Home / Iroyin Pajawiri / #EndSARS: Obasanjọ, Ọọ̀ni sọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́
ooni obj

#EndSARS: Obasanjọ, Ọọ̀ni sọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́

EndSARS:Obasanjọ, Ọọ̀ni sọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àgbà tí òye yé kan kìí wà lọja, kí orí ọmọ tuntun wọ́, ìdí rèé tí àwọn àgbà kàn-aǹ-rìn méjì nílẹ̀ Yorùbá fi forí korí lórí ìwọ́de EndSARS tó ń lọ lọ́wọ́ yíká Orílẹ̀ yìí.

Àwọn àgbààgbà méjéèjì náà ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbasanjọ àti Ọọ̀nirìṣà tìlú Ilé Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ẹnìtàn Ògúnwùsì, tí wọ́n ṣọ̀rọ̀ lórí ìwọ́de náà.

Olóye Ọbasanjọ, lásìkò tó lọ se kára ó le sí Ọọ̀ni, sàlàyé pé ìwọ́de tó ń lọ yíká Nàìjíríà yìí ti fún Ìjọba lánfààní láti sọ fún aráàlú pé òun náání wọn.

Ọbasanjọ ní ìwọ́de yìí ló ń ṣàfihàn inú tó ń bí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà, èyí tó yẹ kí Ìjọba tètè kọbi ara sí.

Ààrẹ àná ní Nàìjíríà náà ní ó lé ní ìdá ọgọ́ta nínú Ọgọ́rùn àwọn èèyàn Nàìjíríà tí ọjọ́ orí wọn kò tó ọdún márùndínlógójì, tí wọ́n sì ń fi ojú sọ́nà fún ìgbé ayé tó dára àmọ́ tí wọn ń bá kádàrá yí pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ lọ́wọ́.

“Ọ̀pọ̀ wọn gan ni kò ní àǹfààní sí ẹ̀kọ́ ìwé, tó sì jẹ́ pé àìsí àǹfààní láti se rere ti dá ìrẹ̀wẹ̀sì sí àwọn ọ̀dọ́ tó kàwé lọ́kàn, ó sì yẹ kó yé wa pé ó di dandan kí wọ́n sí ìdérí lórí omi tó ń hó náà.”

“Àmọ́ mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà fún Ìjọba láti ṣàmúlò rẹ̀ lórí ìpèsè ìdẹ̀rùn fún àwọn ọ̀dọ́, Ààrẹ, gẹ́gẹ́ bíi bàbá orílẹ̀-èdè àti àwọn ọ̀dọ́, tó sì ní ọmọ tirẹ̀, ó yẹ kó mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ti le hùwà.”

Nígbà tó wá ń fèsì, Ọba Ògúnwùsì ní ìwọ́de yìí jẹ́ ọ̀nà láti fi iṣẹ́ ránṣẹ́ síìjọba pé àwọn ọ̀dọ́ náà leè se nǹkan lọ́nà tó dára.

“Tá a bá wo ìwọ́de náà, aá ri pé àwọn ọ̀dọ́ ti gba àkóso orílẹ̀-èdè yìí, láti ọjọ́ àkọ́kọ́ ìwọ́de, sì ni wọ́n ti se àfihàn pé àwọn ní àbùdá asáájú rere.

Bákan náà ni wọ́n ń jíyìn iṣẹ́ ìríjú wọn láàrin ara wọn, tí wọ́n sì ń se ojúṣe tó yẹ, èyí tó ń pàrokò fún Ìjọba nípa báwọn ọ̀dọ́ Ilẹ̀ yìí ti dáńgájiá tó.”

Ọba Ògúnwùsì wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ náà láti jèbùrẹ́, kí wọ́n sì dúró de ohun tí Ìjọba fẹ́ se lórí ìbéèrè wọn.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

tems

Mo setán láti kú’ – Tems

Mo setán láti kú’ – Tems Mary Fágbohùn Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti safihan pe oun setan lati doju ko saare nigba ti oun fi eya orin takasufe ti gbogbo eniyan mo kaakiri orile ede sile fun R&B. Tems wi pe oun ni igbagbo pupo ninu ara oun to bee ti oun ko bikita bi oun o ba “je nnkankan tabi da enikeni” pelu R&B. Olorin ‘Essence’ naa so pe oun kan ...