Home / Àṣà Oòduà / Odù Ifá Mímọ́ Ọ̀bàrà Bubu

Odù Ifá Mímọ́ Ọ̀bàrà Bubu

Ekáàrọ̀ọ́ ẹ̀yin ènìyàn mi, aojiire bi? Oni a sanwa o, ao rí tiwa se loni, gẹ́gẹ́bí òní ṣe jẹ ọjọ́ àíkú, gbogbo wa koni kánjú ku lágbára Olodùmarè àṣẹ.
E jékí a fi odù ifá mímọ́ ọ̀bàrà bubu yi ṣe ìwúre ti aarọ yìí.
Ifá náà ki báyì wípé:
Òkún ṣàn
Ó relé òkun
Òsá ṣàn
Ó relé ọ̀sà
Óní Alárá nwọ ogun lọ o pa ìyán lórí òun
Óní Ajerò nwọ ogun lọ o pa ìyán lórí òun
Óní sebi òun lo se òun ọ̀pẹ̀ èlìjù ti imọ̀ orí òun wá kù jééré
Òrúnmìlà ni kí wọn mú ajá kan ki wọ́n wẹ lagbo ifá ki wọn sọ orúkọ ajá náà ni “ojú ọ̀pẹ̀”
Moni moti ṣe bẹẹ bara mi àgbonmìrègún
Òrúnmìlà ni ṣé mo mọ orin tí màá máa kọ?
Moní rárá èmi kò mọ́
Òrúnmìlà ni kí ma so wípé:
Mí tì bímọ
Mí tì lọ́yà
Ojú ọ̀pẹ̀ mèi ò( ojú ọ̀pẹ̀ ni mo nwo)
Ojú ọ̀pẹ̀
Ééye
Ojú ọ̀pẹ̀ mèi ò
Ojú ọ̀pẹ̀.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, mosè ni ìwúre laarọ yi wípé ifá kòní dójú ìwúre tìwa lọ́jọ́kọ́jọ́, gbogbo ìbéèrè wa lọ́wọ́ ọ̀pẹ̀ ni yio máa wá sí ìmúse lágbára Eledumare, gbogbo àwa ti a ntẹle ifá ni ao máa lẹ́nu ọpẹ̀ nínú àṣeyọrí ati ìgbéga nigba gbogbo lasẹ Eledumare ááse.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

English version when you continue after the page break

About ayangalu

x

Check Also

Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

Looking at the Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá, it could be said that sometimes our detractors feel they are hurting us but they don’t know they are pushing us to wealth. Just listen to this stanza from the Odù. Òtééré ilè ńyóÒtèèrè ilè ńyòIlè ńyó ará iwájúÈrò èyìn e kíyèsí ílèAdífá fún Ìwòrì tí yóó tarí Ogbè sínù àbàtàbútú ajéKòìpé kòìjìnà, Ogbè ló wá jìn sínú ajé gbugburu Òtééré, the ground is slipperyÒtèèrè, the ground is difficult ...