Home / Àṣà Oòduà / Igba otun ti de: Raji Fasola ti bo soju ise

Igba otun ti de: Raji Fasola ti bo soju ise

Minisita fun ina Monamona, Ise Ode, ati Ilegbee, Babatunde Raji Fasola ti kede eto ati awon igbese re akoko eleyii ti o fi ma side ise ilu ti won gbe le e lowo gege bi minisita.

Gege bi gomina eleeketala ti o je ni ipinle Eko se safinhan awon eto re, agbejero agba, eni odun mejilelaadota (52) naa fi da awon ara ilu loju wi pe egberun meji megawaati (2, 000 megawatts) ni eka ile ise ijoba oun ti seto re fun ina monamona orileede yii gege bi afikun agbara ti o tun je ki ina elentiriki gbara duro fun lilo awon ara ilu ju ti tele lo.

Ogbeni Fasola to kawe gboye ninu imo ofin ni Ifafiti ilu Benin lodun 1987 lo fi n da awon eniyan loju nibi ipade to sepo pelu awon oniroyin niluu Abuja wi pe, oju ona masose Eko si Ibadan ati afara Niger to dabi wi pe awon ise to ti bere nibe ko lo geerege mo wa lara awon nnkan ti oun yoo koko musaloogun lati mu aseyori ise naa ya ni kanmokanmo.

Lara awon asiri tuntun eleyii ti ko han senikan tun ni bi BRF se fi sita wi pe, odun 2002 ni igba ikeyin ti ijoba na owo to to bi igba bilionu meji owo naira (N2B) si eka ise ode ti n ri si awon oju popona tijoba apapo.

Fasola tun fi kun oro re wi pe, laipe ni awon ojulowo ise atunse to se e fojuri yoo bere ni awon ojupopona to so awon ipinle merindinlogoji (36) ni jakejado orileede yii papo.

Lara oro gomina ipinle Eko nigba kan ri tun ni bo se tenumo idi pataki ti eka ina monamona orileede yii fi gbodo di taladani patapatapa. Ogbeni Fasola ni ona kan pataki ni yii lati mu aseyori to loorin deba ina monamona gege bi a se ri ti eka ibanisoro wa. BRF so wi pe eleyii wa lara awon igbiyanju oun eleyii to daju wi pe yoo mu eso rere wo orileede Naijiria, ilu olokiki nla ti n san fun wara ati oyin.

Ogbeni Fasola, eni to gba ami eye gomina to pegede ju lo lodun 2010 tun so nipa akitiyan re lati ri daju wi pe awon osise ile ise abanikole ti won padanu ise won latari airowosan ni won yoo pada rerin ayo.

“Gege bi akosile to te mi lowo gege bi minisita, nnkan bi osu karun-un odun yii ni awon onise kongila agbasese ti won sise fun ijoba ti dawo ise duro nitori owo ti ko te won lowo. Eleyii to mu won da pupo awon osise nu bi omi isanwo.

“Iwadii mi lori awon ile ise bi merin ti mo se ayewo won, mo ri wi pe ati bi osu keta odun yii ni won da awon eniyan bi egberun marun-un (5,000) sile ninu awon osise won eleyii to so awon osise naa deni ti n rin kiri igboro lai rise kankan se.

“Te e ba si wo o, awon ise akanse bi igba (200) lo ti dawoduro bayii, eleyii to je wi pe ise akanse kan fun ile ise agbase se kan naa ni eto naa dale lori.

“Ka so wi pe ile ise agbase se kan ni awon osise bi ogorun (100) ti n ba won sise ni awon ibudo ise kookan ti ile ise  naa ti n sise. Gege bi isiro mi, o kere tan, awon eniyan bi egberun lona ogun (20, 000) ni yoo ti di alainise lowo.

“Sugbon pelu gbogbo awon eto ati igbese ti mo fe tara bo yii, awon eniyan bi egberun lona o ogun, o kere tan, ti won ti padanu ise won ni yoo pada sope fun Oluwa oba,” BRF se mo alaye re bee

Ti e ko ba gbagbe, leyin osu kefa ti won gbe agbara isakoso Naijiria le Aare Muhammadu Buhari, eni ti o pe omo odun metalelaadorin (73) lojo ketadinlogun osu yii (17/12/15), lowo lo to pinnu lati se agbekale awon igbimo ti yoo ma sise pelu re gege bi minisita.

Lara awijare aare, eni to tun je minisita fun epo robi lowolowo bayii ni wi pe, pipe to pe oun lati se afihan oruko awon minisita naa ni nipa sisamulo awon eniyan olododo, awon eniyan ti won ko labawon lara, ti won si lemi ifisin lati sise ilu ti won yoo gbe fun won.

Gbogbo ipinle merindinlogoji (36) to gbe Naijiria ro ni ni Aare Buhari, eni ti awon kan tun un pe ni “Baba Go Slow” ti yan enikookan gege bi minisita eleyii ti ile kaaro-o-ji-i-re naa ko gbeyin nibe.

Aare Buhari, eni to je alakoso ile Naijiria gege bi ologun laaarin 1983 si 1985, mu arabirin Kemi Osun lati ipinle Ogun lati fi je Minisita fun eto isuna owo, Omowe Kayode Fayemi, ipinle Ekiti, ni won ni ko se akitiyan lori awon alumooni ile aridimu nigba ti Ogbeni Bayo Shittu lati ipinle Oyo di minisita fun eto ibanisoro.

Awon yoku ti Baba Daura lati ipinle Kastina yan gege bi minisita ni Ojogbon Isaac Folorunsho Adewole lati di eka eto ilera mu, nigba ti won yan Ojogbon Omoyele Daramola lati je igbakeji minisita ti yoo ma risi awon oro to je mo apa agbegbe Niger Delta. Lai Mohammed lati ipinle Kwara si di minisita fun Eto Iroyin.

Akanpo onibeta ni Buhari fi ise Fasola se nigba to fi se minisita ina Monamona, Ise Ode ati Ilegbee. Opolopo awon onwoye nipa iselu ati awon onimo nipa awujo lo gba wi pe oun kan pataki ti ise Fasola fi po to bee ko ju nipa aseyori re ni Ipinle Eko lo. Eleyii ti won gba wi pe yoo tun le se bakan naa ninu ise tuntun re ti won gbe fun un niluu Abuja.

Orisun: Olayemioniroyin.com

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo