Ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo pe Ààrẹ Buhari lánàá , àmọ́ ń kò ri bá sọ̀rọ̀ – Sanwo-Olu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán èèyàn ńlá kò ní tíì sinmi àròyé Sanwo-Olu tíí se Gómìnà wọn ní ìpínlẹ̀ Èkó tún ti gbóhùn sókè sàlàyé pé òun kò tíì rí ààyè bá Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, títí di àkókò yìí.
Ó ní òun pe Ààrẹ Buhari lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn náà láàrọ̀ àná, àmọ́ wọ́n ń bùn mi gbọ́ pé kò tíì dé sí ọ́fíísì.
Ó fikún un pé òun tún padà pè lórí aago, àmọ́ tí wọ́n sọ fún òun pé ó wà ní ìpàdé Ìgbìmọ̀ aláṣẹ Ìjọba ilẹ̀ yìí tó ń wáyé lánàá.
Bákan náà ni Sanwo-Olu ní olórí iléeṣẹ́ ọmọ ológun ilẹ̀ wa ti pe òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ọ̀hún.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀hún tún sísọ lójú rẹ̀ pé ìjọba òun ti gbé igba mílíọ̀nù náírà kalẹ̀ bíi owó gbà má bínú fáwọn èèyàn tó forí sọta ìwọ́de EndSARS náà.
Ó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ tó ń sèwọ́de láti fi orúkọ èèyàn méjì sílẹ̀, tí yóó ṣojú wọn nínú Ìgbìmọ̀ olùwádìí tí Ìjọba gbé kalẹ̀ lórí ẹ̀hónú wọn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò tó tọ́ yẹ kí wọ́n fààyè gba àwọn ìpínlẹ̀ láti ní ọlọ́pàá tiwọn, Kódà, ó ní ọ̀rọ̀ náà ti pẹ́ jù.