Home / Iroyin Pajawiri / Àwọn ilé mi, ọkọ̀ 12, ọmọ àti ènìyàn méje pẹ̀lú ₦500m ni mo sọnù ní Igangan – Seriki Fulani

Àwọn ilé mi, ọkọ̀ 12, ọmọ àti ènìyàn méje pẹ̀lú ₦500m ni mo sọnù ní Igangan – Seriki Fulani

Àwọn ilé mi, ọkọ̀ 12, ọmọ àti ènìyàn méje pẹ̀lú ₦500m ni mo sọnù ní Igangan – Seriki Fulani

Fẹ́mi Akínṣọlá
Seriki Fulani ní ìlú Igangan níjọba ìbílẹ̀ Ibarapa nípìnlẹ̀ Oyo, Alhaji Salihu Abdulkadir ti fẹ̀sù kan pé ajafẹ́tọ ọmọ Yorùbá, Sunday Adeyemo, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sunday Igboho, àti àwọn ìsọ̀mọ̀gbé rẹ̀ pa méje nínú àwọn ènìyàn òun lásìkò tí wọn wa síbẹ̀.

Sáájú ni Igboho ti fún àwọn Fulani ni gbèdéke ọjọ́ méje láti kúrò ninú ìlú Igangan.

Lẹ́yìn ti ọjọ́ náà pé ni Sunday Igboho lọ ilú náà lọ́jọ Ẹtì tó kọ́já nítori pe ó fi ẹ̀sùn kan wọ́n pé àwọn ni wọ́n wà nídìí, ìpàniyan, ìjínigbé àti ìfipá bánilòpọ̀ tó n wáye níbẹ̀.

AbdulKadir sọ pé Fulani méje, àti ǹkan ìní tó tó mílíọ̀nù lọ́nà ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ́ta náírà ni òun pàdànú.

“Awọn ile mi, ọkọ mejila to jẹ temi, awọn ọmọ mi ati alejo meje ni wọn dana sun, ti a ko si ri oku meji ninu wọn, bẹẹ́ ni wn ji awọn ẹran ọsin mi ko lọ.”

Bákan náà ni ó fi kún un pé, òun kò lọ́wọ́ nínú gbogbo ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan òun nípa ìjínígbe ni agbègbè náà, pàápàá jùlọ ìpànìyàn ọmọwé gboye Havard tó jẹ́ ọmọ ìlú náà, ọ̀mọ̀wé Fatai Aborode ti wọ́n pa ni ìpakúpa.

Lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Ilorin, ti ṣe olúùlú ìpińlẹ̀ Kwara ló ti ní irọ́ pọ́nbélé ni Sunday Igboho ń pa mọ́ òun.

Ó ní òun àti ẹbí òun tí ń gbé ìlú Ìgàngàn láti bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, tí kò sì sí ẹni tó yẹ òun lọ́wọ́ wò.

Ó wá ké pe gbogbo àwọn Emir àwọn ìpínlẹ̀ Arewa mọ́kàndínlogun àti àwọn olóyè, láti dìde ìrànlọ́wọ́ fún gbogbo Fulani tó wà ní ilẹ̀ Yorùbá.

Bákan náà lo fi kún pé, nígbà ti wọn wá fi ẹjọ́ ọmọ Fulani kan ti wọ́n ń pè ni Omomogeto sun òun, ẹni tí wọ́n ló fipá bá ọmọbìnrin kan lò pọ̀, òun fá à lé ọlọ́pàá lọ́wọ́ ni.
“Lẹ́yìn ti wọ́n mú un, tí wọ́n ṣe ìwádìí, tí aje ọ̀rọ̀ náà sì ṣí mọ́ ọ lórí, mo fi sí ìkáwọ́ àwọn ọlọ́pàá ni.

Bákan náà ni wọ́n fipá bá ọmọbìnrin míràn tó jẹ́ ọmọ Ìgàngàn lòpọ̀ lọ́dún tó kọjá, débi pé, ọmọbìnrin náà kú, kò sí ǹnkan tí wọ́n ṣe sí ẹni tó bá ọmọbìnrin náà lòpọ̀ di òní yìí.

Ó wá késí Ìjọba láti tanná wádìí àwọn ẹ̀sùn náà, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ̀bi ni kó fí ojú winá òfin .

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*