Home / Àṣà Oòduà / Awon Obirin to n binu si oludari CRIN niluu Ibadan bora sile nihoho

Awon Obirin to n binu si oludari CRIN niluu Ibadan bora sile nihoho

Awon Obirin to n binu si oludari CRIN niluu Ibadan bora sile nihoho
Olayemi Olatilewa
Gbegede gbina niluu Ibadan lojo Monde to koja yii nigba ti awon osise ibudo imo ti won ti n sewadii ijinle nipa koko, Cocoa Research
Institute of Nigeria (CRIN) to kale siluu Ibadan ni ipinle Oyo se tu jade lati fehonu han latari bi oludari ibudo naa se n gbe awon igbese ti ko bojumu.

Ile ise to kale si oju ona masose Ibadan si Ijebu-ode ni awon obirin ile ise yii ti gbe yadina pelu abala ara won nihoho nigba ti awon okunrin bere si ni korin ote, orin owe mo oludari ibudo naa, Ojogbon Malachy O. Akoroda.

Gege bi alaye ti okan lara awon osise ibudo imo naa se fun OLAYEMI ONIROYIN, won ni opo awon iwadii ti ko wulo si ise won ni Akoroda n da owo le lori, eleyii to je wi pe enikeni ko gbodo fohun. Yato si eleyii, won ni oga naa n fi aye ni awon osise lara pupo ju, gbogbo igba lo si maa n ko awon osise abe re laye je nigba ti enikeni ninu won ba gbiyanju lati tu asiri iwa ibaje to pelemo si i lowo.

Sugbon oro naa tun ba ibo mi-in yo nigba ti awon agbofinro de agbegbe naa. Ti won si bere si ni so fun awon osise naa wi pe ki won o gbe awon akole ti won gbe soke wa sile.

Bakan naa ni won ni ki won o ko awon igi ati yanrin ti won ko dina kuro ni kiakia ti won ko ba fe ko leta siya.

Ibi yii ni awon osise ti won n fehonu han, eleyii ti awon ara ilu naa ti darapo mo won ti gbe tuto soke ti won si foju gbaa.

Oro ba tun di isu ata yan-anyan laaarin awon agbofinro ati awon eniyan ti won fehonu han naa. Won ni eto awon lawon n ja fun, olopaa kankan ko si le di awon lowo rara.

Awon osise CRIN pelu atileyin Oloye Yekeen Ogunyode to je Baale Odo Onanla to je agbegbe ti ibudo imo naa kale si ti fesun kan komisanna awon olopaa ti ipinle Oyo, Ogbeni Leye Oyebade, nipa liledi-apo-po pelu Akoroda lati koju ija si awon osise naa.

Gege bi oro Baale agbegbe naa, Baale ni awon alase toro naa kan ni awon ti lo fejo sun nipa rukerudo ti n waye ni ibudo imo naa.

“A ti kowe si Aare ile Naijiria, Ile Igbimo Asoju-sofin lori awon rogbodiyan ti n lo lowo. Bakan naa ni leta ti de odo awon ajo EFCC, ICPC ati awon oga agba nipa isiro owo lorileede Naijiria lori bi Ojogbon Akoroda se n se owo ibudo imo naa mokumoku.

“Gege bi agba ilu, a ko le yaju sile ki awon nnkan bayii maa waye. A tile ti gbiyanju ni awon akoko kan lati dasi oro naa ko si yanju, sugbon agidi ati iwa-taani-yoo-mu-mi ni Akoroda gbewo bi ewu”, Baale Ogunyode fi kun oro re bee.

Gbogbo igbiyanju OLAYEMI ONIROYIN lati gbo alaye enu oludari CRIN, Ojogbon Akoroda lori rugudu naa lo jasi pabo. Akoroda ni gege bi osise ijoba, won ko fun oun lanfaani lati ba oniroyin yin kankan soro lai gbase lowo awon oga loke.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo