Home / Àṣà Oòduà / Senato ipinle Ekiti pin iresi fun awon eniyan bi Fayos

Senato ipinle Ekiti pin iresi fun awon eniyan bi Fayos

Awon eniyan ti won gbe ni agbegbe ekun Guusu Ekiti gbajo tilu tifon nigba ti arabirin Biodun Olujimi ti n soju won nile igbimo asofin agba Abuja si obitibiti ounje wolu l’Ojobo ose to koja yii.

Apo iresi, ororo ati aimoye awon nnkan ti enu n je ni Senato Olujimi ko wa lati da awon eniyan lola gege bi ebun odun. Lara awon ebun ti Senato Olujimi ko wa ni awon oko tokunbo bi tuntun mefa eleyii ti okookan re yoo ma lo si ijoba ibile mefa to gbe ekun naa duro.

Gege bi oro Senato Olujimi, o ni awon kii se oloselu to je wi pe, akoko idibo lasan ni won yoju si awon eniyan won nigberiko. Bakan naa lo tun so siwaju ninu abewo re wi pe, ki awon eniyan lo mokan bale, gbogbo ileri ti awon se pata ni awon yoo mu wa si imuse.

Sugbon sa, gege bi ero Ogbeni Ayo Oluwaseesin to je omobibi ipinle Ekiti sugbon to fi ilu Eko se ibujoko salaye wi pe, ko ba dara ti awon oloselu wa ba le ronu idasile ileese alabode ti awon eniyan ti le sise. Eleyii ti yoo mu won kuro ninu iponju yato si ounje pinpin nigbogbo igba. O ni owo ti awon oloselu bi senato n gba lati se itoju ekun ti won soju koja owo ti won fi n ra iresi ti won pin. O si tun fi kun-un wi pe, yoo dara ti ero yii ba le ye awon eniyan ki won si jigiri lati beere ojulowo eto won lowo awon oloselu.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo