Home / Awọn Iroyin Agbegbe / À ń fún àwọn èèyàn lọ́rùn pa ni-Monsuru Afurasí

À ń fún àwọn èèyàn lọ́rùn pa ni-Monsuru Afurasí

À ń fún àwọn èèyàn lọ́rùn pa ni-Monsuru Afurasí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àtubọ̀tán ayé ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n.
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní bí a bá ń rin ìrìnàjò, kí á wo ẹni tí à ń bá lọ, nítorí àti ilé àti òde ni apani wà.

Ìròyìn àgbọ́ Tomi lójú pòròpòrò nípa Monsuru Tajudeen ẹni ọgbọ̀n ọdún kan tí ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọṣun lórí ẹ̀sùn pé ó ń pa ènìyàn tí ó sì ń ta ẹ̀yà ara wọn fáwọn tó ń fi ènìyàn ṣètùtù ọlà.

Ìlú Ìwó lọ́wọ́ àwọn agbófinró ti ba Monsuru tí ó sì jẹ́wọ́ pé kò tíì ju èèyàn tí òun ti pa. Ó ní ọ̀rẹ́bìnrin òun gan an wà lára àwọn èèyàn tí òun ti pa.

Bákan náà, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́, Hamzat Akeem ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó jẹ́wọ́ pé òun lòun tan Gafari ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ òun lọ sí ilé Mọnsuru níbi tí wọ́n ti gba ẹ̀mí rẹ̀.

Ó ní ẹgbẹ̀rún márùn náírà ni wọ́n fún òun nínú owó náà.

Awayewaṣere Yusuf tí ó ń ra àwọn orí èèyàn lọ́wọ́ Mọnsuru náà jẹ́wọ́ pé ẹgbẹ̀rún lọna ogún Náírà ni òun máa ń san fún orí kọ̀ọ̀kan tí òun bá rà lọ́wọ́ mọnsuru láti fi ṣe ètùtù ọlà.

Bákan náà ni Lukman Garuba, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n tí wọ́n mú pẹ̀lú rẹ̀ náà ṣàlàyé pé ẹ̀yà ara èèyàn ni òun máa ń rà lọ́wọ́ Mọnsuru àti pé ẹgbẹ̀rún méjì náírà lòun máa ń san fún un.

Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn ṣọ̀rọ̀, Mọnsuru ni: “Ohun ti a má ń ṣe nipé, a má ń fún àwọn tó bá kó sí wa lọ́wọ́ lọ́rùn pa ni, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ní ìgbàgbọ́ nínú wa tán.

Nígbà míràn, a ó ti bá wọn lòpọ̀ tán ní alẹ́, kí á tó wá fún wọn ní ọrùn pa kí ilẹ̀ tó mọ́, tí a ó sì gé ara wọn sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ láti tà wọ́n.”

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Covid-19- kó̩ ló pa Babatunde Oke

Covid-19 ko lo pa Babatunde OkeOwuro oni ni won kede iku Alaga ijoba ibile Onigbongbo, Ogbeni Babatunde Oke. Gbogbo iroyin to gbee ni ajakale arun coronavirus lo paa. Won ni baba naa se aisan ranpe ni nnkan bii ose meta seyin sugbon ti ara ti ya.Won ni alaga yii se odun ileya pelu awon ololufe ati ore pelu ojulumo ni asiko odun naa. Asiko yii gan-an ni awon olutele oloogbe naa ni ategun tun raaye wo ara re. Won ni ...