Home / Àṣà Oòduà / Niluu Abeokuta, apata wo pa iya ati awon omo re

Niluu Abeokuta, apata wo pa iya ati awon omo re

Niluu Abeokuta, apata wo pa iya ati awon omo re. Olayemi Olatilewa

Apata kan ti n be loke tente ni agbegbe Iberekodo niluu Abeokuta ti ye lule to si seku pa iya ati awon omo re.

Bi eniyan ba je ori ahun, bo ba ribi ti okuta nla ti gbe run eniyan eleran ara mo ogiri ile, onitoun yoo bu omi loju suurusu.

Ojo ibanuje nla gbaa ni ojo Eti to lo loun je fun awon idile ogbeni Ismail Lawal ti won gbe ni agbegbe Iberekodo to kale si Abeoukata ni ipinle Ogun nigba ti apata nla kan sadeede yelule, to si seku pa iyawo ati awon omo re ti won sun sinu yara ibusun.

Isele yii lagbo wi pe o waye latari ojo nla kan to bere lati bi nnkan bi ago marun-un irole titi di bi nnkan bi ago mesan-an ale.

Awon eniyan ti won ba isele laabi naa lo ni iyawo ogbeni Ismail, ti n je Silifat Lawal ati awon omo re meji ti won je Rasheedat ati Semia.

Omo odun meedogun (15) ni Rasheedat nigba ti Semia je omo odun merin (4). Bakan naa ni Mariam to je omoomo Silifat na doloogbe ninu isele naa.

Nigba ti Ismail to je baale ile fara pa pelu awon omo re meji ti won n je Sukurat ati Rofiat.

Ohun to ko Ogbeni Ismail ati omo re meji yoku yo ni wi pe won ko si ninu yara ibusun ti iyawo re wa, yara igbalejo (palo) ni awon wa ni akoko isele naa.

Arabirin Khadijat Adegoke, okan ninu awon eniyan ti won gbe ni agbegbe naa ni awon ko tile mo ohunkohun, nitori iji ti n ja n pariwo gan-an, titi di akoko ti Ogbeni Ismail fi wa pe awon fun iranlowo.

Elomii to ko lati daruko ara re naa tun fi ero re han nipa isele to waye naa:
“Isele buruku ni isele naa eleyii ti ko ye ko maa sele.

Opolopo awon okuta nlanla ni i be lori oke eleyii ti ko ridi joko. Sibesibe, awon eniyan n kole sabe re nisale. Ero awon eniyan ni wi pe apata kii sidi, sugbon eyi to sele yii yoo je arikogbon”.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo