Jàǹdùkú pa ọlọ́pàá méjì, jó àgọ́ wọn mẹ́wàá, báńkì mẹ́ta, jí ọ̀pọ̀ owó l’Ékó -iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, ìjàngbọ̀n kìí dúró síbi tó bá rọ̀, bí kò ṣe ibi tó bá le koko.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ké síta lórí bí àwọn jàǹdùkú tó fi ìwọ́de End SARS bojú, ṣe ń kọlu àwọn ọ́fíìsì àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde bẹ́ẹ̀ nínú àtẹjáde kan tó fi ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn, èyí tí alukoro iléeṣẹ́ náà ní ìpínlẹ̀ Èkó, Olumuyiwa Adejobi, buwọ́lù.
Ó ní àwọn jàǹdùkú náà pa ọlọ́pàá méjì ní àgọ́ wọn tó wà ní Orile, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ṣe ogun lọ́gọ̀ ọlọ́pàá lése, kí wọ́n tó dáná sun àwọn agbègbè mẹ́wàá míì, tí àwọn ọlọ́pàá máa ń kórajọ sí.
Lára àwọn àgọ́ ọlọ́pàá tí ọ̀rọ̀ náà kan ni ti Igando, Layeni, Denton, Ilenbe Hausa, Ajah, Amukoko, Ilasa, Cele labẹ Ijesha.
Bákan náà ni wọ́n tún kọlu ọ́fíìsì SARS tó wà ní Ajegunle, Ebute-Ero Mushin níbi tí wọ́n ti ṣíná ìbọn fún ọlọ́pàá méjì, pẹ̀lú Ojo àti Ajegunle níbi tí wọ́n ti jó ọkọ̀ ọlọ́pàá meji méjìméjì.
Kò tán síbẹ̀, àtẹjáde náà ní “Àwọn jàǹdùkú ọ̀hún tún dáná sun báńkì mẹ́ta, tí wọ́n sì jí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó kó lọ, ṣùgbọ́n a rí díẹ̀ lára mú, tí a sì gba ohun ìjà olóró àti owó tí wọ́n jí kó lọ́wọ́ wọn.”
Ní Ajégúnlẹ̀, wọ́n dáná sun ọ́fíìsì Ìjọba ìbílẹ̀ Ajeromi Ifelodun tí wọ́n sì tún ba àwọn dúkìá jẹ́ níbẹ̀.
Àwọn jàǹdùkú náà tún ṣàkọlù sí ààfin ọba ìlú Èkó, ilé ìtajà Shoprite, iléeṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ní Marina àti ilé ìyá Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó tó wà ní Akerele.
Bákan náà ni wọ́n tún jó ọ́fíìsì àwọn VIO ní Ojodu, ilé ẹjọ́ májísírètì ní Igbosere, iléeṣẹ́ Ìròyìn TVC àti The Nation, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà fi kún un pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dágbére fáyé nítorí ìkọlù àwọn jàǹdùkú náà, tí àwọn mẹ́rin kan sì farapa yánayàna.
Lẹ́yìn náà ló ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ní fààyè gba irú rògbòdìyàn báyìí mọ́.