Home / Àṣà Oòduà / Ijamba buruku kan lo waye loju ona masose Ilesa si Ibadan

Ijamba buruku kan lo waye loju ona masose Ilesa si Ibadan

Awon Yoruba bo, won ni iku ti o ba pani, toba si fila eni lo ope ni ka maa du. Ijamba buruku kan lo waye loju ona masose Ilesa si Ibadan l’Ojobo ose to koja yii nigba ti maalu awon darandaran sadeede yawo titi oloda ti awon oko n rin.

Oko akero nla bogina (luxurious bus) lo jalu awon maalu yii lori ere lojiji. Awako naa gbiyanju bi ko dogbon yiwo fun won maalu naa. Sugbon o ti pe ju, bi o ba se bee yiwo segbe, oseese ki oko nla naa yi danu.

Awako naa tun ero inu re pa, lo ba tena gba aaarin awon maalu naa koja. Awon maalu bi ogun ni oko naa gba pelu bo se n juwon si apa otun ati apa osi. Awon maalu bi mokanla ni won deran Ogun loju ese, nigba ti awon kan sun sile lo legbe titi ti won ko si le dide.

Bi o tile je wi pe oko akero na o danu, sugbon gbogbo ara oko naa lo te wonu, ti awon ina iriran re si fo yangayanga bi eyin ti won so lu apata.

Olayemioniroyin.com

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*