ‘ya ẹ;
Emi ni ki nmaa ran owo niṣẹ;
Aje jọwọ fi ile mi ṣe’bugbe o.
Ibi tan ti n nawo;
Jeki nba wọn naa;
Ibi tan ti n gbayi;
Ẹlẹda mi jẹ ki ntayọ(best)
Owo Dangote ko le to temi.
Agbe to ngbe ire pade olokun;
Ma gbe pade olokun mọ;
Agbe to ngbe ire pade ọlọsa;
Ma gbe pade ọlọsa mọ;
Ọdọ gbogbo eni to n ka ewi yii ni ki ogbe lò
Ọmọ Ajifọlajifaọla ni won ku se
Gbogbo Wa Lao Ri T’owo Ṣe O. Ao Ni Wa Owo Ti Laṣẹ Ọlọrun
Amin.
*OJUMO’RE* -
Ogbón kò kúkú ní tán n’ílé ayé kí á wa lo sí òde òrun.
Ogbón kò kúkú ní tán n’ílé ayé kí á wa lo sí òde òrun.
Arákùnrin kan ni ó so àwon táyà okò tí ó ti bàjé yí di tábìlì aláfé, okùnrin yí tí ó jé omo orílè èdè Nìjíríà.
Kí ní òhún sì rewà.
-
Àwon ìbeta tí ó rewà yí tí ewà won sì wuni yí se ayeye ojó ìbí won pèlú àwòrán tó yááyì.
John, Peter àti Jamie Obidiegwu, ìbeta se ayeye ojó ìbí won ní àrà òtò.
Ayeye ojó ìbí míràn ni ó jé fún àwon ìbeta tí ó jé okùnrin yí, ohun ayò ni ayeye yí sì jé fún won tí won fi se ayeye ojó ìbí won.Òkan lára àwon ìbeta yí ni ó pin sí orí instagiramu tí orúko rè ń jé @jamietriplet, tí ó pín àwòrán náà tí ó sì ko ibi tí won ti baabò.
-
Ìgbeyàwó alárédè ti DJ consequences àti Olayemisi Williams.
Arákùnrin tí ó ń se isé DJ tí a mò sí DJ consequences àti aya rè Olayemisi Williams ti se ayeye ìgbeyàwó won. A kí tokotayà kú oríre .

-
Tboss se ayeye ojó ìbí fún ìyá rè àgbà ti ilè Roman
Tboss se ayeye ojó ìbí fún ìyá rè àgbà ti ilè Roman.
Ará ilé télè ti BBnaija tí a mò sí Tokunbo Idowu tí ìnagije rè ń jé Tboss, ti se ayeye ojó ìbí fún ìyá rè àgbà ti ilè Roman.
Ó pín àwòrán òun àti ìyá náà ní àná láti se ayeye fun.